Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Ǹjẹ́ ìdàpọ ìlo ajílẹ̀ àti èédú lè ṣe ìfikún sí awọn àmúyẹ ilẹ̀ pápá?

Yoruba translation of DOI: 10.1016/j.heliyon.2021.e07089

Published onApr 04, 2023
Ǹjẹ́ ìdàpọ ìlo ajílẹ̀ àti èédú lè ṣe ìfikún sí awọn àmúyẹ ilẹ̀ pápá?
·

Ìdínkù èròǹjà ìmúgbóòrò ilẹ̀ jẹ́ ìdíwọ́ sí ìdáko ní àwọn agbègbe gúsù ilẹ̀ Áfíríkà.

Àwọn ohun àmúyangan fífi èédú àti ajílẹ̀ sí ìmúgbóòrò ilẹ̀ ti di kíkosílẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwádìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣèwádìí.

Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, ìṣèwádìí ọjọ́ 30 wáyé nínú láàbù nípa lílo àpẹẹrẹ Haplic Acrisol 120 g pẹ̀lú ṣùkùrù àgbàdo (cbio), èpo ìrẹsì (rbio), èpo àgbọn (coco300 and coco700) tàbí àwọn ohun ajílẹ̀ ní iyẹ 1% w/w alátúnṣe: ilẹ̀, lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Àwọn ohun mìíràn nínú ìwádìí náà ni àpapọ̀ ajílẹ̀ àti ṣùkùrù àgbàdo tàbí èpo ìrẹsì (1 % compost + 1% èédú: 1% soil w/w), lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan, láti lè wo ìṣe wọn lórí ìmí ilẹ̀ básálì, ilẹ̀ pH; kábọ́ọ̀nù ilẹ̀; ìpàrọ̀ kábọ́ọ̀nù; àpapọ̀ kábọ́ọ̀nù tó jíire, àpapọ̀ náítírójínì àti ìgbápọ̀ nahítírójínì.

Èédú àti ajílẹ̀ ta papọ̀ tàbí ta lò lọ́tọ́ọ̀tọ̀, àti èédú ń ṣe ìkúnwọ́ sí ilẹ̀ pẹ̀lú 0.28 sí 2.29 pH ní àfiwé pẹ̀lú ìdarí ti a ò túnṣe.

Ìmí básálì láti ìdí ajílẹ̀ tàbí èpo ìrẹsì, tàbí ṣùkùrù àgbàdo tàbí àpapọ̀ ajílẹ̀ pọ̀ ju èyí tí ìdarí ti a ò túnṣe ko sí fún, léyìí tó jọ èyí tí ajílẹ̀ nìkán wà fún lọ.

TOC ni ajílẹ̀ gbòógì àti àpapọ̀ ṣùkùrù àgbàdo àti àtúnṣe ajílẹ̀ tó ìwọn 37% àti 117% Ju ètí tí à ń darí lọ.

Àpapọ̀ èpo ìresì àti ijílẹ̀ ṣe àfikún MBC pẹ̀lú iwọn 132% nígba tí ìlo ajilẹ̀ nìkan ṣe àfikún pẹ̀lú 247% lólọ́kan-ò-jọ̀kan, ni àfiwé pẹ̀lú ìdarí.

Ní àkótán, ìwádìí náà ṣe àfihàn ìdálò ajílẹ̀ àbí àpapọ̀ ajílẹ̀ àti èédú, àbí kí ajílẹ̀ fikún àmúyẹ ilẹ̀ bíi ph àbí MBC, àti láti ṣe ìgbooro fún ìdúróṣinṣin ilẹ̀ C látara TOC àti ìdínkù C nínú ilẹ̀ látara ìmí básálì.


Èédú àti ajílẹ̀ ṣe ìfikún fún ìdára ilẹ̀ fún èso

Ìwádìí yìí ṣiṣẹ́ lóríi bí èédú, tí a ṣẹ̀dá látara báómaàsì, lè di lílò fún ìfikún ìdára ilẹ̀ ní àwọn agbègbe gúsù ilẹ̀ Áfíríkà.

Ìwádìí náà fihàn pé èédú máa ń fi kún ìdára ilẹ̀ bíi àwọn ọ̀nà mìíràn tí ó wọ́n tí ò sì rọrùn láti rí.

Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tó ń kojú ìlànà ọ̀gbìn ní agbègbe gúsù ilẹ̀ Áfíríkà ni àdínkù ìmúgbòrò inú ilẹ̀.

Ìmúdára ilẹ̀ yóò jẹ́ kí èsó so síi, léyì tí yóò mú kí ìṣẹ́ dínkù ní àwọn ìlú ìgbèríko àti láti dín ìtàbùku bá ohunnàlùmọ́nì inú ilẹ̀ kù.

Ìwádìí ti fi hàn pé èédú, tí a ṣẹ̀dá látara báómaàsì lè di lílò fún ìfikún ìmúgbòrò ilẹ̀.

Èédú jẹ àbo àbájádeìgbóná, tàbí báómaàsì, ní àyíkáa afẹ́fẹ́ bíńtín tàbí àìsáfẹ́fẹ́.

Èédú ti jẹ́ mímọ̀ láti ṣe ojú ilẹ̀ dáadáa, fífikún omi àti atẹ́gùn tó wà láyìíká, àti láti mú kí àwọn kòkòrò aláìfojúrí inú ilẹ̀ jí pépé.

Ìwádìí náà ṣàyẹ̀wò sí ìṣe èédú àti ajílẹ̀ lóri àmúyẹ nípa lílo àwọn ohun bí i ìmí ilẹ̀, pH ilẹ̀, ìwa kòkòrò àìfojúrí, iye kábọ́ọ̀nù tó wà, àti iye náítírójínì tó wà.

Àwọn olùṣèwádìí náà ṣẹ̀dá ṣùkùrù àgbàdo, àgbọn àti èpo ara ìresì èédú nípa lílo ìgékuru látara ìgbóná, tó níṣe pẹ̀lú imúgbónà láìsí ìwa afẹ́fẹ́, ní 450 C ní àrò tí a ṣe nílànà ìbílẹ̀.

Àwọn olùṣèwádìí náà ṣẹ̀dá èpo àgbọn nípa lílo ìgékuru látara ìgbóná ní 300C àti ní 700C.

Àwọn olùṣèwadìí náà sì ṣe ìgbé-sí-ìgò àwon àpẹẹrẹ iyẹ̀pẹ̀ tí a ti dàpọ̀ p̀ẹlú èédú fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́.

Àpẹẹrẹ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan ló ní àkànṣe iyẹ̀pẹ̀ tí à ń pè ní Haplic Acrisol, èyí tí a pò pọ̀ mọ́ oríṣiríṣi èédú táa ṣe látara ṣùkùrù àgbàdo, èpo ìrẹsì tàbí èpo àgbọn, àti ìgbẹ́ àwọn adìyẹ.

Àwọn àgbàálẹ̀ àpẹẹrẹ mìíràn ní àpapọ̀ iyẹ̀pẹ̀ àti ajílẹ̀ nǹkan ọ̀sìn, pẹ̀lú èpo ìrẹsì, àti sùkùrù àgbàdo.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí ní 1% ajílẹ̀ nínú, 1% fún èédù kọ̀ọ̀kan, kí àwọn olùṣèwádìí náà lẹ̀ sàyẹ̀wò ìṣe ìdàpọ̀ kọ̀ọ̀kan lóríi ìdára ilẹ̀ náà.

Àwọn olùṣèwádìí náà ri pé fífi èédú àti ajílẹ̀ sínú ilẹ̀ bóyá papọ̀ tàbí lọ́tọ́ọ̀tọ̀, máa ń ṣe ìfikún fún pH ilẹ̀ náà láti 0.28 sí 2.29 iye pH, ní àfiwé pẹ̀lú ilẹ̀ tí a kò ṣe ìdàpọ méjẹ́èjì sí.

Ìgbòòro pH túmọ̀ sí pé ilẹ̀ náà yóò dínkù ní ásíìdì.

Ìwádìí náà ri pé ipò ìmí básálì, tàbí iye ìmíjáde tó kéré jùlọ tí ilẹ̀ ń mú jáde, máa ń pọ̀ si ní a bá fi ajílẹ̀ nìkan sílẹ̀, tàbí tí a bá pa ajílẹ̀ pọ̀ mọ́ èpo ìrẹsì, tàbí ṣùkùrù àgbàdo àbí àpapọ̀ èédú.

Àgbàálẹ̀ àpẹẹrẹ iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ náà fi hàn pé ìkúnwọ́ àpapọ̀ kábọ́ọ̀nù ilẹ̀ sí 37% nígbà tí a lo ajílẹ̀ nìkan, àti ìfikún 117% nígbà tí a pa ṣùkùrù àgbàdo pọ̀ mọ́ ajílẹ̀.

Ìṣe àwọn kòkòrò àìfojúrí gbèrú si pẹ̀lú 132% nibi tí ilẹ̀ náà ti ilẹ̀ ti ní àpòpọ ajílẹ̀ àti èpo ìresì, ní àfiwé pẹ̀lú ìgbèrú 247% nínú ilẹ̀ fún àwọn ilẹ̀ tó ní ajílẹ̀ nìkan.

Èsì ìwádìí yìí fi hàn pé ó ṣeéṣe láti dín asíìdì inú ilẹ̀ kù nípa lílo èédú, léyìí tí kò nira láti rí tó sì dínwó lọ́pọ̀lọpọ̀.

Èyí lódì sí àwọn ọ̀nà mìíràn tá à ń gbà kọ ilẹ̀, léyìí tó wọ́n tí ó sì ṣòro àti ṣe fún àwọn àgbè olóko-kékèké tó wà ní agbègbè gúsù ilẹ̀ Áfíríkà.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?