Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àwọn aráàlú Uganda tó ní àrùn kọ̀kòrò HIV àti ẹ̀jẹ̀ ríru ò rí ìtọ́jú tí ó péye gbà

Yoruba translation of DOI: 10.1186/s43058-020-00033-5

Published onOct 02, 2023
Àwọn aráàlú Uganda tó ní àrùn kọ̀kòrò HIV àti ẹ̀jẹ̀ ríru ò rí ìtọ́jú tí ó péye gbà
·

Ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn ohun ìdènà àti olùdarí sí ìṣàkóso ìsopọ̀ ẹ̀jẹ̀ ríru HIV ní Uganda ní àwọn ilé-ìwòsàn HIV nípa lílo Ìsọ̀kan Fún Ìmúṣẹ Iṣẹ́ Ìwádìí (CFIR)

Ìpàjùbà

Àwọn èèyàn tó ń gbé pẹ̀lú HIV (PLHIV) tó sì ń gba ìtọ́jú àìlera antiretroviral ní ewu púpọ̀ tó jẹ mọ́ àrùn ọkàn àti ti ẹ̀jẹ̀ (CVD).

Asopọ̀ iṣẹ́ fún ẹ̀jẹ̀ ríru (HTN), èyí tó jẹ́ ewu CVD àkọ́kọ́, sínú àwọn ilé-ìwòsàn HIV tí wọ́n ṣe ìdúró fún ní orílé-èdè Uganda.

Iṣẹ́ wa ìṣáájú ṣe àfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlààfo tí a lè lò fi sẹ àmúlò ìsopọ̀ ìtọ́jú HTN pẹ̀lu ọgbọ́ń ìtọ́jú HIV lẹ́sẹẹsẹ.

Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, a wá láti ṣàwárí àwọn ohun ìdènà sí ti àwọn tó wà ní ìdí ìbojúwo ìṣàkóso ìsopọ̀ HTN àti ìtọ́jú sí àwọn ilé ìwòsàn HIV ní Ilà-Oòrùn ilẹ̀ Uganda.

Àwọn ọ̀nà àágbegbà

A ṣe iṣẹ́ ìwádìí tó lágbára ní ilé-ìwòsàn mẹ́ta pẹ̀lú kékeré, agbede méjì, àti iṣẹ́ ìtọ́jú HTN tó ga gan, èyí tí a fi pamọ́ kúrò ní àwùjọ tó sì dá lórí iṣẹ́ tí a ti ṣe sẹ́yìn.

Pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àjọ fún Ìṣọ̀kan Ìmúṣẹ Iṣẹ́ Ìwádìí (CFIR), a ṣèdá àwọn ìfọ̀rọlwánilẹ́nuwò tí wọ́n rọra ṣètò àti àwọn ẹgbẹ́ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn alákóso àwọn ètò ìlera, àwọn olùpèsè iṣẹ́ ìlera, àti àwọn PLHIV tó ní ẹ̀jẹ̀ ríru (n = 83).

Wọ́n ṣe ìdàkọ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà ní ọ̀rọ̀ fún ọ̀rọ̀.

Àwọn oníwádìí tó lágbára mẹ́ta lo ọ̀nà ìyọkúrò (èyí tí CFIR ṣe) láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn kóódù àti àkọ̀rí tó yẹ.

Wọ́n ṣe ìwọn rẹ̀ láti pinnu ìwọn ohun tó ń sọ iye átọ́ọ̀mù inú nǹkan àti agbára ìgbéléwọ̀n CFIR kọ̀ọ̀kan lórí ìsopọ̀ HTN/HIV.

Esi

Àwọn ohun ìdènà sí ìsopọ̀ HTN/HIV dìde láti ibi àwọn CFIR mẹ́fà:

àwọn ohun amóríyá àti èrè, àwọn ohun èlò tó wà nílẹ̀, ààyè láti rí ìmọ̀ àti àwọn àlàyé, ọgbọ́n àti ìgbàgbọ́ nípa ìdásí, ipá ara-ẹni, àti ṣiṣe ètò.

Àwọn ìdènà náà ní àìní ẹ̀rọ tó ń mójútó ẹ̀jẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa, àìlèpèsè àwọn òògùn tó ń gbógun ti ẹ̀jẹ̀ ríru, àfikún iṣẹ́ fún àwọn olùpèsè iṣẹ́ HTN, ìmọ̀ lórí àwọn PLHIV tí kò tó nípa ìtọ́jú HTN, ìmọ̀ tún kéré ọgbọ́n àti agbáraẹni tí àwọn tóń pèsè ìlera fi ń tọ́jú HTN, àti ètò ìsopọ̀ìtọ́jú HTN/HIV tí kò pé.

Àńfààní àti pèsè àwọn iṣẹ́ HTN àti HIV ní àwọn ilé-iṣẹ́ tí wọ́n lè dúró sí kan, ayédẹ̀rọ̀ (ìṣẹ̀dá tí kò ní ẹ̀ka) ti ìsopọ̀ ìtọ́jú HTN/HIV, tó lè faradà, tí ó sì wà ní ìbámu ìtọ́jú HIV àti ìtọ́jú HTN tó wà tẹ́lẹ̀ jẹ́ ìrànwọ́ fún ìsopọ̀ HTN/HIV.

Àwọnìtúmọ̀ CFIR yòókù ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìdí kan pàtàkì nípa ìsopọ̀ HTN/HIV.

Ìkádìí

Nípa lílo CFIR, a ti fin hàn pé àwọn ìdíwọ́ ìyípadà wà fún ìdàpọ HTN/HIV, ìdàpọ HTN/HIV jẹ́ ohun tó mums láyà àwọn aláìlera, àwọn òṣìṣẹ́ elétò àbò, àti àwọn adarí.

Ṣíṣe ìmúdára àti ráàyè sí ìtọ́jú HTN láàárín àwọn PLHIV yóò nílò kí wọ́ borí àwọn ìdènà àti fífi agbárasí àwọn olùrànlọ́wọ́ nípa siṣàmúlò ọ̀nà ẹ̀tọ́ ètò ìlera.

Àwọn àwárí wọ̀nyí jẹ́ orísun fún ìdásí tó péye fún HTN/HIV ní àwọn oríléèdè àti ọwọ́ ọ̀ya.


Àwọn aráàlú Uganda tó ní àrùn kọ̀kòrò HIV àti ẹ̀jẹ̀ ríru ò rí ìtọ́jú tí ó péye gbà

Iṣẹ́ ìwádìí fi hàn pé àwọn ilé ìwòsàn HIV ò ní ohun èlò àti àwọn òṣiṣẹ́ tí yóò tọ́jú àwọn aláìsàn tó tún ń bá àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru fínra.

Ẹ̀jẹ̀ ríru, tàbí haipatẹńsọ́ọ̀nù, máa ń mú 1 nínú 3 àwọn àgbàlagbàmẹta tó ní HIV ní ilẹ̀ Uganda.

Níwọ̀n ìgbà tí àwọn èèyàn tó ń bá àwọn ipò méjéèjì yìí fínra papọ̀ gbọ́dọ̀ máa ṣe ìbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn lóòrèkóòrè, àwọn oníwádìí sọ pé ó ní òye nínú fún àwọn ilé ìwòsàn HIV tó wà nílẹ̀ láti mọ̀ àti láti tọ́jú ẹ̀jẹ̀ ríru, kàkà kí wọ́n máa rán àwọn aláìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru lọ sí ibòmíràn.

Ó ṣeni láànú pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé-ìwòsàn HIV ò tí ì ṣe àseyọrí láti ṣe àsopọ̀ ìtọ́ju ẹ̀jẹ̀ rírú pẹ̀lú ìtọ́ju ́HIV tí wọ́n ti pèsè sílẹ̀.

Àwọn oníwádìí ṣe ìwádìí lórí ìdí tí ìsopọ̀ ìtọ́jú i ń ṣiṣé tàbí tí kò fi ṣiṣẹ́ ní ìlà-Oòrùn Uganda.

Níní òye nípa àwọn ìpèníjà yóò ṣe ìrànwọ́ láti lè pèsè ọ̀nà tó dára láti ṣe àsopọ̀ fún ìtọ́jú ẹ̀jẹ̀ ríru àti HIV.

Wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá àwọn elétò ìlera ní ilé ìwòsàn lẹnu wò ̀ti àọn alaáìsàn tó ń gbé pẹ̀lú HIV àti ẹ̀jẹ̀ ríru.

Wọ́n ṣe àtúpalẹ̀ àwọn ìdáhùn nípa ṣíṣàmúlò àwọn ọ̀nà ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì láti lè ṣe dáadáa lórí ètò ìlera.

Wọ́n rí i pé àwọn ilé-ìwòsàn HIV ò ní àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ní òye púpọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun èlò, pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ tó ń mójútó ẹ̀jẹ̀ àti àwọn òògùn.

Àwọn aláìsàn ò tún mọ̀ pé àwọn lè rí ìtọ́júgbà fún ààrùn méjéèjì ní àwọn ilé-ìwòsàn tí a dá sílẹ̀ fún ìtọ́jú HIV.

Àwọn oníwádìí mìíràn ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí bí ilẹ̀ Africa ti lè ṣẹ ìsopọ̀ ìtọ́jú ẹ̀jẹ̀ ríru àti HIV.

Síbẹ̀síbẹ̀, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀nà ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì tí a mẹnubà lókè, tí a mọ̀ sí Ìṣọ̀kan Fún Ìmúṣe iṣẹ́ Ìwádìí (CFIR), ni a lò láti wá ojútùú sí àwọn ìṣòro náà.

Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn oníwádìí ṣe ìkìlọ̀, pé nínú iṣẹ́ ìwádìí wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláị̀sàn ni ò mọ̀ nípa ìsopọ̀ ìtọ́jú HIV-ẹ̀jẹ̀ ríru, torí wọn ò mọ̀ nípa rẹ̀.

Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ ò lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n fi wá wọn lẹ́nu wò.

Nítorí náà wọ́n gbà wọ́n níyànjú pé kí iṣẹ́ ìwádìí ọjọ́ iwájú ó fi ojú àwọn aláìsàn wọ ó.

Wọ́n tún sọ pé wọ́n nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìwádìí láti fi wo ìjọra iye àti àǹfààní ìsopọ̀ ìtọ́jú ẹ̀jẹ̀ ríru àti HIV.

Orílé-èdè Uganda àti àwọn aláṣe ètò ìlera ilẹ̀ Africa yòókù lè lo òye inú iṣẹ́ ìwádìí yìí láti ṣe ìsopọ̀ ìtọ́jú fún ẹ̀jẹ̀ ríru àti HIV.

Pẹ̀lú irú àwọn ìdásí bẹ́ẹ̀, a lè mú àwọn ikú tí a lè yẹra fún torí ẹ̀jẹ̀ ríru, níwọ̀n ìgbà tí wọn yóò tètè rí i àti tọ́jú ẹ̀ nígbà tí àwọn aláìsàn bá lọ gba ìtọ́jú HIV.


Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?