Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Ìwọ́pọ̀ Àìlèṣe-bí-ọkùnrin lára aláìsàn tí ó ní Àìsàn ìtọ-ṣúgà àti àwọn àsomọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìwọn òòrìn tòhun gíga tìbútòró àti Imogilobíìnì ajẹmọ́-ṣúgà ní Ilẹ̀ Áfíríkà

This is Yoruba translation of DOI: 10.1155/2020/5148370

Published onJul 24, 2023
Ìwọ́pọ̀ Àìlèṣe-bí-ọkùnrin lára aláìsàn tí ó ní Àìsàn ìtọ-ṣúgà àti àwọn àsomọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìwọn òòrìn tòhun gíga tìbútòró àti Imogilobíìnì ajẹmọ́-ṣúgà ní Ilẹ̀ Áfíríkà
·

Ìwọ́pọ̀ Àìlèṣe-bí-ọkùnrin lára aláìsàn tí ó ní Àìsàn ìtọ-ṣúgà àti àwọn àsomọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìwọn òòrìn tòhun gíga tìbútòró àti Imogilobíìnì ajẹmọ́-ṣúgà ní Ilẹ̀ Áfíríkà:

Àtúngbéyẹ̀wò oníṣíṣẹ̀ntẹ̀lé àti àtúpalẹ̀ tó gbòòrò.

Abstract

Ìpàjùbà.

Ìṣẹ̀lẹ̀-ikú àti ààrùn kíkó tí ó jẹ mọ́ àwọn aláìṣà tí ó ní ìtọ̀-ṣúgà (DM) jẹ́ kíkà sí ara ṣégeṣège àwọn òpó ńláńla àti kéékèèké.

Àmọ́ ṣá, iye oríṣìí ìkẹ́kọ̀ ìpìlẹ̀ nípa DM tí ó nííṣe pẹ̀lú ìwọ́pọ̀ àìlèṣe-bí-ọkùnrin (ED) ní ilẹ̀ Áfíríkà pọ̀ púpọ̀.

Nítorí náà, iṣẹ́ ìwádìí yìí gbèrò láti ṣe ìṣirò ìwọ́pọ̀ àwọn aláìsàn ED tí ó ní DM àti àwọn àsomọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òòrìn tòhun gíga tìbútòro (BMI) àti imogilobíìnì ajẹmọ́-ṣúgà ní Ilẹ̀ Áfíríkà.

Àwọn ọ̀nà àágbegbà.

PubMed, Web of Science, Cochrane Library, Scopus, PsycINFO, African Journals Online, àti Google Scholar jẹ́ yíyẹ̀wò fún àwọn iṣẹ́ tí ó sọ nípa ED lára àwọn aláìsàn DM.

Ète Àyẹ̀wò fọ́nẹ́ẹ̀lì àti Egger jẹ́ lílò láti mọ àìṣedéédé àwọn iṣẹ́ ìwádìí.

Ìṣirò I2 jẹ́ lílò láti wo àwọn ìyapa inú iṣẹ́ náà.

Òpó ipa-aláyìípo DerSimonian àti Laird jẹ́ lílò láti ṣèṣirò ìwọ̀n ìrinlẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí náà.

Ìtúpalẹ̀ ọ̀wọ́lọ́wọ̀ọ́ àti ìtúpalẹ̀ ajẹmọ́-mẹ́tà jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú orílẹ̀-èdè, ìwọn iṣẹ́, àti ọdún tí a gbé iṣẹ́ jáde.

Ìtúpalẹ̀ aláfojúlẹ̀ṣe jẹ́ lílò láti rí ipa iṣẹ́ kan ṣoṣo lórí ìṣirò àbájáde àpapọ̀.

Ẹ̀yà 14 irin-iṣẹ́ aṣèṣirò aláìrídìmú STATA jẹ́ lílò fún àtúpalẹ̀ tó gbòòrò náà.

Èsì.

Àpapọ̀ iṣẹ́ ìwádìí 13 pẹ̀lú 3,501 àwọn akópa jẹ́ lílò nínú iṣẹ́ ìwádìí náà.

A ṣèṣirò pẹ́ ìwọ̀n ìwọ́pọ̀ ED lára àwọn aláìsàn tí ó ní DM ní ilẹ̀ Áfíríkà jẹ́ 71.45% (95% CI: 60.22–82.69).

Àwọn aláìsàn ìtọ-súgà tí BMI wọ́n ≥30 kg/m2 ṣeéṣe kí wọn ó jẹ ED (AOR = 1.26; 95% CI: 0.73–2.16) yọ pẹ̀lú 1.26 ìgbà àti àwọn tí imogilobíìnì ajẹmọ́-ṣúgà wọn jẹ́ <7% were 7% ṣeéṣe kí ó má jẹ ED (AOR = 0.93; 95% CI: 0.5–5.9), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní àsopọ̀ pẹ̀lú ED lójú páálí.

Ìkádìí.

Ìwọ́pọ̀ ED lára àwọn aláìsàn DM ní Áfíríkà gbé sókè síbẹ̀.

Nítorí náà, ọ̀nà-àbáyọ̀ tó bàsẹ̀lẹ̀ wí àti ètè ìdèènà ajẹmọ́lù tó forísọ̀ṣẹ̀lẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ gbígbé kalẹ̀ láti mú àdínkù bá ìwọ́pọ̀ ED láàrin àwọn aláìsàn tí ó ní DM.

Summary Title

70% àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní ìtọ-súgà ní ilẹ̀ Áfíríkà ni kò lè ṣe bí ọkùnrin.

Ẹgbẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn aláìsàn ìtọ-súgà káàkiri àgbááyé ni ó bá àìlèṣe-bí-ọkùnrin fínra, àmọ́ ṣá, iye rẹ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà kò hàn síta di àsìkò yìí.

Ó súnmọ́ mílíọ̀nù 425 àwọn ènìyàn tí ó bá àìsàn ìtọ-súgà (DM) fínra káàkiri àgbááyé lọ́dún 2017, èyí sì ń gòkè láti tó mílíọ́nù 629 lọ́dún 2045.

Ìṣoro ìtọ-ṣúga kan tí ó gbajúgbajà tí a kò sì tí ì kàsí ni àìlèṣe-bí-ọkùnrin (ED), tí ó túmọ̀ sí àìlè mára le láti fi ààye gba ìbálòpọ̀ débi ìgbádùn.

Ìròyìn À̀ìlèṣe-bí-ọkùnrin ti gbígbé jáde lára 49% iyé àwọn ọkùnrin tí ó ní ìtọ-ṣúga ní orílè-èdè England, 35.8% ní Italy, 77.1% ní South Africa, àti 67.9% ní Ghana.

Àmọ́, àwọn àbájáde mìíràn ní ilẹ̀ Áfíríkà yàtọ̀ púpọ̀púpọ̀, nítorí náà, àwọn aṣèwádìí ṣe àfiwéra àbájáde láti mọ bí àìlèṣe-bí-ọkùnrin ṣe wọ́pọ̀ tó lára aláìsán ìtọ-ṣúgà, àti láti sọ àwọn asomọ́ tí ó ṣeéṣe kí ó so mọ́ ara-àsanjù àti àpọ̀jù ṣúgà nínú ẹ̀jẹ̀.

Àwọn aṣèwádìí wo àwọn yàrá ìkàwé PubMed, Web of Science, Cochrane Library, Scopus, PsycINFO, African Journals Online àti Google Scholar fún àwọn iṣẹ́ ìwádìí tí ó wo àìlèṣe-bí-ọkùnrin lára aláìsàn tí ó ní ìtọ-ṣúgà.

Wọ́n lo oríṣiríṣi ìlànà ìtúpalẹ̀ láti ṣe àtúpalẹ̀ àwọn àbọ̀ inú ìwádìí 13 léyìí tí ó ní àpapọ̀ 3,501 akópa.

Wọ́n fi ojú sílẹ̀ ṣe àtúpalẹ̀ láti rí i pé ọ̀kankan àwọn iṣẹ́ ìwádìí náà kò nípà lórí òmìíràn, léyìí tí ó lè dábùú àbájáde gbogbogbò okùnfà ìwọ́pọ̀ àìlèṣe-bí-ọkùnrin lára àwọn akópa.

Iṣẹ́ ìwádìí náà ṣàkíyèsí pé àìlèṣe-bí-ọkùnrin wọ́pọ̀ lára 71.45% àwọn ọkùnrin aláìsàn ìtọ-ṣúgà ní ilẹ̀ Áfíríkà.

Wọ́n sàwárí pé àwọn aláìsàn ìtọ̀-ṣúgà tí ó ní ìwọn òòrìn tòhun gíga tìbútòro tí ó fi ara àsanjù hàn ṣeéṣe; kí ó jẹ àìlèṣe-bí-ọkùnrin yọ ní pẹ̀lú ìdá 1.26 ìgbà.

Wọ́n tún ṣàwárí pé àwọn aláìsàn ìtọ̀-ṣúga tí ìmójútó súgà inú ẹ̀jẹ̀ wọn dàra, gẹ̣́gẹ́ bí imogilobíìnì ajẹmọ́-ṣúgà 7%, ìwọ̀n àmójútó súgà ọjọ́ pípẹ́, ṣeéṣe pẹ̀lú 7% ó dín kí ó bí àìlèṣe-bí-ọkùnrin.

Iṣẹ́ ìwádìí náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ akùdé tí ó yẹ ní mímójú tó nínú àwọn ìwádìí ọjọ́ iwájú.

Àkọ́kọ́, ó ṣòro láti sọ pé bóyá àwọn èsì láti àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo ń ṣojú fún gbogbo ilẹ̀ ni, ìdí ni pé a kò ṣàwárí dátà kankan fún gbogbò ilẹ̀ Áfíríkà.

Ìkejì, àkọsílẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì nìkan ni iṣẹ́ ìwádìí yìí gbé yẹ̀wò léyìí tí ó jẹ́ pé iṣẹ́ ìwádìí náà le máa pàdánù àwọn dátà tí a fi èdè mìíràn gbé jáde.

Èsì wọ̀nyìí ṣe àfihàn bí ìwọ́pọ̀ àìlèṣe-bí-ọkùnrin ní ilẹ̀ Áfíríkà ṣe gbé sókè síbẹ̀.

Àwọn Aṣèwádìí dá a lábàá pé kí àwọn orílẹ̀-èdè ó sẹ̀dá ọ̀nà-àbáyọ̀ tó bàsẹ̀lẹ̀ wí fún orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?