Description
Lay summary of the research article published under the DOI: 10.1371/journal.pntd.0006629
This is a Yoruba translation of DOI: 10.1371/journal.pntd.0006629
Ìpè fún ìgbésẹ̀ ní kíákíá.
Àfojúsùn ìdàgbàsókè ọlọ́jọ́pípẹ́ láàárín orílẹ̀-èdè kan sí òmíran fún ìmúkúrò kòkòrò jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ tó jẹ́ ewu fún ìlera àwujọ ní ọdùn 2030 tọ́kasí ohun ìnílò tó kanni gbọ̀gbọ̀ láti wá ọ̀nà ìṣẹ́nà, àyèwò àrùn àti ìtọ́jú.
Àwọn atako ajẹmọ́ ìyípadà tí a yàn tàbí kóràn (RAMs) àti ìyípada pípẹ́ àbẹ́rẹ́-àjẹsára (VEMs) nínú kòkòrò jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ (HBV) lè dínkù àseyọrí àwọn ìtọ́jú tó wà tẹ́lẹ̀ àti àwọn ọ̀nà ìsẹ́nà.
Àwọn ìṣòro yìí wúlò fún ọ̀pọ̀ ètò ní ilẹ̀ Áfíríkà ní ibi tí òǹkà-àpòpjù-ìṣẹ̀lẹ̀-àìsàn HBV wà àti ìjàkálè àkóràn àrùn HIV àti àwọn àrùn mìíràn, ṣùgbọ́n àìní ànító dátà fún ìkápá-àrùn tó pọ̀ àti àìnító ẹ̀kọ́ ìwé, ìdámọ̀ àìsàn àti ìtójú ajẹmọ́wòsàn.
Ọ̀ǹkà-àpòjù-ìṣẹ̀lẹ̀-àìsàn, pínpín, àti ipa RAMs àti VEMs tí di àpatì ní àárín àwọn olùgbé ní lítíráṣọ̀ òde-òní.
A jáde láti gbà dátà fún ìhà agbègbè Sàhárà nípasẹ̀ ṣíṣe àyẹ̀wò lítíréṣọ̀ lẹ́sẹẹsẹ àti ṣíṣe ìtúpalè àwọn àtẹ̀jáde dátà kọ̀ọ̀kan, àti gbígbé àkójọpọ̀-dátà sí orí ayélujára
(https://livedataoxford.shinyapps.io/1510659619-3Xkoe2NKkKJ7Drg/).
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn dátà náà wá láti ọ̀wọ́ àwọn tí ìkọ́ràn HIV/HBV ń bá jà.
RAM tí ó wọ́pọ̀ jù ni rtM204I/V, bóyá ó dá wà tàbí ní àpapọ̀ pẹ̀lú ajẹmọ́ ìyípadà, àti ìṣàwárí nípa àwọn àgbàlagbà tí kò mọ̀ nípa ìtójú àti àwọn tó mọ̀ nípa ìtójú.
Bẹ́ẹ̀ náà larí àwọn onírúurú ìyípadà rtM204V/I + rtL180M+ rtV173L, tí wọ́n jẹmọ́ pípẹ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára, nínú 1/3 àwọn ọ̀wọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pẹ́ egbòogi-aṣèwòsàn fún àrùn HIV àti HBV ní odi ajẹmọ́ran tí ó ga fún ìsàtakò, ohun tí ó kanni lóminú nip é àwọn dátà tuntun dábàá àwọn ǹnkan mìíràn tí ó jẹmọ́ aṣàtakò, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ipa tí àwọn wọ̀nyí ń kó nínú ìwòsàn.
Ní àkótán, a nílò láti ṣe àtúṣe sí ìbojútó àyẹ̀wò-àìsàn, ìmúgbòòrò bá ìgbéléwọ̀n HBV ní láàbù ṣáájú àti lẹ́yìn ìtọ́jú àìlera, àti àlòlòtúnlò ẹgbòogi-aṣèwòsàn fún àrùn HIV àti HBV tẹnofófì dípò egbòogi-aṣèwòsàn fún àrùn HIV àti HBV lamifudíìn níkan.
Wọ́n nílò àwọn dátà tuntun láti sọ fún àwọn olùgbé àti ènìyàn kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀nà àti ṣe ìdámọ̀ àìsàn HBV, ìmọ́jútó àti ìtọ́jú àìlera ní ọ̀nà tí ó mú ìpalára dání gan-an.
Áfíríkà ní òǹkà-àpapọ̀-ìṣẹ̀lẹ̀-àìsan pípẹ́-òògùn- àjẹsára àti ìṣàtakò òògùn-kòkòrò-jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀, èyí sì lè ṣokùnfà ewu tó pọ̀ fún ilẹ̀ ti ó ni ọpọlọpọ̀ ìkóràn àrùn-ìsọdọ̀le-àjẹsára.
Àwọn aṣèwádìí sọ pé ó pọn dandan kí Áfíríkà náwó sí ṣíṣe ìdámọ̀ àìsàn àti ìdiwọ̀n ìtọ́jú.
Àjọ tí ó rí sí ìtọ́jú ìdàgbàsókè àfojúsù ti United Nations (SDG 3) pè fún ìdẹ́kun ìwọ́pọ̀ àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ gẹ́gẹ́ bí i ìsòro fún ẹ̀ka ètò ìlera gbogbò ní ọdúṅ 2030.
Èyí túmọ̀ sí ṣíse àtúnṣẹ sí ìdẹ́kun, ìdámọ̀ àìsàn àti ìtọ́jú ìwọ́pọ̀ àrùn jẹdọjẹdọ.
Wàyí, àwọn ìyípadà kòkòro jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B kán wà tí kò jẹ́ kí akitiyan à ti dẹ́kun àti láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀ yọ.
Àwọn ìsòro yìí súyọ ní ilẹ̀ Áfíríkà níbi tí òǹkà-àpapọ̀-ìṣẹ̀lẹ̀-àìsan ìkóràn oníbejì HBV àti HIV ti wọ́pọ̀ jùlọ.
Ìwọ̀nba dátà ni ó wà nípa òǹkà-àpapọ̀-ìṣẹ̀lẹ̀-àìsàn àti ipa ìyípadà tó tẹ̀lẹ́ HBV láti ṣètakò àwọn òògùn kọọkan tàbí láti pẹ́ ìjíṣiṣẹ́ àjẹsára tí abẹ́rẹ́ àjẹsára ń fún ara.
Nínú ìwádìí yìí, àwọn aṣèwádìí ṣe àtúwò àwọn ìwọnba dátà tó wà fún ihà kan ní agbégbè Sahara, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe àkójọpọ̀ dátà náà sí ọ̀nà kan ṣoṣo lórí ẹ̀rọ ayélujára.
Àkójọpọ̀ data yìí máa ń sàlàyé ìgbà lílò, òǹkà-àpapọ̀-ìṣẹ̀lẹ̀-àìsàn, àti ìṣẹ̀lẹ̀ ìyípadà oníbejì tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìyípadà òògùn aṣàtakò HBV (RAMs) àti ìyípadà pípẹ́ abẹ́ré-àjẹsára (VEMs) ní ilẹ̀ Áfíríkà.
Àwọn aṣèwádìí ṣàwárí àtẹ̀jáde lítíréṣọ̀ ní ìyàrá-ìkàwé tí wọ́n ní jọ́nà fún ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì ti MEDLINE, SCOPUS, àti EMBASE, láàárín oṣù òwàwà ọdún 2017 àti oṣù ṣẹẹrẹ ọdún 2018.
Wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ ọdún ìtẹ̀jáde ìwé, ọ̀nà ìgbà àti àyẹ̀wò dátà, ìwọ̀n ohun àyẹ̀wò, olùgbé tí wọ́n fẹ́ fi ṣe ìwádìí, ìtọ́jú agbógunti kòkòrò àti àwọn àlàyé pàtàkì mìíràn tí wọ́n rí nínu àtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan.
Wọ́n rí aṣàtakò tó níṣe pẹ̀lú ìyípadà tó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà orúkọ rẹ ni rtM204I/V, wọn rí èyí lára àwọn àgbàlagbà tí wọn kò tí ì gba ìtójú àti àwọn tó ti gbà.
Ìwádìí náà rí ìyípadà rtM204V/I, rtL180M, àti rtV173L tó níṣe pẹ̀lú pípẹ́ abẹ́rẹ́-àjẹsára, tí wọ́n ròyìn pé ó wà ní ọ̀wọ́ kẹta, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀wọ́ àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ìwádìí lé lórí nínú iṣẹ́ ìwádìí wọn.
Ìwòye tí ó kan àwọn aṣèwádìí lóminú ni pé òògùn Tenofovir ní àwọn ìtọ́kasí tí ó máa ń tètè jẹyọ tí ó sì máa ń ṣàtakò òògun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí òògùn yìí gẹ́gẹ́ bi aṣàtakò títí di òní.
Àbájáde ìwádìí náà nipé òǹkà-àpapọ̀-ìṣẹ̀lẹ̀-àìsàn àwọn ìyípadà yìí pọ̀ gan-an láàárín àwọn olúgbé kọ̀ọ̀kan ní ìhà kan ní agbègbè Sahara.
Àìnító àwọn ohun èlò ló ṣokùnfa àìní ìbojúwò ohun ìdámọ̀ àìsàn, àìsedéédé lórí ìpèsè òògùn, àti àìní àǹfàní àti ṣòfintótó ìṣèwòsàn, gbogbo àwọn wọ̀nyí ló kún ìtakò òògun àti abẹ́rẹ́ àjẹsára.
Èyí ni àgbéyẹ̀wò ṣíẹ̀ntẹ̀lé àkọ́kọ́ tí ó ṣe àyẹ̀wò RAMs àti VEMs fún HBV ní ilẹ̀ Áfíríkà.
Ìṣọwọ́ jẹyọ àkóràn HBV láàárín àwọn alárùn ìsọdọ̀le-àjẹsára pọ̀ gan-an ní àwọn agbègbè bí i Cameroon àti South Africa, èyí lè jẹ́ ọ̀nà láti mọ̀ pé wọ́n ti fi ìgbà kan jábọ̀ nípa àkóràn HBV lábẹ́lẹ̀, ó ṣée ṣe kí ó jẹ́ torí àìní ìlànà ìbojúwò, àìní ìmọ̀ tó dáńgájíá, àbùkù, ọ̀wọ́n gógó àti àìtó ohun amáyédẹrùn ti ajẹmọ́wòsàn àti láàbù.
Púpọ̀ nínú ẹ̀tò Áfíríka ni kò ní ìlànà ìbójútó fún àkóràn HBV, Fún ìdí ètí òtítọ́ tó wà nídìí òǹkà-àpapọ̀-ìṣẹ̀lẹ̀-àìsàn àti àbùdá àkóràn HBV kò tí ì di mímọ̀.
Ìwọnba àtẹ̀jáde ìwádìí àwọn aláìsàn ti HBV jẹ àìsàn ajẹmọ́ra ni àwọn aṣẹ̀wádìí rí.
Èyí tọ́kasí ìsòro àìbìkítà àrùn HBV ní ilẹ̀ Áfíríkà, àti àìkọjúsí àwọn dátà ajẹmọ́ran kọ̀ọ̀kan ní pàtó.
Pẹ̀lú àbájáde ìwádìí yìí, àwọn aṣẹ̀wádìí dábàá ìkówólé alálòpé láti mú ìmúgbòòrò bá pípèsè àwọn òògùn àti àjẹsára lóòrèkóòrè, àti láti pèsè ìbojúwò tí yóò ṣe ìdámọ̀ àìsàn ìkárùn àti ṣíṣe àwárí aṣàtakò.
Wọ́n nílò data sí i láti jẹ́ kí àwọn olùgbẹ́ àti èèyàn kọ̀ọ̀kan mọ ọ̀nà ìgbà ṣe àyẹ̀wò, ìmọ́jútó àti ìtọ́jú àìlera ní ọ̀nà tí ó mú ìpalára dání gan-an ní ìhà agbègbe Saharan.
This is Amharic translation DOI: https:10.1371/journal.pntd.0006629
This is Zulu translation of DOI: 10.1371/journal.pntd.0006629
This is Northern Sotho translation of DOI:10.1371/journal.pntd.0006629
This is Hausa translation of DOI: 10.1371/journal.pntd.0006629
This is Luganda translation of DOI: 10.1371/journal.pntd.0006629