Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1038/s41598-021-96330-7
Yoruba translation of DOI: 10.1038/s41598-021-96330-7
Àwọn oríṣiríṣi ẹ̀ya màlúù ilẹ̀ Sudan, Baggara, fún ẹran àti Butana àti Kenana fún mílíìkì, jẹ́ èyí tí a fi ìwà ìfaradà wọn ṣe àdámọ̀ wọn àti ìgbòòrò ìṣe wọn ní agbègbè-koríko tó gbọ́ná àti èyí tí ó gbẹ.
Wọ́n jẹ́ lílò fún ìwákiri àti ìwá-ráńpẹ́ ibi pápá oko tútù.
A yànnàná ìṣèyàtọ̀ àti àto gíìnì ti gíìni BoLA-DRB3, ibìṣẹ̀lẹ̀ gíìnì tí a lè sopọ̀ pẹ̀lú ìgbógun-ti-àìsàn, fún àwọn màlúù tó jẹ́ ti ilẹ̀ Sudan àti ní ìwòye àgbàálẹ̀ nípa màlúù ní àgbáyé.
Àpẹẹrẹ èjẹ̀ (n=225) jẹ́ gbígbà láti ara ẹ̀ya mẹ́ta (Baggara; n = 113, Butana; n = 60 and Kenana; n = 52) tí a pín káàkiri agbègbè mẹ́fà ní Sudan.
Núkílíótáìdì onípelé jẹ́ èyí tí ó ń lo ìlànà ìkọ onípele.
A ṣàlàyé álíìlì 53, pẹ̀lú àfikún álíìlì tuntun méje.
Principal component analysis (PCA) ti àpò èròǹjà aṣaralóore fihàn nínú ìṣe antigen-binding ti MHC complex fihàn pé àpò 4 àti 9 ṣèyàtọ ẹ̀ya Kenana-Baggara àti Kenana-Butana sí àwọn ẹ̀yà mìíràn.
Àlàyée Veen ti àwọn ẹ̀ya màlúu Sudan, Southeast Asia, àwọn Europe àti America pẹ̀lú álíìlì 115 fihàn pé 14 jẹ́ àkànṣe sí àwọn ẹ̀ya ilẹ̀ Sudan.
Iye ipò ìjẹyọ gíìnì ti màlúù Baggara fi ìdọ́gba ipò ìjẹyọ hàn léyìí tó fi ìdọ́gba hàn, nígbà tí ìmú ìjẹyọ fi ìjẹyọ onírúurú hàn nínú oríṣiríṣi ibùgbé amino acid lára BoLA-DRB3 exon 2 nínú àwọn ẹ̀yà yí.
Àbọ̀ ìwádìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ PCA wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìtòjọ onípele tí a rí lára igi NJ.
Àwọn àbọ̀ ìwádìí yìí fi ojú-inú hàn sí ipò-ìyè wọn sí oríṣiríṣi àìsàn àti okun ìbímọ wọn nínú àìrọgbọ ojú-ọjọ́ ilẹ̀ Sudan.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ti rí àwọn irúfẹ́ gíìnì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn màlúù ilẹ̀ Sudan tó gbajúmọ̀ tó jọ pé òhun ni kò jẹ́ kí wọ́n fi àyè gba àìsàn, àti pé àwárí náà lè jẹ́ èyí tí yóò túbọ̀ ṣe ìkúnwọ́ sí ètò ìlànà ìsinranko.
Àwọn ìyàtọ̀ nínú gíìnì, tí à ń pè ní álíìlì, jẹ́ èyí tó máa ń sábà jẹ ìṣokùnfà ìṣe bíi ìṣokun tí ó máa ń jẹyọ lára irúfẹ́ ẹranko kan tàbí àwọn ohun ọ̀gbìn.
Irúfẹ́ ẹ̀ya màlúù mẹ́ta tó yàtọ̀ síra, Baggara, Butana àti Kenana, jẹ́ àwọn tí a mọ̀ tí wọ́n ní ìpamọ́ra, wọ́n sì jẹ́ èyí tí àwọn adaran káàkiri ilẹ̀ Sudan máa ń sìn fún ẹran àti mílíìkì.
Ìwádìí lórí i ẹ̀ya màlúù ní àwọn ilẹ̀ mìíràn tí kì í ṣe Afirikà fi hàn pé ìyàtọ̀ álíìlì ti gíìnì kan tí à ń pè ní BoLA-DRB3, tí ó ń kópa nínú èròǹjà ìgbóguntàìsàn inú ara, lè mú kí àwọn ẹranko náà má fi àyè gba àìsàn àti àwọn kòkòrò ajẹnipa.
Ṣùgbọ́n di àsìkò yí, ohun bíńtí ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì mọ̀ nípa ìyàtọ̀ nínú ẹ̀yà inú àwọn màlúù ilẹ̀ Áfíríkà.
Nínú ìwádìí yìí, àwọn olùṣèwádìí ṣiṣẹ́ lé BoLA-DRB3 nínú màlúu ilẹ̀ Sudan, láti ri bóyá àwọn màlúù náà ní àkàǹṣe álíìlì tí ó lè ṣàlàyé àìfàyègba àìsàn wọn kí wọ́n sì pèsè ojú-inú sí àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí fún ìwádií ọjọ́ iwájú.
Àwọn olùṣèwádìí gba ẹ̀jẹ̀ látara ẹranko 225 káàkiri Sudan.
Wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò gíìnì fún àwọn ẹ̀jẹ̀ àgbàjọ náà, yíyẹ ìyàtọ̀ wò nínú gíìnì BoLA-DRB3 náà.
Wọ́n ṣe àfiwé ìwádìí wọ́n pẹ̀lú àwọn ìwádìí àtẹ̀yìnwá nípa gíìnì tó wà lára àwọn màlúù mìíràn.
Wọ́n tún wo bí oríṣiríṣi álíìlì ṣe ń jẹyọ sí nínú àgbàálẹ̀ wọn, láti ṣaáyan àwárí ìdí tí ìyàtọ̀ le fi máa wáyé.
Láborí ẹ̀, àwọn màlúù ilẹ̀ Sudan ní oríṣi ìjẹyọ gíìnì BoLA-DRB3 tí àwọn olùṣèwádìí ronú pé yóò ṣàfikún okun sí ìgbógun-ti-àìsàn wọn tí kò ní jẹ́ kí wọ́n fi àyè gba àìsàn.
Àwọn olùṣèwádìí náà rí álíìlì méje tí wọ́n jẹ́ tuntun tí ó sì jẹ́ àdáníi sí ẹ̀ya Sudan.
Wọ́n tún ṣàwárí pé, tí a bá ṣe àfiwé pẹ̀lú àwọn màlúù ilẹ̀ mìíràn láti àwọn ibò mìíràn lágbàáyé, àwọn àpẹẹrẹ àgbàálẹ̀ wọn jẹ́ álíìlì 14 ti gíìnì BoLA-DRB3 èyí tí kò sí nínú àwọn ẹranko tí kìí ṣe ti ilẹ̀ Áfíríkà.
Àwọn ìkànṣe ìrísí yìí lè ṣe ìrànwọ́ fún àwọn màlúu ilẹ̀ Sudan láti ye àpapọ̀ àìsàn àti àìmókun ara, bíi oru, ètí tí ó wọ́pọ̀ ní agbègbe wọn.
Ìwádìí náà pèse àwòjinlẹ̀ àkọ́kọ́ nípa ìṣèyàtọ gíìnì nínú gíìnì BoLA-DRB3 nínú àwọn màlúu ilẹ̀ Áfíríkà.
Álíìlì tuntun náà ṣi ilẹ̀kùn fún iṣẹ́ ìwádìí ọjọ́ọwájú sí àìfàyègba-àìsàn nínúu màlúù, àti bí ètò ìṣẹ̀ẹ̀yà ṣi lè di gbígbooro si.
Ohun pàtàkì mìíràn fún ìwádìí lọ́jọ́ iwájú ni ipa pàtó tí àwọn álíìlì tuntun yìí ń kó nínú ìgbógun-ti-àìsàn tó wà nínú àwọn màlúù wọ̀nyí.
Nígbà tí àwọn ìyàtọ́ mìíràn fikún àìfàyègbài ̀sàn, àwọn mìíràn mu kí ẹrànko náà wà ní àìmúrasílẹ̀ fún àwọn àìsàn mìíràn.
Àwọn ìwádìí ọjọ́ iwájú yóò nílò láti ṣe ìwádìí lórí ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín oríṣiríṣi àwọn álíìlì àti àìsàn inú màlúù.
Gẹ́gẹ́ bí àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní Áfíríkà, ìwádìí náà ṣe pàtàkì fún ìṣèwádìí gíìnì BoLA-DRB3 àti ìṣe àìṣàìsàn.
Àwọn onímọ̀ láti Sudan, Lebanon, Saudi Arabia, Japan àti Argentina ń ṣiṣẹ́ papọ̀ lóríi iṣẹ́ àkànṣe yìí.
Northern Sotho(Sepedi) translation of DOI: 10.1038/s41598-021-96330-7
Amharic translation of DOI: 10.1038/s41598-021-96330-7
Luganda translation of DOI: 10.1038/s41598-021-96330-7