Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1101/2021.02.11.429702
Yoruba translation of DOI: 10.1101/2021.02.11.429702
Ìgbógun ti ìpakòkòrò ń fún ewu àìsàn tí ó ti ara kí kòkòrò géni jẹ tí ó ń jà rànìn-rànìn àti òye sí ipa iye òǹkà ènìyàn tí ó lápẹẹrẹ láti ṣàfihàn ìtànkálẹ̀ kíá sí ìṣàfihàn ìyanni tuntun.
Ìlò ìpakòkòrò párẹ́tọ́ìdì ni ìṣàkóso ibà ṣì fẹ̀yìn tì jùlọ, ní pàtó nínú àwọn àwọ̀n ìpakòkòrò alálòpẹ́ (LLINs), ìdojúkọ àwọn ògìdi ẹ̀fọn tí wọ́n ń fà ibà ti pọ̀ si ní nǹkan bí ọdún 15 sẹ́yìn pẹ̀lú ìpolongo àti bí wọ́n ṣe fẹ pínpín LLIN lójú.
Dídá àwọn ète ajẹmọ́ran tí wọ́n jẹ́ ìpìlẹ̀ fún agbára-ìdojúkọ ńlá nínú àwọn ẹ̀fọn, èyí tí ó lè sọ pyrethroid di ọ̀lẹ pátápátá, ṣe pàtàkì fún ìgbéǹde àti ìlò àwọn ohun tí ó lè já agbára-ìdojúkọ wálẹ̀.
Ṣíṣe àmúlò dátà apó gíìnì Anopheles gambiae 1000 (Ag1000g) a tọ́ka sí ìdìde àwọn ẹ̀fọn lahti Uganda èyí tí ó sọ ìdìgíìnì sátókóòòmù P450, pèlú àwọn tí ó wọ́pọ̀ kọ̀ọ̀an di ohun tí ó lágbára-ìdojúkọ.
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ síwájú síi ṣàfihàn ìdí àwọn ìdì gíìnì tí wọ́n wà lórí okùn ìran kanṣo, tí ibi àyípadà wọn ní Cyp6p4 (I236M) kò jọra, tí ó gbà ọ̀nà mìíràn bíi ti Zanzibar (TE) àti ìṣèlọ́pogíìnì Cyp6aa1.
Àwọn àyípadà náà jọ èyí tí ó wáyé ní kọ̀pẹ́kòpẹ́ ní AN, gambiae ní ààlà-ilẹ̀ Kenya-Uganda ní sàkáání oni-adágún Victoria, pẹ̀luh ìṣèrọ́pò àyípadà oníbèjì lẹ́sẹẹsẹ (TE ti Zanzibar àti Cyp6p4-236M) pẹ̀lú àyípadà ìdì gíìnì onihlọọ́po mẹ́ta (lahra rẹ̀ ni àlòtúnlò Cyp6aa1) èyí tí ó ti tàn wọ il̀ Olómìnira Congo àti Tanzania.
Àyípadà ìdì àwọn ẹ̀yọ́ ìran onílọ̀ọ́po-mẹ́ta ní ìbáṣe tí ó nípọn pẹ̀lú bi àwọn gíìnì ṣe ń sọ párẹ́tọ́ìdì di èròjà ara, tí ó sì ń fún wọn lahgbára láti dojú kọ párẹ́tọ́ìdì pàápàá jùlọ dẹtamẹtíìn, tí ó jẹ́ LLIN tí wọ́n máa ń sáàbà lò fún ìpakòkòrò.
Ní pàtàkì, kíkú àwọn ẹ̀fọ̀n tí wọ́n ní àyípadà-onílọpomẹta pọ̀ si nígbà tí wọ́n kojú àwọ̀n tí wọ́n pèlò rẹ̀ papọ̀ mọ́ synergist piperonyl butoxide (PBO).
Ìṣọwọ́jẹyọ àwọn àyípadà ìdìgíìnì onílọ̀ọ́po-mẹ́ta jẹ́ ohun tí ó yàtọ̀ síra nípa ipò, ibi àti títóbi láti ìlú dé ìlú, èyí ń dábàá ìlànà tí yóò ṣe atọ́nà fún ìpinnu lórí ìlò àti pínpín PBO jákèjádò ilẹ̀ Áfíríkà.
Ìṣèlọ́pogíìnì Cyp6aa1 wọ́pọ̀ nínú An.Gambiae jákèjádò Áfíríkà, àti pé bí a bá wo ìyòrò ẹ́ńsáìmù ó lè wúlò fún ìdámọ̀ àìsàn fún agbára-ìdojúkọ pyrethroid ńlá.
Àwọn mìíràn nínú àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n ń tan ibà kálẹ̀ ti ń ṣe àyípadàgíìnì wọn láti ohun tí ó lè dojúkọ àwọn ohun ìpakòkòrò tí ó wọ́pọ̀.
Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n máa ń ye àwọn kẹ́míkà olóró tí ó máa ń wà nínú àwọ̀n ìpẹ̀fọn, èyí tí ó túnbọ̀ fi àwọn ènìyàn sínú ewu níní àìsàn ibà.
Àwọn aṣèwádìí ti wá rí àwọn àyípadà ajẹmẹ́yọ-ìran tí ó lè máa ṣe àtọ́kùn fún ìgbàmọ́ra yìí.
Wọ́n ní ṣíṣe àfikún kẹ́míkà mìíràn tí wọ́n ń pè ní (PBO) sí àwọn àwọ̀n ìpẹ̀fọn lè ṣèrànwọ́ dídarí ó kéré tán ẹlyà ẹ̀fọn aṣèdojúkọ kan.
Àrùn olóró tí àwọn ẹ̀yà ẹ̀fọn kọ̀òkan máa pín ni ibà.
Ọkan lára àwọn ohun ìdáàbòbò lọ́dọ̀ ibà tí wọ́n ń lò jùlọ ni àwọ̀n tí wọ́n fi pyrethroid pèlò rẹ̀ tí ó sì ní àlòpẹ́.
Pyrethroid jẹ́ irúfẹ̀ ìpakòkòrò kan, tí ó jẹ́ ohun tí wọ́n fi ń àwọn kòkòrò bíi ẹ̀fọn.
Ó ṣeni láàánú pé àwọn ẹ̀fọn ti yí padà láti fara da pyrethroid, èyí tí ó túmọ̀ sí pé àwọn àwọ̀n wọ̀nyí kò ṣiṣẹ́ mọ́ fún ìṣàkóso ibà ní àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan.
Àwọn aṣèwádìí fẹ́ mọ ohun náà gan-an ní pàtó tí ó yí DNA àwọn ẹ̀fọn aṣèdojúkọ padà tí ó jẹ́ kí wọ́n lè yẹ párẹ́tọ́ìdì sílẹ̀.
Wọ́n fẹ́ tọ́ka sí àwọn gíìnì kọ̀ọ̀kan ní pàtó tí ó ń ṣe àtìlẹ́yìn fún ìṣèdojúkọ párẹ́tọ́ìdì yìí, àti bi ìṣedojúkọ yìí ṣe ń wáyé (ète rẹ̀).
Òmíràn ẹ̀wẹ̀, wọ́n fẹ́ fẹnu kò lórí bí ara ẹ̀fọn sọ parẹ́tọ́ìdí di èròjà tí ara lè lò níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé kẹ́míkà olóró ni.
Àwọn aṣèwádìí ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn gíìnì tí àwọn ẹ̀fọn Anopheles gambiae ni, tí wọ́n wọ́pọ̀ ní Kenya, Uganda, àti àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà mìíràn.
Lọ́gán tí wọ́n ti tọ́ka sí àwọn ẹ̀yọ́-ìran kọ̀ọ̀kan ní pàtó àti àwọn ètò tí ó wà lẹ́yìn agbára tí àwọn ẹ̀fọn fi ń dojúkọ párẹ́tọ́ìdì, wọ́n gbìyànjú láti fi àwọn kẹ́míkà mìíràn kún àwọ̀n láti wò ó bóyá àwọn ẹ̀fọn náà yóò tún yè é.
Àwọn aṣèwádìí rí àwọn àyihpadàgíìnì mẹ́ta tí ó ń jẹ́ kí ẹ̀fọn gba kẹ́míkà sára.
Wọ́n ní o lè jẹ́ pé àwọn àyípadà náà ń se àǹfààní fún àwọn ẹ̀fọn ní àwọn ọ̀nà mìíràn náà, torí pé ó jọ bí ẹni pé ìtànká wọn yá kíákíá nínú àwọn òǹkà iye tí àwọn aṣèwádìí fi ṣiṣẹ́.
Ó dà bí ẹni pé àwọn àípadà náà bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè ààlà-ilẹ̀ Kenya-Uganda lágbègbè adágún-omi Victoria.
Wọ́n tún sọ pé ó jọ pé àyípadà onílọ̀ọ́po mẹ́tà yìí ń jẹ́ kí àwọngíìnì lè sọ ìpakòkòrò di èròjà tí ara lè lò lọ́nà tó pọ̀, tí ó sì ṣe àsọtẹ́lẹ̀ ipá láti ṣe ìdójúkọ párẹ́tọ́ìdì.
Ní ìpárí, wọ́n fẹnu kò pé ṣíṣe àfikún kẹ́míkà piperonyl-butoxide (PBO) sí párẹ́tọ́ìdì lásìkò ìtọ́jú àwọ̀n ní ipá tí ó pọ̀ láti bórí agbá-ìdojúkọ àwọn ẹ̀fọn wọ̀nyí.
Àwọn iṣẹ́ ìwádìí àtẹ̀yìnwá dojú kọ àwọngíìnì kọ̀ọ̀kan tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì lérò pé wọ́n lè máa ṣàtilẹ̀yìn fún agbára ìdojúkọ ìpakòkòrò nìkan ní pàtó.
Ìwádìí náà fẹ ẹ́ lójú nípa wíwo ogunlọ́gọ ̀gíìnì láti rí àwọn àyípadà tí ó wọ́pọ̀ nínú àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n nị agbára ìdojúkọ.
Àwọn aṣèwádìí sọ pé kò ṣeé ṣe kí wọ́n ti ara ìwádìí wọn mọ àwọn ipa mìíràn tí àwọn àyípadà tí wọ́n tọ́ka sí lè ní, àbí àwọn ọ̀nà wo ní pàtó ni àyípadà kọ̀ọ̀kan ń gbà ní ipa lórí agbára-ìdijúkọ párẹ́tọ́ìdì.
Wọ́n sọ pé àwọn ẹ̀yà ẹ̀fọn mìíràn tí wọ́n ní irúfẹ̀ àyípadà kannáà ni agbára-ìdojúkọ wọn sí kẹ́míkà-apakòkòrò ń pọ̀ si.
Àmọ́, ó rújú bóyá bí wọ́n bá fi apakòkòrò bíi PBO kún un yóò pa àwọn ẹ̀yà aṣèdojúkọ mìíràn náà.
Àwọn aṣèwádìí láti Kenya, Uganda, Congo, Tanzania, Kilifi, UK àti USA ni wọ́n parapọ̀ ṣiṣẹ́ nínú ìwádìí yìí.
Àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n wà ní ààlà ilẹ̀ Kenya-Uganda ni wọ́n dojú kọ, èrò tuntun wọn láti Sàfikún PBO sí àwọn àwọ̀n le la ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ara ilẹ̀ Áfíríkà.