Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn nípa ẹranko nígbà àjàkálẹ̀ aàrun Covid-19

Yoruba translation of DOI: 10.20944/preprints202006.0130.v2

Published onOct 02, 2023
Ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn nípa ẹranko nígbà àjàkálẹ̀ aàrun Covid-19
·

Ipa ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ aàrun COVID-19 lórí i Ìṣe nínú ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ àwọn Ọmọ Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìṣègùn nípa Ẹranko

Abstract

Ọ̀pọ̀ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ fásitì àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ni wọ́n dáwọ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ dúró nítorí ìtàkálẹ̀ àjàkálẹ̀ aàrun kòrónà léyìí tí wọ́n yí ibi ìgbẹ̀kọ́ sí orí ẹ̀rọ ayélujára.

Ìwádìí òwọ́ lólọ́kan-ò-jọ̀kan jẹ́ èyí tí a ṣe láti wo ipa ìsémọ́lé nítorí i aàrun kòrónà 2019 (COVID-19) lórí I ìṣe nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ awọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn nípa ẹranko àti àwọn olùṣèwádìí.

Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn nípa ẹranko àti awọn olùṣèwádìí di pípè láti wá kópa nínú àtẹ̀jíṣẹ́ ìwá ìbéèrè pélébé e ti google.

Àpapọ̀ ẹni 1398 láti orílẹ̀-ède 92 ni ó kópa nínú àtẹ̀jíṣẹ́ ìbéèrè náà tí ìwọn èsì si tó 94.52%.

Dátà náà fi hàn pé ìsénimólé ti àjàkálẹ̀ aàrun COVID-19 nípa lórí ìṣe nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùkópa (96.7%) tí wọ́n ní ìwé èrí oríṣiríṣi.

Èsì ìgbéléwọ̀n onídajì fuń ẹ̀kọ́ orí ẹ̀rọ ayélujára lápapọ̀ jẹ́ 5.06 ± 2.43 léyìí tí oní ìwòṣe jẹ́ 3.62 ± 2.56.

Ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára máa ń pèsè aǹfààní fún ìkọ́ra-ẹni.

Ìdojúkọ pàtàkì tí ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára ń fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègun nípa ẹranko ni bí wọ́n ṣe lè gba àwọn ẹ̀kọ́ aláwòṣe.

Nígbà tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ náà jẹ́ aláwòṣe; nítorí náà, kò rọrùn láti kọ́ ní orí ẹrọ ayélujára.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rò ó pé ó nira láti ní imọ tó péye lórí ìṣègùn nípa ẹrànko pẹ̀lú ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára nìkan.

Ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára lè gbé pẹ́lí bí a bá jẹ́ kí ìkópa pọ̀, fífi ìlànà ìṣègùn hàn nílànà ìṣẹ̀lẹ̀ ojú-ayé, fífúnni ní àwọn ìròyìn pató, àti pípesè irinṣẹ́ oní 3D láti ṣe ìsínjẹ ìṣẹ̀lẹ̀ ojú-ayé.


Ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn nípa ẹranko nígbà àjàkálẹ̀ aàrun Covid-19

Ẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára nígba àjàkálẹ̀ aàrun Covid-19 nira fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègun nípa ẹranko àti àwọn olùṣèwádìí, nítorí iṣẹ́ aláwòṣe ni wọ́n ń ṣe tó pè fún ìkọ́ṣe ojú-ẹsẹ̀.

Ìwádìí náà rí díẹ̀ lára àwọn ìdojúkọ wọn lórí ayélujára, bẹ́ẹ̀ náà ni ó pesè àwọn ọ̀nà abáyọ.

Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ fásitì káàkiri àgbáyé yí sí ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára láti dènà ìtànkálẹ̀ Covid-19 nígbà àjàkálẹ̀ aàrùn náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, pàápàá àwọn tí kò ní àyè sí alátagbà tó dára, rí ipa tí kò suwọn gidigidi.

Iṣẹ́ ìwádìí náà fẹ́ pinu, nípa lílo ìwé ìbéèrè pélébé, bí ẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára ṣe ń ní ipa tí ò dára lórí ìṣe nínú ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègun nípa ẹranko káàkiri àgbáyé.

Awọn oluṣèwádìí náà tún fẹ́ pinu àwọn ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìpèníjà ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára yí.

Wọ́n ṣe ìwé ìbéèrè pélébé aláìládàámọ̀, pẹ̀lú àwọn ìbéèrè tí ó níṣe pẹ̀lú irúfẹ́ ẹni tí àwọn olùkópa jẹ́, àti ipa tí ẹ̀kọ́ orí ẹ̀rọ ayélujára ń kó lórí I ìṣe ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn.

Àwọn olùṣèwadìí béèrè nípa àwọn ohun èlò ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń lò, iye wákàtí tí wọ́n ń lò lórí ìgbẹ̀kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára lójojúmọ́, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára ṣe nípa lórí àwọn iṣẹ́ àwòṣe àti toní tíọ́rì, àti àwọn ìdojúkọ tí wọ́n máa ń ní bígbà tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Àwọn olùkópa náà fi èrò wọn gẹ́gẹ́ bí I ọ̀nà àbáyọ sílẹ̀.

Bí i ìdajì nínú àwọn olùkópa 1398, láti orílẹ̀-èdè 92, ni wọ́n sọ pé àjàkálẹ̀ aàrùn náà kó ìfàṣẹ́yìn bá ètò ẹ̀kọ́ àwọn.

Àwọn olùṣèwadìí náà ri pé àwọn ohun àǹfààní kọ̀ọ̀kán wà nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn nípa ẹranko, ṣụ̀gbọ́n àwọn àlébù nípa àìníàǹfààní sí ẹ̀rọ ayárabihàṣá pọ̀, àìsí ohun èlò, àti ipò ìwòṣe àwọn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan.

Ìwádìí náà dábàá pé àwọn akẹ́kọọ́ nílo àwọn irinṣẹ́ sí i, àti ìfèròwérò láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ fún àwọn iṣẹ́ ìwòṣe wọn.

Àwọn ìwádìí mìíràn ti so bí àjàkálẹ̀ aàrùn náà ti d ètò ẹ̀kọ́ rú fún àwọn akẹ́kọọ́ ìmọ ìṣègùn, àti bí aàrùn náà ṣe ṣe àkóbá fún àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìmọ̀ ìṣègùn nípa ẹranko.

Àwọn ọ̀nà àbáyọ tí a là kalẹ̀ níbí gùn lé àwọn iṣẹ́ ìwádìi náà nípa dídábàá bí ìkẹ́kọ̀ọ́ orí ẹ̀rọ ayélujára ṣe lè tẹ̀wọ̀n tó lọ́jọ́ iwájú, pàápàá fún àwọn iṣẹ́ ìwòṣe nínú gbogbo irúfẹ́ iṣẹ́.

Àwọn olùṣèwadìí náà wòye pé iṣẹ́ àwọn kò níla tó, léyìí tó mú kí àwọn orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kán má ní ìṣojú tó yè kooro.

Olùṣèwádìí yìí ń gbé ní orílẹ̀-ède Egypt.


Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?