Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù a máa halẹ̀ mọ́ onírúurú ewé àti ẹranko ní orílẹ̀ èdè South Africa.

Yoruba translation of DOI: 10.1007/978-3-030-32394-3_17

Published onMay 19, 2023
Ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù a máa halẹ̀ mọ́ onírúurú ewé àti ẹranko ní orílẹ̀ èdè South Africa.
·

Ìgbéléwọ̀n ipa tí ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù ńkó lórí onírúurú ewé àti ẹranko ní orílẹ̀ èdè South Africa, pẹ̀lú lílo oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìgbéléwọ̀n

 Ìwádìí lórí ipa tí ọ̀wọ́ àwọn àjòjì ọganisíìmù ń kó ní àwùjọ́ ń gbèrú síi, bákan náà si tún ni ìjíròrò ń lọ lọ́wọ́ lórí bí bí a ṣe le è ṣe ètò àpejúwe ipa wọ̀nyí.

Ìpín yìí ṣe ìgbéléwọ̀n ipò ìmọ̀ lórí ipa tí ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù ńkó lórí onírúurú ewé àti ẹranko ní orílẹ̀ èdè South Africa, nípa lílo oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìgbéléwọ̀n.

Bí orílẹ̀ èdè South Africa ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè ní àgbáyé, tí ó ní onírúurú ohun ẹlẹ́mìí jùlọ, ìṣẹ́ iwadìí péréte ni ó wà ní àkọsílẹ̀ lórí ipa tí ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù ńkó lórí onírúurú ewé àti ẹranko.

Púpọ̀ nínú àwọn ohun tí àwọn ènìyàn mọ̀ wá láti ara èrò àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, fún ìdí èyí ipò ìdánilójú nínú ìfojúdá bí àwọn ipa yìí ti gbilẹ̀ tó kéré.

Síbẹ̀, ó hànde pé iyé tí ó pọ̀ nínú àwọn ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù ni ó kó ipa tí kò dára, àti pé ohun tí ó gba àmójúto gidi ni.

Ní gbogbo àgbáyé ni akitiyan ti ń wáyé kí ọwọ́ lè ba gbogbo ọ̀wọ́ àwọn àjòjì ọganisíìmù nípa ṣíṣe àmúlò ìlàna-ipa alábọ́de láti paná ìṣòro lílo onírúrú ìlànà.

Àkọsílẹ̀ ìgbéléwọ̀n ti wà fún díẹ̀ lára ọ̀wọ́ àwọn àjòjì ọganisíìmù ní South Africa, ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú àwọn ọ̀wọ́ tí wọ́n ti dí ti ìbílẹ̀ àti ọ̀wọ́ àwọn ọgáńsíìmù aṣàkóbá- fun-ni ni kò tíì ní ìgbéléwọ̀n, bẹ́ẹ̀ sì ni a fúnra pé, fún ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ àwọn àjòjì wọ̀nyí, kò tíì sí ìgbìyànú láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ipa tí wọ́n ń kó.

Síbẹ̀, ìgésẹ àtòjọ-ewu fi hàn pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọhn máa ń ṣe àfikún ọ̀wọ́ àwọn àjòjì ọgánísihìmù gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ewu tih ó máa ń fa ìparun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀wọ́ àwọn ẹja, ọ̀pọ̀lọ́ àti ewéko ìbílẹ̀.

Iṣẹ́ ìwádìí lórí àkópọ̀ ipa ọ̀wọ́ àwọn àjòjì ní àwọn agbègbè kan kò wọ́pọ̀, àti pé iṣẹ́ ìwadìí wọ̀nyí le è pèsè ọgbọ́n inú fún ìlànà òfin àti àmójútó, èyí tí kìí sí ní ọ̀pọ̀ ìgbà.

Nígbàtí àdínkù wà látàrí iye ọ̀wọ́ àwọn àjòjì ọganisíìmù tí ó wà nínú ètò ìbaṣepò, àmúwá-iṣẹ́ ti ilẹ̀ gbígbẹ àti dídúró déédé onírúurú ewé àti ẹranko kéré jọjọ lọ́wọ́lọ́wọ́ èrò ni pé àwọn ipa wọ̀nyí máa gbèrú kíákíá bí ọ̀wọ́ àwọn ọgáńsíìmù aṣàkóbá- fun-ni ti ń wọ ipò ìdàgbàsókè tó rinlẹ̀.


Ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù a máa halẹ̀ mọ́ onírúurú ewé àti ẹranko ní orílẹ̀ èdè South Africa.

Àwọn oníṣẹ́ ìwádìí ṣe àfiwe àwọn iṣẹ́ ìwadìí tí ó ti wà nílẹ̀ láti dá ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù tí ó jẹ́ ìṣòro fún àwọn onírúurú ewé àti ẹranko ti orílẹ̀ èdè South Africa.

 Orílẹ̀ èdè South African jẹ́ ọkan gbòógi lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ni onírúurú ewé àti ẹranko jùlọ ní àgbáyé.

Ó kéré tán 107 ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù, ní èyí tí ìdá 75 jẹ́ ohun ọ̀gbìn, ni a funra pé wọ́n ń kó ipa burúkú lórí onírúurú ewé àti ẹranko orílẹ̀ èdè náà.

Ipa tí ó jọ pé àwọn ọ̀wọ́ ọganisíìmù wọ̀nyí ńkó kò hànde, nítorí kò tíì sí àkànṣẹ iṣẹ́ ìwádìí tí ó ṣe àfihàn èyí ní pàtó.

 Ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù wọ̀nyí le è mú àdínkù bá onírúurú ewé àti ẹranko ní onírúurú ọ̀nà.

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà náà ni a mọ̀ sí ìfọmọ-irú-yọ-lára ọ̀wọ́-ọ̀tọ̀-méjì, ní ibi tí orírun wọ́n ti dàpọ̀ mọ́ ọ̀wọ́ àwọn ọganisíìmù ìbílẹ̀.

Ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn ọganisíìmù àjòjì tún le è pa Ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn ọganisíìmù ìbílẹ̀ run pátápátá.

Ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù tún le è ṣe okùnfà àwọn àìsàn tuntun, tí yóò si tún fa àkóbá fún agbègbè, bí i igi tí ó ń ṣe àmúlọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi láti ọ̀gbun ilẹ̀.

Iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àgbàjọ gbogbo ìmọ̀ tí ó wà nípa Ipa tí ó jọ pé àwọn ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ ọganisíìmù wọ̀nyí ńkó kò lórí onírúurú ewé àti ẹranko ti orílẹ̀ èdè South Africa.

 Oníṣẹ́ ìwádìí wo bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ ọganisíìmù tí ó jẹ́ àjòjì wọ̀nyí ti ṣe mú àyípadà bá ètò ìbaṣepò àwọn ọganisíìmù tí wọ́n jẹ́ ti ìbílẹ̀, àti irúfẹ́ ọ̀wọ́ àwọn ọganisíìmù ìbílẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ìsọ̀ro fún.

Wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ tí ó ló ìlàna ìmọye-ipa alábọ́de, bákan náà ni wọ́n tún bá àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ sọ̀rọ̀ láti mọ èrò wọn.

Bákan náà ni wọ́n tún wo Ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn ọganisíìmù ìbílẹ̀, èyí tí ó ti ń lọ sí ìparun, wọ́n si lo “àkójọ” yìí láti wo bóya ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù kó ipa Kankan nínú ìparun wọn.

Iṣẹ́ ìwadìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì ẹranko-onítete (̀igbín àti ẹranko alọra), ẹja, ẹranko afọmọlọ́mú àti eweko ni wọ́n le è ṣe okùnfa ìsòrò fún ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn ọganisíìmù ìbílẹ̀.

 Fún àpẹẹrẹ, ìgbí tí a mọ̀ sí Tarebia granifera jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹranko-onítete aṣàkóbá- fun-ni South Africa.

Ó ti kógunja ọ̀pọ̀lọpọ̀ odò, ìsun, ilẹ̀ omi àti ẹnu odò ní ìhà ìlà oòrùn àti ìhà àríwá orílẹ̀ èdè náà, ní ibi tí ó ti jẹ́ gàba lórí àwọn ọ̀wọ́ ìgbín ìbílẹ̀.

 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ ẹja márùn ún tí wọ́n jẹ́ aṣàkóbá- fun-ni tí wọ́n mọ ipa rẹ̀ ní orílẹ̀ èdẹ̀ South Africa ní ẹja tí a mọ̀ sí Largemouth Bass.

Ó ti pa ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ ẹja ìbílẹ̀ dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ẹ̀ ẹ́ parun tán ninú gbogbo omi orílẹ̀ èdè South African.

Fún àwọn ẹranko afọmọlọ́mú, ìwádìí fi hàn pé ekú dúdú aṣàkóbá- fun-ni ni (Rattus rattus) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ogún-lọ́gọ̀ ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ ródẹ́ǹtì àjèjì tí ó ti mú ìparun bá àwọn ẹyẹ, kòkòrò, àdán, àti ọ̀wọ́ àwọn ródẹ́ǹtì mìíràn nípa dídọdẹ wọn, jíjẹ oúnjẹ wọn àti kíko ààrun ràn wọ́n.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ipa àwọn ọ̀wọ́ àjèjì wọ̀nyí lórí ìpín ewé àti ẹranko kò wọ́pọ̀ púpọ̀, àwọn oníṣẹ́ ìwádìí fi lélẹ̀ pé, tí orilẹ̀ èdè South Africa kò bá dẹ́kùn ìdàgbàsókè wọn, ipa wọ́n yóò máa burú sí i ni.

Ìṣẹ ìwádìí yìí jẹ́ igbéṣẹ̀ àkọ́kọ́ sí ìfimúlẹ̀ bí a ṣe le è ṣe òdiwọn ipa àwọn ọ̀wọ́ ọganísíìmu àjèjì lórí ìpín ewé àti ẹranko ni South Africa.

 Nígbàti iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àṣeyọrí lórí ìgbéléwọ̀n iye ìbàjẹ́ tí àwọn ọ̀wọ́ ọgánísíìmù aṣàkóbá- fun-ni i ṣe ní South Africa, kò le è ṣe ìṣirò ibi tí ìbàjẹ́ náà ṣe ni ìgbà tí àwọn ọ̀wọ́ àjèjì ọ́gánísíìmù wọ̀nyí bá ju ẹyọ kan lọ nínú ètò ìbaṣepò ìbílẹ̀.

Láì sí irúfẹ́ iṣẹ́ ìwádìí yìí, àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gbogbo kò ní ní ìmọ láti dáàbò bo àwọn onírúurú ewé àti ẹranko ìbílẹ̀.

Fún ìsìnyí, ohun tí olùwádìí gbà ní ìmọ̀ràn ni pé kí òfin South Africa gbájú mọ́ ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ àwọn àjòjì ọganisíìmù tí bébà yìí mẹ́nubà láti dẹ́kun ìbàjẹ́ àwọn onírúurú ewé àti ẹranko ìbílẹ̀.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?