Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àpapọ̀ ìtẹ́rọsọ́nà àti ìlò ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran láti fi ṣe àwárí ibà

Yoruba translation of DOI: 10.1016/j.heliyon.2021.e07089

Published onApr 30, 2023
Àpapọ̀ ìtẹ́rọsọ́nà àti ìlò ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran láti fi ṣe àwárí ibà
·

Ìṣàwárí àwọn àfòmọ Ibà ní àwọn ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ nípa lílo ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran mid-infrared àti ìṣèṣirò kání fún ìtúpalẹ̀

Ìpàjùbà

Ìwádìí ajẹmájàkálẹ̀-àrùn nípa ibà lọ́wọ́lọ́wọ́ ń gbẹ́kẹ̀lé ìlò ẹ̀rọ awòbíńtín, ìhùwàsí àsopọ̀ polimẹ́ŕàsì (PCR) tàbi àwọn ohun ìdáàìsànmọ̀ lọ́gán fún ìkóràn àfòmọ́ agbébàrìn.

Ìwádìí yìí tọpinpin bóyá ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran mid-infrared (MIR) papọ̀ mọ́ ìtẹ́rọsọ́nà aṣàmójútó le parapọ̀ jẹ́ ìlànà mìíràn fún ìṣàyẹ̀wò ibà lọ́gán, tààràtà láti ara àwọn ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ.

Àwọn ọ̀nà àágbegbà

Wọ́n gba àwọn bébà tí wọ́n ní ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ (DBS) nípa ìfimúfínlẹ̀ gbogbogbò wọ́ọ̀dù 12 ní gúsù-mọ́-ilà-oòrùn Tanzania ní 2018/19.

Wọ́n ṣe àyẹ̀wò àwọn ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ́ (DBS) nípa lílo ẹ̀rọ aṣòdiwọ̀n onírannran fún ètè àṣeyẹ̀wò tí ó fi ààyè gbà àyẹ̀wò láìṣe ohun kankan sí ohun ìṣàyẹ̀wò (ATR-FTIR) láti gba èsì tí ó ga jù tí ó tó 4000 cm−1 sí 500 cm−1.

Wọ́n ṣe àfọ̀mọ́ ohun èèlò náà láti fi ààyè sílè fún ìrì ojú òfurufú àti CO2 tí wọ́n sì fi kọ́ onírúnrú aṣèpínsísọ̀rí ìlò ìsrò òǹkà láti ṣe ìyàtọ̀ láàrin àwọn bébà DBS tí wọ́n ní ibà àti àwọn ti wọn kò ní gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn níní àyẹ̀wò PCR fún ìtọ́kasí.

Ìtúpalẹ̀ náà ṣe àdàrò èèyàn 296, lára wọn ni 123 tí wọ́n ti fòǹtẹ̀ lù pé wọ́n ní ibà àti àwọn 173 tí wọn ò ní.

Ìdá 80 nínú àkójọ dátà ni wọ́n lò láti kọ́ àwòṣe, lẹ́yìn náà ni wọ́n wá mú iṣẹ́ àwòṣe tí ó dára jù dára sí i nípa lílo ète ajẹmọ́ṣirò aṣàkọ́túnkọ́ ní ìdá 80/20.

Wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn àwòṣe tí wọ́n kọ́ nípa ṣíṣe àsọtẹ́lẹ̀ ìjẹ́bẹ́ẹ̀ àfòmọ́ agbébàrìn fásípárọ́ọ̀mù nínu ìda 20 láàrin àwọn ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ́ tí wọ́n mú gẹ́gẹ́ bi aṣòǹtẹ̀.

Esi

Èsì fi yéni pé ìṣèṣirò kání ni àwòṣe tí ọ̀nà ìgbàmúṣẹ́ṣe rẹ̀ dára jùlọ.

Bí a bá lo PCR gẹ́gẹ́ bí ìtọ́kasí, ìtọ̀nà àwọn àwòṣe náà lápapọ̀ jẹ́ 92% fún ìṣàsọtẹ́lẹ̀ ìkóràn fásípórọ́ọ̀mù P. (ìsọpàtó = 91.7%; ìmọ̀lára = 92.8%) àti 85% nínú ṣíṣe àsọtẹ́lẹ̀ àdàpọl ìkóràn fásípórọ́ọ̀mù P. àti àfòmọ́-agbébàrìn ófélì (isọpàtó = 85%, ìmọ̀lára = 85%) fún àwọn ohun-ìṣèwádìí tí wọ́n gbà lóko ìwádìí.

Ìkádìí

Àwọn èsì yìí fi hàn pé ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran mid-infrared papọ̀ mọ́ ìtẹ́rọsọ́nà aṣàmójútó (MIR-ML) ṣe é lò láti ṣe àyẹ̀wò àfòmọ́ ibà ní àwọn ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbígbẹ.

Ìlànà ìgbàmúṣẹ́ṣe yìí lè ní agbára láti di ohun ìṣàyẹ̀wò àwọn àfòmọ́-agbébàrìn lọ́gán ni àwọn ibi tí kì í ṣe ìbùdó ìṣègùn (bí àpẹẹrẹ, ibùdó ìwádìí) àti àti àwọn èyí tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìṣègùn (bí àpẹẹrẹ ìdámọ̀ àìsàn láti ran ìdojúkọ ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́).

Àmọ́ ṣá, kí wọ́n tó lè ṣàmúlò ìlànà yìí, a nílò àfikún ìfòǹtẹ̀lù mìíràn ní àwọn oko ìwádìí mìíràn pẹ̀lú ìlò àwọn àfòmọ́ mìírà, àti àyẹ̀wò tó jinlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ìgbèrú àwọn ètè MIR.

Nípa ṣiṣé àtúnṣe sí ìtúnpínsísọ̀rí ìlò ìṣirò-òǹkà, àti fífi ọ̀pọ̀ dátà kọ́ àwòkọ́ṣe náà lè ṣàtúnṣe ìsọpàtó àti ìmọ̀lára.

Ètò ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran MIR-ML tóbi ní ìrísí, owó rẹ̀ kò ga jara lọ, àti pé bíńtín ni ìsọdọ̀tun rẹ̀.


Àpapọ̀ ìtẹ́rọsọ́nà àti ìlò ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran láti fi ṣe àwárí ibà

Àwọn aṣèwádìí ṣe àwárí àwọn ìlànà tuntu fún ṣíṣe ìdámọ̀ àwọn àìsàn ibà kíkó tí ó tún rọrùn láti rí, tí ó sì wà ní àrọ́wọ́tó tí ó sì tún ṣe é gbẹ́kèlé ju àwọn ìlànà àti àyẹ̀wò ìdámọ̀ àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí lọ.

Àwọn ìlànà wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀rọ tí a mọ̀ sí ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran mid-infrared (MIR), tí wọ́n papọ̀ mọ́ ìtẹ́rọsọ́nà.

Ó ṣe pàtàkì láti tọ ipa kíkó ibà lára ènìyàn àti ẹ̀fọn/yànmùyánmú kí àwọn aláṣẹ le ṣètò àwọn ohun ajẹmọ́tọ̀ọ́jú kí wọn ó sì lè se àmójútó àwọn ìṣẹ̀lẹ̀.

Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹ̀rọ awòbíńtín ni àwọn aṣèwádìí gbẹ́mìí lé, àyẹ̀wò PCR (ìlànà aṣọ̀pọ̀ ẹ̀dà), tàbí ìlànà ìdámọ̀-àìsàn lọ́gán láti dá àìsàn ibà mọ̀, àmọ́ àwọn ìlànà yìí kò ṣe é gbára lé, ó gba agbára káká, ó nílò ọ̀pọ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tàbí kí wọ́n gógó láti lè lò ó ní àwọn agbègbè ìgbèríko.

Ìwádìí yìí tọpinpin bóyá ẹ̀rọ ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran mid-infrared (MIR), bí wọ́n bá pa á pọ̀ mọ́ ìtẹ́rọsọ́nà, lè jẹ́ ìlànà mìíràn tí ó ṣe é tẹ́wọ́ gbà fún àyẹ̀wò ibà lọ́gán lórí àwọn ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ.

Àwọn aṣèwádìí náà gba àwọn ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ́ láti oko-ìwádìí tí wọ́n ti ṣe àwáká àwọn tí wọ́n kó ibà ní agbègbè ibi tí àjàkálẹ̀ ibà wà ní Tanzania.

Wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ nípa lílo ẹ̀rọ aṣòdiwọn-oníranǹran.

Wọ́n ṣe ìtúpalẹ̀ ọ̀gangan ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ́ àwọn 296, èyí tí ibà jẹ́ 123 níbẹ̀, tí 173 kò sì í ṣe ibà, àyẹ̀wò PCR ni wọ́n fi ṣe àrídájú ẹ̀.

Àwọn aṣèwádìí kọ́ àwòṣe aṣàmúlò-ìṣirò atẹ́rọsọ́nà kan tí ó ṣàmúlò ìdá 80 nínú dátà àyẹ̀wò ibà, ó sì yà àwòsè tí ó dára jùlọ tí yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láti ṣe àsọtẹ́lẹ̀ bóyà oje-àyẹ̀wò kan ní àfòmọ́ aṣàkóràn-ibà fásípórọ́ọ̀mù.

Àwọn aṣèwádìí tọ́ka sí àwòṣe ajẹmọ́ṣirò kan tí ìṣàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ lórí àfòmọ́ aṣàkóràn-ibà fásípárọ́ọ̀mù dára ní ìwọ̀n 92%, àti ìwọn 85% nínú ṣíṣe àsọtẹ́lẹ̀ àdàpọ̀ àfòmọ́ aṣàkóràn-ibà fásípárọ́ọ̀mù àti àfòmọ́ aṣàkóràn-ibà ófélì, tí ó tún oríṣìí àfòmọ́ mìíràn tí ó máa ń fa àìsàn ibà.

Àwọn ìwádìí láti ẹ̀yìn wá ti fi hàn pé a lè lo ète ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran mid-infrared (MIR) láti fi ṣe ìtọ́kasí àwọn àfòmọ́ ibà.

Ìwádìí yìí fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ìlànà náà jẹ́ èyí tí ó ṣe é gbára lé fún dída ohun-ìṣàyẹ̀wò tí o bá ti kó ibà mọ̀ yàtọl sí èyí tí kò tí ì kó.

Ètí ṣe pàtàkì torí ó túmọ̀ sí pé kò sị àfikún ìtúnrólágbára tàbí ìṣèlànà-ìṣaájú kankan fún àwọn ohun ìṣàyẹ̀wò.

Ó tún fi ẹ̀rí síwájú sí i múlẹ̀ nípa irú ipa tí ìṣòdiwọ̀n-oníranǹran ẹlẹ́rọ ífárẹ́ẹ̀dì le kó àti ìlànà ajẹmọ́ ìlò dátà òun ìmọ̀ kẹ́mísírì, tí a mọ̀ si ìṣòdiwọn-kẹ́mò láti fi tọ ipasẹ̀ àrùn tí ó jẹmọ ẹ̀fọn.

Ìdíwọ́ kan tí ó wà fún ìwádìí yìí ni pé iye ohun-ìṣàyẹ̀wò tí wọ́n lò kéré, àpapọ̀ gbogbo ẹ̀ jẹ́ 296.

Òmíràn ni pé àwọn aṣèwádìí kò lè fi ipa tí àwọn ohun bí àìlẹ́jẹ̀tó, ìṣakọṣabo, ọjọ́-orí, àti àkókó tí wọ́n ti fi wọ́n pamọ́ lórí bóyá àwọn ẹ̀jẹ̀ àyẹ̀wò náà yóò jási bẹ́ẹ̀ ni tàbi bẹ́ẹ̀ kọ́.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?