Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àwọn tí wọ́n faragbá ogun abẹ́lé Uganda tí wọ́n sì pàdánù ẹsẹ̀ wọn kò tí ì rí ìrànwọ́ di báyìí.

Yoruba translation of DOI:10.1101/2020.05.14.095836

Published onMay 24, 2023
Àwọn tí wọ́n faragbá ogun abẹ́lé Uganda tí wọ́n sì pàdánù ẹsẹ̀ wọn kò tí ì rí ìrànwọ́ di báyìí.
·

Ìwádìí Ajẹmọ́-ìwosààkun Dátà àwọn Olùgbé Tí a gbà láti mọ bí Ìpàdánù Ẹsẹ̀ ṣe Wọ́pọ̀ sí àti Ààtò rẹ̀ ní Apá kan Agbègbè Acholi ti Uganda

ÌPÀJÙBÀ

 Ìròyìn tó gbalé-gboko ni ti ìpàdánù ẹsẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ ní apá Àríwá Uganda, èyí tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé àjààjàtán ogun abẹ́lé ni ó fà á.

Akitiyan láti jẹ àǹfààní ìṣọdọtun kéré púpọ̀, kò sì tí ì sí ìwádìí kankan tí ó gbèrò láti lóye iye àwọn ènìyàn tí wọ́n pàdánù ẹsẹ̀ wọn, tàbí èyí tí ó wo àwọn tí wọ́n rí ìtọ́jú tàbí ìsọdọ̀tun nínú wọn.

ÈRÒŃGBÀ

Àkọ́kọ́ irú ìwádìí tí ó tọpinpin ìwọ́pọ̀ àìlera àti ìpàdánù ẹsẹ̀ ní agbègbè náà, tí ó sì ṣe àyẹ̀wò ààtò pípàdánù ẹsẹ̀ MLL.

ÌHUN

Ọgbọ́n ìṣewádìí aṣàpèjúwe.

IBÙDÓ ÌWÁDÌÍ

Àwùjọ kan ni ibùdó ìwádìí yìí (Ní inú ilé àwọn ẹni tí a yàn).

ÒǸKÀ OLÙGBÉ

Ojúlé 7,864 ni a yàn láìlétò kan pàtó jákè-jádò ihà kan agbègbè Acholi ní apá Àríwá Uganda.

ÀWỌN Ọ̀NÀ

 Atòjọ-ìbéèrè méjì ni ó wà nínú ìwádìí yìí, olórí ojúlé kọ̀ọ̀kan tí a ṣàyàn (yàn) ni yóò dáhùn àkọ́kọ́ (n=7,864), ẹnikẹ́ni nínú ojúlé náà tí ó bá ti pàdánù ẹsẹ (n=181) yóò sì dáhùn ìkejì.

A ṣàyẹ̀wò àwọn ibi tí ilé kọ̀ọ̀kan wà bóyá ìtànká wọn báramu nípa lílo ìṣirò I ti Moran.

A lo ìṣirò X^2 láti ya òte àwọn tí wọ́n pàdánù ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú àfiwé wọn àti iye àwọn olùgbé.

ESI

 A fi pẹ̀lẹ́ sòdiwọ̀n pé àwọn tí wọ́n ti pàdánù ẹsẹ̀ wọn tó c.10,117 ni agbègbè náà tí wọ́n nílò iṣẹ́ ìsọdọ̀tun ọlọ́jọ́-pípẹ́ (c.0.5% àwọn olùgbé), àti c.150,512 ènìyàn tí wọ́n ní àwọn àìlera tí ó yàtọ̀ sí ìpàdánú ẹsẹ̀ (c.8.2% àwọn olùgbé).

Àwọn ènìyàn tí wọ́n ti pàdánù ẹsẹ̀ fọ́nká gbogbo agbègbè náà (yàtọ̀ sí kí wọ́n kàn ṣujọ sí ojú kan) ọkùnrin sì ni ó pọ̀jù nínú wọn, wọ́n lọ́jọ́ lórí, wọn ò sì kàwé tó àwọn olùgbé lápapọ̀.

ÌKÁDÌÍ

 Fún ìgbà àkọ́kọ́, ìwádìí yìí fi àìkájú ìwọ̀n akitiyan ìsọdọ̀tun ọlọ́jọ́-pípẹ̀ fún àwọn tí wọ́n ti pàdánù ẹsẹ̀ ní agbègbè ìwádìí hàn.

A pèsè àwọn ìmọ̀ ọ̀tun nípa àwọn ìdí tí ọwọ́ àwọn ènìyàn kò fi tó ètò ìlera àti ètò ìsọdọ̀tun, a sì dábàá ọ̀nà àbáyọ fún ìtẹ̀síwájú nípa àṣedánwò àwòṣe ‘ìwòsàn ìkànsíní’ ní àṣeyọrí.

IPA ÌSỌDỌ̀TUN AJẸMỌ́WÒSÀN

Ṣíṣe àwárí ìtànkálẹ̀ àwọn tí wọ́n pàdánù ẹsẹ̀, pẹ̀lú ṣíṣe ìṣedánwò àwòṣe ṣíṣe ìkànsíni ajẹmọ́wòsàn, fi ààyè àwíjàre fún nínílò irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ àti àwọn ìlànà ajẹmétò ìmúlò tí wọ́n fara pẹ́ ẹ ní àwọn agbègbè tí wọn kò tí ì lájú àti ìgbèríko ní ihà Gúúsù Àgbáyé.


Àwọn tí wọ́n faragbá ogun abẹ́lé Uganda tí wọ́n sì pàdánù ẹsẹ̀ wọn kò tí ì rí ìrànwọ́ di báyìí.

 Fún ìgbà àkọ́kọ́, àwọn aṣèwádìí ṣe aṣamúlò èsì-ìbéèrè nípa àwọn tí wọ́n pàdánù ẹsẹ̀ wọn (MLL) àti àwọn àìlera mìíràn ní ihà agbègbè Acholi ni apá Àríwá Uganda.

Wọ́n ní ìrètí pé ìjọba àti àwọn àjọ mìíràn yóò ṣe àmúlò àwọn àlàyé wọ̀nyí láti pèsè ìwòsàn ní ibi tí àwọn ènìyàn ti nílò rẹ̀ jùlọ.

 Ihà kan nínú agbègbè Acholi ní apá Àríwá Uganda fi ara káásá ogun abẹ́lé fún ọdún 20 tí ó sì dópin ní ọdún 2005.

Ọ̀pọ̀ enìyàn ni wọ́n pàdánù ẹsẹ̀ wọn nínú ogun náà, inú ìṣẹ́ sì ni agbègbè náà wà.

Ó ṣeni láàánú pé títí di báyìí, ìjọba ìbílẹ̀ àti àwọn àjọ tí wọn kì í ṣe ti ìjọba ní ilẹ̀ òkèèrè kò mọ iye ènìyàn tí wọ́n ni àìlèra/ìpèníjà ẹ̀yà-ara tí ó dunra tí wọ́n ní àǹfààní sí ètò ìtọ́jú tàbí ètò ìsọdọ̀tun ní àdúgbò yìí.

 Èyí ni ìwádìí àkọ́kọ́ tí yóò wádìí bí ìpàdánù ẹsẹ̀ ṣe wọ́pọ̀ tó ní ihà kan agbègbè Acholi.

Ohun tí iṣẹ́ yìí múṣe ni láti ṣe àkọsílẹ̀ onírúnrú àìlera àti ìpàdánù ẹsẹ̀ tí ó wà láàrin àwọn olùgbé agbègbè yìí ní apá Àríwá Uganda, àti láti ya máàpù àwọn ọ̀gangan ibi tí wọ́n ti nílò ètò ilera jùlọ.

 Àwọn aṣèwádìí náà yan ojule 7864 láti fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ènìyàn lẹ́nu wò láìfi ètò kan ní pàtó yan ojúlé kankan, ibẹ̀ wọ́n ti ní kí olórí ilé kọ̀ọ̀kan àti àwọn ènìyàn 181 tí wọ́n ti pàdánù ẹsẹ̀ wọn dáhùn àtòjọ-ìbéèrè kan tàbí méjì.

Wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ ibi tí ojúlé kọ̀ọ̀kan wà wọ́n sì lo ètò ìṣirò I ti Moran láti lè ṣe ìpinnu ibi tí ìpàdánù ẹsẹ̀ ti wọ́pọ̀ jùlọ àti ibi tí wọ́n yóò ti nílò iṣé náà jù.

 Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn aṣewádìí kò lè bẹ gbogbo ojúlé tí ó wà ní agbègbè náà wò, wọ́n nílò láti ṣe àfojúsùn àwọn ojúlé tí wọn yóò ṣiṣẹ́ aṣojú fún àwọn aráàlú yòókù lọ́nà tó dára jù.

Wọ́n lo ètò ìṣirò tí wọ́n ń pè ní “Chi-squared (X^2) goodness of fit” láti ri dájú pé àwọn ojúlé tí wọ́n ní àwọn tí wọ́n ti pàdánù esẹ̀ wọn ni wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí aṣojú fún àwọn olùgbé yòókù.

 Àwọn aṣèwádìí náà ṣe ìṣírò pé ó tó 0.5% àwọn olùgbé tí wọ́n ti pàdánù ẹsẹ̀ wọn tí wọ́n sì nílò iṣẹ́ ìsọdọ̀tun ọlọ́jọ́-pípẹ́.

Wọ́n tún rí i pé nǹkan bí 8.2% àwọn èèyàn tí wọ́n ń gbé níbẹ̀ ni wọ́n tún ni àwọn àìlera mìíràn.

 Ìwádìí náà fi hàn pé fífọ́nká ni àwọn tí wọ́n pàdánù ẹsẹ̀ wọn fọ́n káàkiri agbègbè náà, kì í se pé wọ́n sùjọ sí àwọn ọ̀gangan kọ̀ọ̀kan.

Ọpọ̀ nínú àwọn tí wọ́n pàdánù ẹsẹ̀ (MLL) jẹ́ ọkùnrin, wọ́n lọ́jọ́ lórí, wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ kàwé púpọ̀ bí a bá ṣe àfiwé wọn pẹ̀lú àwọn olùgbé lápapọ̀.

Àwọn àbájáde yìí ni àkọ́kọ́ láti ṣe òdiwọn bí ìpàdánù ẹsẹ̀ ṣe wọ́pọ̀ sí ní apá kan agbègbè Acholi lọ́nà tó létò, pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé aáwọ̀ náà ti dópin ní ọdún 15 sẹ́yìn.

Ó ṣeni láànú pé dátà ètò-ìkànìyàn tí ó ti ju ọdún 5 lọ ni àwọn aṣèwádìí ní láti gbẹ́kẹ̀lé, wọn kò sì ní nọ́ḿbà fún àwọn olùgbé tí wọ́n jẹ́ asásàálà, tí wọ́n sì ń pọ̀si.

 Pẹ̀lú àwọn ìdíwọ́ yìí, ìwádìí ṣì fi hàn pé iṣẹ́ ìsọdọ̀tun ni ihà kan agbègbè Acholi ti kùnà láti ṣe ìrànwọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n ti pàdánù ẹsẹ̀ wọn.

Àwọn aṣèwádìí dábàá ìlànà àwòṣe ìkànsíni ajẹmọ́wòsàn fún ìpèsè ìwòsàn tí yóò fi ibi tí àwọn akitiyan ìsọdọltun yóò ti wúlò jùlọ tó ìjọba àti àwọn àjọ tí wọn kì í ṣe ti ìjọba kárí-ayé létí.

Wọ́n tún sọ pé ó ṣe-é-ṣe kí wọ́n nílò akitiyan ìsọdọ̀tun ní àwọn agbègbè ìgbèríko tí ogun ti ṣe lọ́ṣẹ́ ní apá Gúúsù Àgbáyé.



Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?