Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1101/2020.11.16.384339
Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.11.16.384339
Bẹ́mìídíje ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ògidi àìlera-ẹ̀dọ tí ó sì lè jásí ìpelè tí ó kẹ́yìn àrùn ẹ̀dọ̀ lára àwọn aláìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí wọ́n ń ṣe ìkànpọ̀ ìtọ́jú ìkóràn adènàHIV (cART).
Iṣẹ́ ìwádìí wa fẹ́ ṣàyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ àti àwọn ohun tí ó ń se àsọtẹ́lẹ̀ ògidi àìlera-ẹ̀dọ̀ ti cART (CIH) láàrin àwọn tí wọ́n ti ń lo cArt tipẹ́ ní ilé-ìwòsàn tí ó wà ní agbègbè ìgbèríko.
Èyijẹ́ ìwádìí tí a ṣe ní ilé-ìwòsàn tí ó kó gbogbo ìpín ilé-ìwòsàn tí ó wà ní Agbègbè Bali pọ̀.
Ọgbọ́n-ìṣèwádìí tí ó nííṣe pẹ̀lú ìṣòdiwọ̀n-agbára oòrùn ni wọ́n láti ṣòdiwọ̀n aláròpọ̀ fún ìpele ìṣàyẹ̀wò-àìra-ẹ̀dọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ (ALT) àti ìṣàyẹ̀wò-àìlera-ẹ̀dọ̀ ọ́lọ́jọ́pípẹ́ (AST).
Ojú CIH ni wọ́n fi wo àwọn aláìsàn tí wọ́n ní ìgbésóké ALT àti AST.
Àyẹ̀wò Chi (χ2), ANOVA àti ìtúpalẹ̀ ti Kaplan Meier ni wọ́n fi tú data náà palẹ̀.
Èsì àwọn akópa 350 [[156 (44.6%) tí wọ́n jẹ́ akọ àti 194 (55.4%) tí wọ́n jẹ́ abo], ọjọ́-orí wà ní ẹni ọdún 43.87 ± 0.79 (ní gbèǹdéke ẹni ọdún 20 – 84) náà wà nínú ìtúpalẹ̀ yìí, 26 (4.4%) nínu wọn ni CIH wọn kò ga jù.
A ṣàkíyèsí ìpele ìgbéga 57 (16.3%), 62 (17.7%) àti 238 (68%) fún ALT + AST, ALT àti AST ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé.
Àwọn ohun àsọtẹ́lè CIH tí wọ́n wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ méjì náà ni, ti akọ àti ọtí mímu lásìkò ìwádìí.
Ìjẹyọ CIH lára àwọn tí wọ́n ní àrùn HIV ní Bali kéré sí ti àwọn tí wọ́n ṣàkíyèsí nínú àwọn ìwádìí tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn.
Àkókó tí ìtọ́jú fi ń lò kò kó ipa kankan lórí àlòtúnlò CIH.
Ọtí líle mímu àti fífa nǹkan fi ìyàtọ̀ tí ó hàn gedengbe hàn nínú ìgbéǹde CIH.
Ìwọn àìlera ẹ̀dọ̀ lára àwọn aláìsàn tí wọ́n ní HIV tí ó sì tara àlòpọ̀ ARVs (ìtọ́jú-àìlera adènàHIV) kò pọ̀ ni ilé-ìwòsàn ti agbègbè Bali, bí a bá fi wé ti àọn ìwádìí tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn.
Àmọ́ ṣá, ìṣakọṣabo, ọtí líle mímu àti fífa nǹkan ń kó ipa lórí ewu ṣíṣàkóbá àìlera fún ẹ̀dọ̀ fún àwọn aláìsàn àrùn HIV.
Apá gúúsù Sahara ilẹ̀ Áfíríkà ni ó ni ìdá tí ó ju ààbọ̀ lọ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn HIV lágbàáyé.
Ìkànpọ̀ àwọn oògùn àrùn HIV ni ìtọ̀jú tí wọ́n yàn, àmọ́ ìlò rẹ̀ a máa fa àìlera ẹ̀dọ̀ lára àwọn aláìsàn.
Ọpọ̀ ìwádìí kò dojú kọ àìlera ẹ̀dọ̀ tí àwọn ARV fà, àmọ́ a ṣì nílò dátà síi nípa èyí.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì náà fẹ́ tọpinpin iye ènìyàn tí tí ó ní àrùn HIV àti àìlera ẹ̀dọ̀ ní agbègbè náà.
Wọ́n tún fẹ́ wádìí ìwà ìlànà ìgbé-ayé wo ni ó ń ran ewu àìlera ẹ̀dọ̀ lọwọ lára àwọn aláìsàn yìí.
Àwọn aṣèwádìí náà tọpinpin àwọn aláìsàn ilé-ìwòsàn agbègbè Bali tí wọ́n ni àrùn HIV tí wọn kò sì ju ẹni ọdún 18 lọ.
Wọ́n gba ẹ̀jẹ̀ láara gbogbo àwọn aláìsàn fún àyẹ̀wò, wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò bóyá àwọn potéènì tí wọ́n níi ṣe pẹ̀lú àìlera ẹ̀dọ̀ wà níbẹ̀ àbí wọn kò sí.
Wọ́n wá ṣàmúlò módẹ́ẹ̀li ẹlẹ́rọ kọ̀m̀pútà láti se àsọtẹ́lè àwọn ìlànà ìgbé-ayé tí ó lè ṣòkùnfa àìlera ẹ̀dọ̀.
Àwọn aṣèwádìí fìdìí rẹ̀ múlẹ̀ pé iye potéènì tí ó ń ṣàfihàn àìlera ẹ̀dọ̀ pọ̀ lára àwọn aláìsàn tí wọ́n ní àrùn HIV.
Iṣẹ́ wọn tún ṣàfihàn rẹ̀ bí àwọn ìtọ́jú àrùn HIV kọ̀ọ̀kan ṣe rọ̀ mọ́ ìpèle gíga àwọn potéènì wọ̀nyí.
Módẹ́ẹ̀lì ẹlẹ́rọ kọ̀m̀pútà tún fi hàn pé àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń gba ARV wà nínú ewu àìlera ẹ̀dọ̀ tí ó ga, àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ń mu ọtí àti àwọn tí wọ́n ń fa nǹkan sínú.
Ohun tí ó ti di mímọ̀ tẹ́lẹ̀ ni pé ewu àwọn aláìsàn tí wọ́n ní àrùn HIV láti ni àìlera ẹ̀dọ̀ pọ̀ torí àwọn ìtọ́jú tí wọ́n ń gbà.
Àmọ́ ṣá, ìwádìí yìí wo gbèdéke tí àwọn aláìsàn àrùn HIV fi ń ní àìlera ẹ̀dọ̀ ní Ilé-ìwòsàn Agbègbè Bali.
Àwọn aṣèwádìí tún rí i pé mímu ọtí léle àti fífa ǹǹkan sínú ń fi àwọn aláìsàn àrùn HIV sínú ewu àìlera ẹ̀dọ̀ ńlá.
Àwọn aṣèwádìí pè fún ìṣóra pé dátà àwọn aláìsàn lè fa ìdíwọ́ fún ìwádìí yìí.
Wọn kò fi ti àwọn ohun mìíràn bíi kí wọ́n máa lo òògùn mìíràn tí kì í ṣe fún ìtọ́jú àrùn HIV ṣe.
Àti pé, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé iye òǹkà-olùgbé tí a lò fún iṣẹ́ ìwádìí yìí yàtọ̀ sí ti àwọn ìwádìí mìíràn nípa ọjọ́-orí àti ìṣakọṣabo, àwọn ìpinnu rẹ̀ kò bá ti àwọn ìwádìí mìíràn ní ilẹ̀ Áfíríkà mu.
Iṣẹ́ ìwádìí náà dojú kọ ilé-ìwòsàn kan ní Cameroon, wọn yóò sì fìdíi àbọ̀ ìwádìí múlẹ̀ nínú àwọn ìwádìí tí wọn yóò se lọ́jọ́-iwáju ní àwọn agbègbè mìíràn.
Àjàgà-ẹrù arun HIV pọ̀ lọ́rùn ilẹ̀ Áfíríkà.
Ìwádìí tí àwọn aṣèwádìí ilẹ̀ Cameroon ṣe yìí tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn data pàtàkì tí wọ́n ń ṣàfihàn àìlera ẹ̀dọ lára àwọn tí wọ́n ní àrùn HIV, àti pé àwọn ohun mìíràn náà tún ń se àlékún ewu àìlera ẹ̀dọ̀.
Bí a bá ní irú ìfitónilétí yìí, ó ṣe é ṣe kí ó ran ìṣàkóso àìlera ẹ̀dọ̀ nínú fún àwọn tí wọ́n ní àrùn HIV.
Northern Sotho (Sepedi) translation of DOI: 10.1101/2020.11.16.384339
Luganda translation of DOI: 10.1101/2020.11.16.384339
Hausa translation of DOI: 10.1101/2020.11.16.384339
This is Zulu translation of DOI: 10.1101/2020.11.16.384339
Amharic translation of DOI: 10.1101/2020.11.16.384339