Description
This is a lay summary of the research article published under the DOI: 10.1101/2020.06.04.20119594
Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.06.04.20119594
Láti ṣe òdiwọn ìrànmọ́ni àti ikú látàrí Àrùn Covid-19 láàárin àwọn òṣìṣẹ́ ìlera (HCWs) káàkiri àgbáyé.
Èto Àtúpalẹ̀.
Ìwádìí ọlọ́nà-méjì lóri ìwé ìtọ́kasí iṣẹ́ akadá àtilítíréṣọ̀ gíréè ní ó wáyé lẹ́ẹ̀kan náà.
Bákan náà ni wọn sọwọ́ sí àwọn ìjọba láti fún wọ́n ni àwọn àkọsílẹ̀ tí wọ nílò.
Látàrí imọ̀sílára-àsìkò tí àgbéyẹ̀wò náà wáyé àti ìwulò tí ó wà láti jábọ̀ gbogbo àwọn dátà fún rògbòdìyàn tí kò ì tí ì dáwọ́ dúró, kò sì ààyè láti ṣe ọ̀fintótó il̀ò èdè, orísùn àwọn àkọsílẹ̀ tí a lò, ipò àwọn ìwé tí wọn ti tẹ̀ jáde àti irúfẹ́ orísun àwọn ẹ̀rí.
Ohun tí ó wà nínú ìwé àyẹ̀wò AACODS ní a lò láti ṣe àgbéyẹ̀wò orísun àwọn ẹ̀rí.
Ìrísí ìwé títẹjáde, orílẹ̀ èdè ní pàtó, kókó dátà, dátà àrùn Covod-19 ní pàtó, ìwọn iye àwọn òṣìṣẹ́ ìlera HCWs tí wọn fara kááṣá, àti irúfẹ́ ìgbéléwọ̀n ilera àrà ìlú tí wọn ṣàmúlò.
Àwọn tí wọ́n kó àrùn yìí jẹ́ 152,888 bẹ́ẹ̀ ènìyàn 1413 ní wọ́n sì ti kú.
Àwọn obìnrin ní àrùn yí ràn jùlọ (71.6%)) àti àwọn nọ́ọ̀sì (38.6%), ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin ni ó kú jùlọ (70.8%) àti àwọn dókítà (51.4%).
Ìwọ̀nbà Dátà fihàn pé àwọn òṣìṣe ìleragbogboogbò àti àwọn nọ́ọ̀sì tí wọ́n wà ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń wo àwọn àrùn ọpọlọ far aní àwọn tí wọ́n kú jùlọ.
Nínú àwọn 100 tí wọ́n kó àrùn yìí 37.17 ní ó kú lára àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tí wọ́n ti pé ọmọ 70 ọdún.
Europe ni ó ni iye àwọn ènìyàn tí ó kó àrùn yìí jùlọ ọ̀kẹ́-mẹ́fà dín ní èjìlá ní ọ̀tà lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún (119628), tí àwọn tí ó sì kù jẹ́ ẹ̀jọ̀ dín ni okòó-lé-ní-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (712), ṣùgbọ́n agbègbè ìwọ̀ oòrùn Mediterranean ni àwọn ènìyàn tí ó kó àrùn yìí ti kú jùlọ, márùn ún àti méje (5.7) nínú 100 àwọn tí ó kó àrun.
Ìrànmọ́ni àti Ikú àwọn òṣìṣẹ́ ìlera (HCWs) látàrí àrùn Covod-19 ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà iye gbogbo àgbáyé.
Ìdí ìlo ìyàtọ̀ ako-n-babo àti àṣàyàn iṣẹ́, gba àòtúnwò, nítorí ohun tí wọ́n kéde láti Áfíríka àti Indíà keré jọjọ.
Àwọn oníṣègùn tó ń ṣiṣẹ́ ní àṣàyàn àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan le è wà nínú ewu àti ṣe àgbákò àrun yìí jùlọ látàrí bí wọn ṣe máa ń ṣe alábáapàde oríṣìí ìsun ara, bẹ́ẹ̀ ni ewu tí àwọn tí wọ́n wà ni ẹ̀ka mìíràn ń kọjú pàápàá kò ṣe é fojú fò.
Ó yẹ kí wọ́n fi àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tí wọ́n ti dàgbà sí àwọn ipò tí kò ní ewu púpọ̀, bíi ẹ̀ka tó ń lo ẹ̀rọ ìbẹ́nisọ̀rọ̀ pẹ̀lú aláìsàn tàbí ipò ìṣẹtò.
Ìlànà ìlo ìṣe wa pèsè ìmọ̀ lóri bí nǹkan ṣe ń lọ káàkiri, ó sì pe àkíyàsí sí ìdí tí a fi gbọdọ̀ ni ìlànà ìṣàyẹ̀wò àti ìfíṣọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tí wọn ti kó àrùn yìí káàkiri àgbàyé.
Àwọn òṣìṣé ìlera, àwọn òṣìṣe ìlera gbogboogbò ní wọ́n fara kááṣá Àrun Covid-19 jùlọ
Nínú làáṣìgbò Àjàkálẹ̀ Àrun Covid-19, àwọn òṣìṣé ìlera káàkiri àgbayé fí ẹ̀mi wọn wéwu láti dóòlà ẹ̀mí àwọn yòókù.
Iṣẹ́ ìwadìí yìí jẹ́ àkọ́kọ́ tí ó ṣe àyẹ̀wò bí Àjàkálẹ̀ Àrun náà ti kọlù àwọn òṣìṣé ìlera tó, àti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọ́n wà ní gbàgede kíkó Àrun Àrànmọ́-ni àti ikú.
Láti ara àṣùpọ̀ àwọn aláìsàn tí ó ní àmì àìsàn làkúrègbé tí ó so mọ́ ọjà olómi ni Wuhan, China ní bíi òpin oṣù Ọ̀pẹ 2019, àìsà kòrónà (àrun Covid-19) ti fẹ́ lójú di àjàkálẹ̀ àrùn ní gbogbo àgbàyé.
Ní àsìkò tí iṣẹ́ ìwadìí yìí ń lọ lọ́wọ́, ní oṣù Èbìbí ọdụ́n 2020, ó tó mílíọ́nù márùn-ún àwọn ènìyàn tí wọ́n tí kó àrùn yìí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ti kú tó 300,000 ènìyàn.
Àwọn tí wọ́n wà ní ojú agbami làálàá yìí ni àwọn òṣìṣé ìlera (HCWs) tí wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò àti ìtọ́jú fún ọ̀wọ́ àwọn aláìsàn tí àrùn yìí ti wọ̀ lára, ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí wọ́n ni láti ṣe ìpinnu nínú àwọn ipò tí ó lágbára tí a lè fi ojú rí àti èyí tí ó gba gba ọgbọ́n inú.
Eyí ti jú àwọn òṣìṣé ìlera (HCWs) sí inú ewu kíkó àrùn àti ikú, ṣùgbọ́n a kò mọ iye àwọn ti wọ́n ti fara kááṣá.
Fún ìdí èyí, iṣẹ́ ìwadìí yìí ṣe àgbéyẹ̀wò iye àwọn òṣìṣé ìlera (HCWs) tí wọ́n kó àrùn Covic-19 àti àwọn tí wọ́n kú ni gbogbo àgbáyé.
Àwọn olùwádìí ṣe àyẹ̀wò dátà nínú àwọn àkọ́sílẹ̀ iṣẹ́ akada àti àdàlú onírúurú orírun ìmọ̀ mìírà (tí a mọ̀ sí lítírésọ̀ gíréè), lára rẹ̀ ni àwọn dátà tí ìjọba gbà sílẹ̀ káàkiri àgbáyé, àwọn ìtàkùn àgbàyé ajẹmọ ìròyìn, àti àtẹ̀jáde orí ìtàkùn àgbáyé medRxiv.
Iṣẹ ìwádìí yìí fi hàn pé àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tí wọ́n kó àrùn Covid-19 yìí jẹ́ 152 888, nígbà tí ẹni 1413 ti kú látàrí àrùn yìí.yìí.
Àwọn obìnrin ní àrùn yí ràn jùlọ (ìdá mọ́kànlélàádọ́rin àti mẹ́fà - 71.6%)) àti àwọn nọ́ọ̀sì (ìdá méjìdínlógójì àti mẹ́fa - 38.6%), ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin ni ó kú jùlọ (ìdá ọgọ́rin àti mẹ́jọ - 70.8%) àti àwọn dókítà (ìdá mọ́kànléláàdọ́ta àti mẹ́rin -51.4%).
Lára àwọn dátà tí ó wà nílẹ̀, ìwádìí fi hànde pé àwọn oníṣegùn gbogboogbo (GPs) ní wọ́n wà nínú ewu àti ṣe àgbákò ikú jùlọ nínú àwọn dókítà, nígbàtí àwọn nọ́ọ̀sì tí ikú súnmọ́ pẹ́kì jẹ́ àwọ́n tí wọ́n wà ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń wo àwọn aláàrùn ọpọlọ.
Ní ibi tí olùwádìí mọ̀ mọ, èyí jẹ́ ìwádìí àkọ́kọ́ tí ó ṣe àgbéyẹ̀wò ìrànmọ́ni àti ikú láàrín àwọn òṣìṣẹ́ ìlera káàkiri àgbáyé látàrí àrùn Covid-19.
Ṣùgbọ́n ìwọn dátà tí ó wà nílẹ̀ tí wọ́n rí gbà, èyi tí ogúnlọ́gọ̀ dátà tí wọ́n gbà káàkiri wà nínú rẹ̀, jẹ́ kí iṣẹ ìwádìí wọn ni gbèdéke tí ó sì lè láti ṣe àfiwe.
Onírúurú orílẹ̀ èdè ni wọn wà ní ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú àjàkálẹ̀ àrun yìí ní àsìkò tí wọ́n gba dátà wọ̀nyí.
Ìrànmọ́ni àti Ikú àwọn òṣìṣẹ́ ìlera látàrí àrùn Covod-19 ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà iye gbogbo àgbáyé.
Ìdí ìlo ìyàtọ̀ ako-n-babo àti àṣàyàn iṣẹ́, gba àòtúnwò, nítorí ohun tí wọ́n kéde láti Áfíríka àti Indíà keré jọjọ.
Amharic translation of DOI: 10.1101/2020.06.04.20119594
Hausa translation of DOI: 10.1101/2020.06.04.20119594
Luganda translation of DOI: 10.1101/2020.06.04.20119594