Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1101/2020.06.12.148593
Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.06.12.148593
E. coli aṣokùfa ìgbẹ́ gbuuru (EPEC) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àìsàn tí ó máa ń fa ìgbẹ́ gbuuru fún ọmọdé káàkiri àgbáyé.
Èkúté C57BL/6 tí a fún ní abẹ́ré oògùn adènà àrùn ní ìdojúkọ irúfẹ́ EPEC tàbí escN (tí ò ní ẹ̀yà 3 ìgbàjáde èérí ara) láti mọ ìjẹgàba, ìwú àwọn èsì àti àwọn àbájáde ìwòsàn nígbà àkóràn.
Ìjàgbara tí ògun apakòkòrò inú ará máa ń ṣe sí àwọn kòkòrò àìfojúrí inú ìfun máa ń ṣokùnfa ìjẹgàba tó péye fún EPEC tí yóò mú àìdàgbà ài ìgbẹ́ gbuuru wá.
Ara wíwú, kẹ́mókáínì, àfikún iṣẹ́ sẹ́ẹ̀lì, àti sátókáínì amárawú jẹ́ yíyẹ̀wò nínú ìfun.
Wọ́n ṣe àkíyèsí mólíkù kékèké nínú àwọn eku tí EPEC ń ṣe pẹ̀lú ìyàtọ̀ TCA, ìdọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀, àti ìsún nínú ipele gọ́ọ̀tì maikuro mẹtaboláítì.
Ní àfikún, lẹ́yìn ijọ́ 7 tí a fúnni ní abẹ́rẹ́, ìsanra yóò pada bọ̀ sípò, àwọn eku tí ó kó EPEC máa ń ní ìkọjá àìlẹ́tọ̀ọ́ àti kíláúdíínì onípele-1.
escN náà yóò ṣàkóso lórih eku náà, ṣùgbọ́n ìsanra rẹ̀ kò ní jò tàbí kó wú, léyìí tó ń ṣàfihàn T3SS nínú EPEC nínú módẹ́lì yìí.
Ní àkótán, módẹ́lì ẹ̀yà eku tí a ṣe pẹ̀lú oògùn apakòkòrò inú ara ti wà láti ní èsì oríṣiríṣi tí a rí lára àwọn ọmọdé tọ́ ní EPEC àti láti ṣe àyẹ̀wò ipa tí wọ́n kó nínú àsàyàn àwọn tíréètì.
Módẹ́ẹ̀lì yí lè ṣe ìrànwọ́ láti ní òye nípa ìdàgbàsókè EPEC àti àwọn àbájáde láti lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ète àti lè dẹ́kun rẹ̀.
Nínú àwọn ọmọwọ́ àti àwọn ọmọdé, E. coli (àìsàn inú ìfun) máa ń fa àìsàn bí i ìgbe gbuuru, ibà, èébì, àìtó omi ara, tàbí ikú.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ti rí ọ̀nà láti ṣèdá àwọn àmì àìsàn irúfẹ́ E. coli tí a mọ̀ sí EPEC (E. coli aṣokùnfa ìgbẹ́ gbuuru) nínú àwọn èkúté tó ti kó àìsàn náà, láti lè ṣèwádìí lórí àìsàn náà ṣe máa ń dàgbà.
Nígbà kan rí, àwọn oníṣẹ́ sáyẹ́ńsì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí E. coli ti lo àwọn ẹranko tí wọ́n ní àìsàn náà bí i ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté, láti lè ní òye kíkún nípa àìsàn náà.
Tí àwọn àmì àìsàn tí a rí nínú ènìyàn bá jẹ́ èyí tí a lẹ̀ ṣẹ̀dá sára ẹranko, èyí yóò jẹ́ ọ̀nà àti lè ṣẹ̀dá àjẹsára fún ìtọ́jú àìsàn náà.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ń rí ìdojúkọ láti ṣẹ̀dá gbogbo àmì àìsàn àìsàn náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe jẹyọ nínú eèyàn.
Nínú ìwádìí yìí, àwọn olùṣèwádìí fẹ́ ṣẹ̀dá àwọn àmì àìsàn E. coli tí à ń rí nínú àwọn ọmọdé tí wọ́n ń jìjàkadì pẹ̀lú EPEC nínú èkúté.
Àwọn àmì àìsàn kọ̀ọ̀kan tó ṣe pàtàkì ni ìgbẹ́ gbuuru, ìlọ́ra ìdàgbàsókè, ara wíwú, àti ìjàm̀bá ìfun.
Wọ́n tún fẹ́ ṣe àyèwò bí ìjẹyọ ìyàtọ gíìnì sí bakiterià ṣe ń kó ipa ĺrí àwọn àmì àìsàn nínú eku.
Tẹ́lẹ̀, àwọn olùṣelwádìí máa ń ṣàyẹ̀wò èkúté náà pẹ̀lú àwọn ògùn apakòkòrò inú ara láti pa àwọn bakitéríà kọ̀kọ̀kan, láti fi àyè sílẹ̀ fún àìsàn inú ìfun láti dàgbà dáadáa.
Wọ́n yóò sì fi EPEC náà sára èkúté, tàbí pẹ̀lú u EPEC èyí tí a ti yídà nípa gíìnì láti lè dín agbára àti bá sẹ́ẹ̀lì ìfun jà.
Wọ́n ṣe àfiwé àwọn èkúté wọ̀nyí pẹ̀lú ọ̀wọ́ àwọn èkúté mìíràn tí ara wọ́n mókun.
Pẹ̀lú ìwà ní ọ̀wọ́ àwọn eku náà, àwọn olùṣèwádìí náà mójútó ìdàgbà àti àmì àìsàn sí àìsàn inú ìfun.
Àwọn eku tí a ti kó EPEC ràn kò yára dàgbà bí i àwọn tí ò ní àìsàn náà, wọ́n sì í yàgbẹ́ gbuuru gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọwọ́ yóò ṣe máa ṣe.
Àwọn olùṣèwádìí náà tún rí kẹ́míkà kan náà tí ó jẹ́ okùnfà àìsàn inú ìfun nínú àwọn èkúté tí ó jẹ́ pé wọ́n rí nínú àwọn ọmọdé.
Ìfun inú àwọn èkúté náà ti ní ìkọlù látara àìsàn náà léyio tó mú kí wọ́n má lè ní okun tó péye – èrí tí àwọn olùṣèwádìí gbàgbọ́ pé ó fa ìdí tí wọ́n fi í jò nígbà tí wọ́n ní E. coli náà.
Wàyí o, àwọn èkúté tí EPEC èyí tí a ti yídà nípa gíìnì jò díẹ̀, wọ́n ṣe àfihàn àmì àìsàn ráńpẹ́, ìfun wọn ol dì bàjẹ́, ṣùgbọ́n àìsàn náà wà lára wọn.
Nínú àwọn ìwádìí àtijọ́, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ní ìdojúkọ láti rí àwọn àmì àìsàn kọ̀ọ̀kan nínú àwọn èkúté wọ̀nyí, bíi ìgbẹ́ gbuuru.
Nípa àtiṣẹ̀dá àwọn EPEC yí, nínú ìfun, jẹ́ ohun pàtàkì.
Módẹ́lì eku yìí yóò ran àwọn olùṣèwádìí lọ́wọ́ láti ní ọ̀ye nípa bí àmì àìsàn ṣe máà ń jẹyọ ní EPEC, léyìí tí yóò ran àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì lọ́wọ́ láti wá àwọn ọ̀nà tó péye láti wò àti láti tọ́jú àwọn àmì àìsàn wọ̀nyí.
Lọ́jọ́ọ̀la, èyí lè yọrí sí ṣíṣe ìtọ́jú tó dára tàbí àjẹsára tó lè se àgbè fún ilera àwọm ọmọdé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣe ń ní ìdàgbàsókè tó jọjú.
Ìwádìí náà jẹ́ àjọṣe àwọn olùṣèwádìí láti South Africa, B razil, UK àti USA.
Amharic translation of DOI: 10.1101/2020.06.12.148593
Hausa translation of DOI: 10.1101/2020.06.12.148593
Luganda translation of DOI: 10.1101/2020.06.12.148593
Northern Sotho(Sepedi) translation of DOI: 10.1101/2020.06.12.148593
Zulu Translation of DOI: 10.1101/2020.06.12.148593