Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Ìṣasọtẹ́lẹ̀ lórí àwọn irúgbìn ilẹ̀ Zimbabwe fi hàn pé ilẹ̀ tó dára le dín ìpalára àyípadà ojú-ọjọ́ kù.

Yoruba translation of DOI:10.1007/978-3-319-92798-5_5

Published onJun 01, 2023
Ìṣasọtẹ́lẹ̀ lórí àwọn irúgbìn ilẹ̀ Zimbabwe fi hàn pé ilẹ̀ tó dára le dín ìpalára àyípadà ojú-ọjọ́ kù.
·

 Ìlóye Kíkún nípa Ipa tí Ilẹ̀ àti Ìṣàkóso àwọn Irúgbìn kó Lásìkò Àìlèsọ-ìṣe Ojú-ọjọ́ ní Zimbabwe: Ìtupalẹ̀ Oníjàákúnra

 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe-é-ṣe kí àyípdà ojú-ọjọ́ nípa lórí àwọn ẹ̀ka ile-iṣẹ́ tó pọ̀ ní Zimbabwe, ewu rẹ̀ lórí iṣẹ́ àgbẹ̀ ló tayọ àwọn yòókù torí òun ni ó lé ètò ọrọ̀-ajé ìlú náà fẹ̀yìn tì.

Ní aàfikún, àlàyé peréte ló wà nípa ọ̀nà láti ran iṣẹ́ àgbẹ̀ kéréje-kéréje àti ìgbé-ayé lọ́wọ́ nípa dídojúkọ àwọn ewu yìí.

Láti wo ipa tí ó ní lórí ìpèsè ohun ọ̀gbìn ní ìrètí àwọn àyípàdà òjò-rírọ̀ àti àlékún afẹ́fẹ́ kábọ́ọ̀n (CO2) àti ìgbóná-gbooru, a ṣàmúlò àwòṣe ohun ọlọ́gbìn ajẹmọ́lànà-méjì- àwòṣe Etò Aṣèpinnu Aṣàtìlẹyìn fún Ìṣàmúlò-ẹ̀ro fún ìṣẹ́ àgbẹ̀ (DSSAT) àti àwọ̀ṣe (APSIM).

Wọ́n wo òdiwọn àwọn àwòṣe náà láti lè mú wọn ṣiṣẹ́, kí wọ́n lè ṣàyẹ̀wò ipa tí àwọn ohun ajẹmójú-ọjọ́ kan tàbi àpàpọl wọn kó lórí hóró àti ìso àwọn àgbọ̀n-ọ́nlẹ̀, láàrin oríṣìí ilẹ̀ mẹ́ta.

Àwọn àwòṣe méjèèjì ni wọ́n fẹnu kò lórí ipa tí onírúnrú ohun ajẹmójú-ọjọ́ ní lórí àgbàdo àti ẹ̀pà, àmọ́, ipa tí ó kó lórí wọn kò dọ́gba.

Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀dínkù nínú èso hóró àgbàdo pọ̀ nínú àwòṣe APSIM, àmọ́ àwòṣe DSSAT fi hàn pé ẹ̀dínkù wà nínú irè àgbọ̀n-ọ́nlẹ̀ hóró àgbàdo.

Àwọn àwòṣe méjèèjì fi àǹfààní irè hàn lábẹ́ CO2 tí wọ́n ṣe ìgbéga fún lórí ẹ̀pà, tí ó sì sénà mọ́ ipa ìgbóná-gbooru tí ó pọ̀ nígbà tí wọ́n ń ṣàyẹ̀wò àpapọ̀ ipa àwọn ohun ajẹmójú-ọjọ́.

Àmọ́ ṣá, lílékún irè wóró ẹ̀pà àti àwọn àgbọ̀-ọ́n-lẹ̀ ni wọ́n fojú hàn jùlọ nínú àwòṣe DSSSAT.

Àbájáde tí ó jẹ́ kókó ni pé àwọn ilẹ̀ ń kó ipa pàtàkì nínú ṣíṣe ìpinnu àbájáde àṣepọ̀ irúgbìn àti ojụ́-ọjọ́: wọ́n le dènà ibi tàbí kí wọ́n mú nǹkan burú sí i.


Ìṣasọtẹ́lẹ̀ lórí àwọn irúgbìn ilẹ̀ Zimbabwe fi hàn pé ilẹ̀ tó dára le dín ìpalára àyípadà ojú-ọjọ́ kù.

 Ìwádìí ti wo ipa tí àyípadà ojú-ọjọ́ ń kó lórí ètò ohun ọ̀gbìn ní Zimbabwe, ó sì ri pé àyípadà nínú ìgbóná-gbooru, òjò àti afẹ́fẹ́ kábọ́ọ̀n ń ṣe àkóbá fún ohun tó bá so.

Àmọ́ ṣá, dídojúkọ ìrólẹ̀lágbára le dín ìpalára àyípadà ojú-ọjọ kù láti dáàbò bo ìṣọwọ́so àwọn ohun ọ̀gbìn.

 Ó ṣe-é-ṣe kí àyípadà ojú-ọjọ́ ṣàkóbá fún ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn ilè Zimbabwe, tí ó jẹ́ olú ètò ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè náà, ṣùgbọ́n kò sí àlàyé tó gúnmọ́ tí ó lè ṣe ìrànwọ́ fún àwọn àgbẹ̀ kéréje-kéréje láti dójúsọ ewu náà.

Àyípadà ojú-ọjọ ní ipá láti yí ìṣọwọ́rọ̀ òjò àti iye afẹ́fẹ́ kábọ́ọ̀n tí ó wà padà, a sì ṣe bẹ́ẹ̀ la ipa lórí ìpèsè ohun ọ̀gbìn.

Àmọ́ wọn kò tí ì ṣe ìwádìí àwọn ipa àyípadà yìí ní Zimbabwe.

Ìwádìí yìí bojú wo àwọn ipa tí àwọn àyípadà tí a lè rí nínú rírọ̀ òjò, alekun afẹ́fẹ́ kábọ̀n (CO2), àti ìgbóná-gbooru, lórí ìpèse ohun ọ̀gbìn nípa ṣíṣe àmúlò àwoṣe ajẹmọ́ṣirò méjì.

 Àwọn aṣèwádìí náà lo àwọn àwòṣe méjèèjì láti ṣe ìpinnu lórí ipa tí ọ̀kanṣo àti àpapọ̀ àwọn ohun tí ó ń fa àyípadà ojú-ọjọ́ ń kó lórí ìpèsè ẹpà àti àgbàdo ní agbègbè Nkayi ní ilẹ̀ Zimbabwe.

Wọ́n lo àwòṣe náà láti wo àwọn ìyàtọ̀ sáà síra, ipa àwọn ìlànà tí ilẹ̀ ń là kọjá bíi àlòtúnlò omi àti afẹ́fẹ́ nátójìn, ní àfikún rẹ̀ pẹ̀lú ìwọn ìgbóná-gbooru tí ó kéré jù, tàbí tí ó ga jù tí ó lè nípa lórí àwọn ohun ọ̀gbìn lójúmọ́ kan.

Ìwádìí náà lo àwọn àwoṣe náà láti tọpinpin ipa àyípadà ojú-ọjọ́ lórí wóro àgbàdo àti ẹ̀pà, àti lára àwọn ẹ̀ka àti ewé tí ó máa ṣeku nígbà gbogbo sínú oko lásìkò ìkórè (tí a mọ̀ sí àgbọ̀-ọ́n-lẹ̀).

 Ìwádìí náà rí pé àwọn àwòṣe méjèèjì gba àwọn ipa tí àwọn ohun ajẹmójú-ọjọ́ ń kó lórí àgbàdo àti ẹ̀pà, àmọ́, òdiwọ̀n ipa náà yàtọ̀ síra.

Àwòṣe APSIM fi hàn pé síso wóró àgbàdo dínkù pẹ̀lú àyípadà ojú-ọjọ́, nígbà tí àwòṣe DSSAT fi hàn pé àyípadà ojú-ọjọ́ ṣe àdínkù àwọn àgbọ̀ọ́nlẹ̀ àgbàdò gidi gan-an.

Àwọn àwòṣe méjẹ̀èji fi hàn pé ọ̀gbìn ẹ̀pà lékun nígbà tí afẹ́fẹ́ kábọ́ọ̀n (CO2) pọ̀ si, àmọ́ àwòṣe DSSAT ran ọ̀gbìn ẹ̀pà àti àgbọ̀-ọ́nlẹ̀ lọ́wọ́ lásìkò ooru àti tí CO2 bá gbé sókè.

Àwọn aṣèwádìí yìí rí i pé ilẹ̀ ń kó ipa pàtàkì nínú àwọn ọ̀nà tí àyipadà nínú ì̀ṣọwọ́rọ̀ òjò àti ìgboná-gbooru lè gbà mọ́ àwọn ohun ọ̀gbìn lára.

 Àwọn èsì wọ̀nyí fi hàn pé ilẹ̀ tó dárá ni kókó nínú ìdènà ipa àyípadà ojú-ọjọ́ lóŕ ìṣètò àwọn ohun ọ̀gbìn.

Àwọn aṣèwádìí náà dábàá pé kí àwọn àgbẹ̀ àti ìjọba ní ilẹ̀ Áfíríkà gbájúmọ́ bí ilẹ̀ wọn yóò ṣe dára sí iláti dáàbò bo ara wọn lọ́dọ àwọn ipa àyípadà ojú-ọjọ́.


Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?