Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Kọ̀ ṣe e ṣe kí àwọn tí wọ́n ń gba ìtójú fún aàrùn HIV kí wọ́n ní àmì àìsàn tó le tàbí kú látàrí aàrùn COVID-19 ju àwọn tí kò ní aàrùn HIV

Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.06.04.20122606

Published onJun 24, 2023
Kọ̀ ṣe e ṣe kí àwọn tí wọ́n ń gba ìtójú fún aàrùn HIV kí wọ́n ní àmì àìsàn tó le tàbí kú látàrí aàrùn COVID-19 ju àwọn tí kò ní aàrùn HIV
·

Ìkóràn-oníbejì aàrùn COVID-19 àti HIV: 

ètò èrí máàpù ìwádìí tó ń lọ lọwọ

Gbogbo àgbáyé ni ó jìjàkadì pẹ̀lú àjàkáyé àrun apanirun.

Àwọn àjàkáyé aàrùn náà ni àìsàn ògidì èémí tó níṣẹ pẹ̀lú àpapọ̀ onírúurú àmì aàrùn kòró 2/ aàrùn kòró 2019 (SARS-CoV2/COVID-19) àti kòkòrò ajẹmọ́ HIV tí ó máa ń fa ìdínkù àjẹsára/ aàrùn ìṣọdọle àjẹsára (HIV/AIDS).

Àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìbásepọ̀ àwọn aàrùn àjàkayé yìí gbòòrò si.

Ṣíse ètò wíwá àwọn àkọsílẹ̀ tó níṣe pẹ̀lú ìkóràn-oníbejì COVID-19 àti HIV.

Lẹ́yìn oṣù márùn-ún tí àjàkáyé aàrùn COVID-19 ti bẹ̀rẹ̀, ó kéré tán ìwádìí ìjìnlè márùn-ún-dín-lógójì ni orílẹ̀-èdè mẹ́tàlá ti jábọ̀.

Èyí jẹ́ yálà ìjábọ̀ iṣẹ́ tí ènìyàn kọ̀ọ̀kan tàbí àjọṣepọ̀ iṣẹ́ lọ́kanòjọ̀kan.

Gẹ́gẹ́ bí i ìwádìí ìjìnlẹ̀ tí ó wà fún gbogbogbò, àwọn tó ní ìkóràn níbejì àwọn aàrùn yìí pẹ̀lú àwọn òǹkà kòkòrò HIV kò ní àpọ̀jù aàrùn àti ikú COVID-19.

Ó kere tán, aláìsàn HIV mẹ́rin ni wọ́n bọ̀sípò látàrí aàrùn COVID-19.

Ẹ̀rí tuntun dábàá pé kí wọ́n máa ṣe sí àwọn tó ní ìkóràn àwọn aàrùn méjéèjì yìí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe sí àwọn ènìyàn yòókù.

Ètò èrí máápù ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn aàrùn ìkóràn-oníbejì SARS-CoV-2 àti HIV fún àwọn aṣèwádìí, aṣòfin, aṣètójú àti àwọn mìíràn ní ààyè à ti ṣe àwárí ní kíakía àti láti wá òye tó jẹmọ ìwádìí yìí.


Kọ̀ ṣe e ṣe kí àwọn tí wọ́n ń gba ìtójú fún aàrùn HIV kí wọ́n ní àmì àìsàn tó le tàbí kú látàrí aàrùn COVID-19 ju àwọn tí kò ní aàrùn HIV

Ọ̀pọ̀ ìwádìí káríayé fihaǹ pé àwọn tí wọ́n ń gba ìtójú fún aàrùn HIV/ìsọdọ̀le àjesára kì í ní àmì àìsàn COVID-19 to le tàbí ní àbájade tó burú.

Àwọn aṣèwádìí tí wọ́n ṣẹ àgbéyẹ̀wó àwọn ìwádìí ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì tó wà lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí kókó-ọ̀rọ̀ yìí sọ pé ẹ̀rí fihàn pé àwọn aláìsàn HIV lè gbá ìtọ́jú àrun COVID-19 gẹ́gẹ́ bí i àwọn aláìsàn mìíràn náà ti lè gbà á.

Nítorí ètò àjesára àwọn alárùn HIV kò ní agbára tó, àwọn aṣèwádìí lẹ́rò pé wọ́n lè ní àìsàn tó burú jù tabi kú lasìkò àjàkáyé aàrùn COVID-19.

Nípa wíwo àwọn ìwádìí ìjìnlẹ̀ tí àwọn enìyàn tí ṣe lórí bí àwọn alárùn HIV/AIDS ṣe ń dáhùn sí ìkóràn àti ìtọ́jú COVID-19, àwọn aṣèwádìí ní ìrètí láti ran àwọn aṣèwádìí mìíràn, ìjọba àti àwọn oníṣègùn òyìnbó lọ́wọ́ bí wọ́n ṣelè ṣe ìtójú àwọn aláìsàn àti HIV àti ìsọdọ̀le àjesára tí wọ́n tún ní ìkóràn COVID-19.

Áwọn aṣèwádìí wo àwọn ìwé tó jáde láàárín oṣù Ṣẹẹrẹ àti oṣù Agẹmọ, ọdún 2020 tó kún fún àwọn kókó-ọ̀rọ̀ bí i "HIV', "AIDS", kòró" àti COVID-19.

Àwọn aṣèwádìí ń wá àbọ̀ nípa àwọn aláìsàn HIV, tàbí àwọn aláìsàn ìsọdọ̀le àjesára tí wọn lo oògùn adènà HIV tí wọ́n sì ní àìsàn COVID-19.

Nínú èsì ìwádìí wọn, àwọn aṣèwádìí rí ìwé 35 láti orílẹ̀-èdè 13, pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ ìkóràn-oníbejì COVID-19 àti HIV àkọ́kọ́ ní orìlẹ̀-èdè China.

Wọ́n rí i pé aàrùn HIV/AIDS kì í jẹ kí aàrùn COVID-19 kó burú sí I, àti wí pé àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ní aàrùn HIV máa ń bọ̀sípò lá tàrí COVID-19.

Àwọn aṣèwádìí náà ri pé àwọn aláìsàn yìí náà máa ń ni àmì àìsàn COVID-19 tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa ń ni bi i ikọ́, ibà, àìlèmí dáadáa, rírẹ̀, àìlègbóòórùn àti àìlètọ́wò, àti ìgbẹ́ gbuuru.

Aláìsàn kan ni ó ṣe dákú-dájí.

Ní àkótán, àwọn aláìsàn HIV/AIDS máa ń ní dáhùn sí COVID-19 gẹ́gẹ̀ bi àwọn aláìsàn mìíràn.

Wàyí, ewu COVID-19 máa ń pọ̀ nínú àwọn tó ní àìsàn bí i ìfúnpá, ìtọ̀-ṣúgà, sísanrà jù, aàrùn kíndìnrín.

Àwọn aṣèwádìí jabọ̀ pé oògùn HIV/iAIDS, darunavir, kì í pa dẹ́kun ìkóràn kòró.

Ìwádìí wọn tún fihàn pé láìsàn o ní ìkóràn-oníbejì tó ti ṣe ìfidípò kíndìnrín àti ẹ̀dọ̀ lẹ̀ bọ́sípò látàrí COVID-19.

Àwọn aṣèwádìí kìlọ̀ pé ó ṣe é ṣe kí àyọrísí ìwádìí wọn fì sí ibì kan ìdí ni pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi kọ àwọn ìwé tí wọ́n rí.

Wọ́n tẹ̀síwájú sí I nínú ìwádìí ìjìnlẹ̀ wọn láti jẹ́ kí a mọ bí COVID-19 ṣẹ ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn aàrùn mìíràn bi i ikọ́ ife, àti òtútù àyà, àti bí ìkóràn-oníbẹjì ṣẹ lè fa àìsàn ọpọlọ fún aláìsàn.

Àwọn aṣèwadìí orílẹ̀-èdè South Africa, ní bi ti aàrùn HIV/AIDS jẹ́ ìṣòro ìlera tó kọni lóminú jù.


Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?