Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àwọn olùwádìí sàfihàn irúfẹ́ sitirẹtokókọ́ọ̀sì tí ó wà ní ilẹ̀ Áfíríkà kí wọ́n le rí abẹ́rẹ àjẹsara tí ó dára jù.

Yoruba translation of DOI: 10.1128/mSphere.00429-20

Published onMay 23, 2023
Àwọn olùwádìí sàfihàn irúfẹ́ sitirẹtokókọ́ọ̀sì tí ó wà ní ilẹ̀ Áfíríkà kí wọ́n le rí abẹ́rẹ àjẹsara tí ó dára jù.
·

Àgbéyẹ̀wò lẹ́sẹlẹ́sẹ àti ṣíṣe àyẹ̀wò détà onírúurú iṣẹ́ ìwadìí lórí àtànkálẹ̀ àhunpọ̀ Strep A ní Áfíríkà láti polongo ìdàgbàsókè abẹ́rẹ àjẹsára

Ìpàjùbà:

 Ìmọ̀ràn ètò yìí tí ó dá lórí àṣùpọ̀-emm, ni iṣẹ́ ìwádìí yìí mú wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀pagun ìlànà láti mú ìrọ̀rùn bá iṣẹ́ ìwádìí ní ọjọ́ iwájú àti ìlànà sọ̀féè àjàkálẹ̀-àrùn fún Ìpín A kòkòrò ààrun sitirẹtokókọ́ọ̀sì(Strep A), purotéènì M àti ìlànà ìmúgbèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára.

A ṣe àgbékalẹ̀-aláfihan lórí àṣùpọ̀ Strep A emm ní ilẹ̀ Áfíríkà tí a sì tún ṣe àyẹ̀wò abẹ́rẹ́ àjẹsára oní falẹ́ńtì-30 ní ìlànà ajẹmọ-àṣùpọ̀.

Ìlànà:

 Àwọn aṣàyẹ̀wò méjì ní wọn ṣe àyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ ìwádìí tí wọ́n fàyọ lati àra ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwadìí, tí wọ́n sì fa dátà tí ó wà ní ìbámu fún wọn yọ.

Ìlànà ìṣe-ìtúpalẹ dátà láti ara ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìwadìí ni a ṣe àmúlò (àrà-èyíkéyìí) làti ṣe àkópọ̀ ohun tí ó wọ́pọ̀ nínú àṣùpọ̀ emm.

Esi:

 Iṣẹ́ ìwádìí mẹjọ (n=1,595 adádúró) ṣe àfihàn àṣùpọ̀ emm èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ bíi E6 (18%, 95% èyí tí kò jìnnà sí (CI), 12.6; 24.0%), E3 (14%, 95% CI, 11.2; 17.4%) àti E4 sì tẹ̀lé e (13%, 95%CI, 9.5; 16.0%).

Àlàfó tí kò pọ̀ wà nínú àṣùpọ̀ emm, èyí tí ó ní ṣe, pẹ̀lú agbègbè, ọjọ́ orí àti ipò ọrọ̀ ajé káàkiri àgbáyé.

Tí a bá wo ìlànà abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó ní ṣe pẹ̀lú àṣùpọ̀ emm, èyí tí ó máa ń dáàbò bo àwọn àṣùpọ̀ tí ó wà ní gbèdéke kan náà papọ̀, abẹ́rẹ́ àjẹsára oní falẹ́ńtì-30 èyi tí ó wà ní ipò ìmúgbèrú ninú ìṣèwòsàn lọ́wọ́lọ́wọ́, yíò pèsè ìgbéléwọ̀n tí ó le kó ìdá 80.3 ní ti ilẹ̀ Áfíríkà.

Ìkádìí:

 Iṣẹ́ àgbéyẹ̀wò lẹ́sẹlẹ́sẹ yìí ṣe àfihàn wípé ọ̀wọ́ àṣùpọ̀ emm Strep A tí ó wọ́pọ̀ jùlọ ní E6, tí E3, E4 àti D4 sì tẹ̀lé e lọ́wọ̀ọ̀wọ́.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára oní falẹ́ńtì-30 tí ó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ máa kó onírúurú ọ̀wọ́ àṣùpọ̀ emm papọ̀ káàkiri ilẹ̀ Áfíríkà.

Àwọn iṣẹ́ ìwádìí mìíràn le è gbajúmọ́ ṣíṣe òdiwọ̀n gbogboogbo fún iṣẹ́ Abẹ́rẹ́ àjẹsára oní falẹ́ńtì-30 nípa lílo ọnà ìṣèwádìí ajẹmọ-yíyànpọ̀ sẹ́ẹ̀lì pẹ̀lú àwọn aṣojú pánẹ́ẹ̀li Strep A èyí tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti ara àwọn ibí tí àìsàn Strep A tí wọ́pọ̀ jùlọ.

Pàtàkì:

 Àìkárí abẹ́rẹ́ àjẹsára jẹ́ ohun tí o ń kọnilóminú nípa ìlera gbogbo ènìyan, pàápàá ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ó sì ń gbèrú lọ́wọ́, ní ibi tí dátà lórí àjàkálẹ̀ àrùn kìí sí ní ọ̀pọ̀ ìgbà.

Láti ṣe àgbédíde Abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àwọn tí wọ́n wà ní ìpín A sitirẹtokókọ́ọ̀sì(Strep A), a ní láti jábọ̀ lórí àjàkálẹ̀ àrùn-un àṣùpọ̀ emm purotéènì M láti ara àrùn àkóràn Strep A ní Áfíríkà, ní ibi tí ó ti jẹ́ pé àwọn àìsàn tí wọ́n tan mọ Strep A ní wọn máa ń tèlé e, àwọn bíi ibà làkúrègbé àti làkúrègbé a-jẹ-mọ́ àìsàn ọkan ní ó wọ́pọ̀ jùlọ.

Ìjábọ̀ àkọ́kọ́ lórí aṣùpọ̀ emm káàkiri gbogbo àgbáyé ṣe àfihàn pé ó ṣe é ṣe kí abẹ́rẹ́ àjẹsára èyí tí wọ́n fi purotéènì M tẹ́lẹ̀ rẹ̀, èyí tí wọn ń ṣe àyẹ̀wò iṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lọ káàkiri, nibí tí wọn yóò ti lo ọ̀nà ìwadìí tí wọ́n fi àṣùpọ̀ emm tẹ́ labẹ́.


Àwọn olùwádìí sàfihàn irúfẹ́ sitirẹtokókọ́ọ̀sì tí ó wà ní ilẹ̀ Áfíríkà kí wọ́n le rí abẹ́rẹ àjẹsara tí ó dára jù.

 Lẹ́yìn àyẹ̀wò ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìwádìí lórí kòkòrò ààrun sitirẹtokókọ́ọ̀sì, àwọn aṣèwádìí tí yànnànà irúfẹ́ èyí tí ó wọ́pọ̀ ní Áfíríkà.

Èsì ìwádìí wọn yóò ṣe ìrànwọ́ fún ìwádìí lórí rírí abẹ́rẹ àjẹsara láti gbógun tí irúfẹ́ kòkòrò ààrùn náà ní pàtó.

 Ààrùn àkóràn èyí ó owà ní Ìpín A kòkòrò ààrun sitirẹtokókọ́ọ̀sì, tàbí ‘GAS’ le è da onírúurú àìsàn tí ó le, bíi àìsàn òtútù àyà àti ààmin àìsàn ajẹmọ́ ṣọ́òkì-kíkorò.

Ní Áfíríkà, ó tó mílíọ́nù 1.78 àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ààrùn GAS tí ó burú jáì.

 Oríṣìí ààrùn GAS tí àwọn onímọ̀ ti ṣàwárí jú 200 lọ, tóri náà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ti ṣe àgbékalẹ̀ bí wọ́n ti lè pín wọn sí ìsọ̀rí ìsọ̀rí nípa wíwo ìyàtọ̀ tí ó wà nínú purotéèni ìkọ̀ọ̀kan wọn tí a mọ̀ sí purotéèni M.

Làtàrí ìlò ọ̀nà yìí, wọ́n ṣe àwárí abẹ́rẹ́ àjẹsára tí yóò ṣiṣẹ́ fún àwọn ààrùn tí ó tún fi ara pẹ́ ẹ, èyí tí a mọ̀ sí àṣùjọ emm.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí ni wọn gbé lórí àwọn dátà ìwádìí tí wọ́n ṣe tí àwọn orílẹ̀ èdè tí wọn ti gbèrú, ṣùgbọ́n àwọn àlàyé díẹ̀ wà lórí bí ó ṣe máa wúlò sí ní ilẹ̀ Áfíríkà.

 Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, àwọn olùwádìí sí àfiwé àwọn dátà tí ó wà nínú iṣẹ́ ìwádìí GAS yóò ní ilẹ̀ Áfíríkà láti lè rí àrídájú irúfẹ́ àṣùjọ emm tí ó wọ̀pọ̀ jùlọ ní gbogbo àgbáyé.

Ní pàtó, wọ́n fẹ́ ní òye tí ó dunjú lórí bí ó tí ṣeéṣe kí abẹ́rẹ àjẹsára náà ṣiṣẹ́ ní agbègbè náà.

 Olùwádìí náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú wíwá àwọn iṣẹ́ ìwadìí sáyẹ́ńsì tí ó wà ní àkọsílẹ̀ nípà Áfíríkà ní gbòòrò, kí wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbájúmọ mọ́ àwọn tí wọ́n níí ṣe pẹ̀lú àṣùjọ emm ní pàtó.

Èyí ni ó fún wọn ní iṣẹ́ ìwadìí mẹ́jọ, ní èyí tí ó wà káàkiri orílẹ̀ èdè Márùn ún:

South Africa, Mali, Kenya, Tanzania, àti Tunisia.

 Lẹ́yin òríkíniwín ìtúpalẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìwadìí wọ̀nyí, àwọn olùwádìí rí àrídájú àwọn agbègbè tí àṣùjọ emm yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ, àti iye irúfẹ́ GAS tí wọ́n ti rí.

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n wá ṣe àfiwéra àwọn ohun tí wọ́n ti ri kójọ pẹ̀lú irúfẹ́ GAS tí wọ́n fẹ́ fi orí abẹ́rẹ́ àjẹsárà náà sọ ní pàtọ́.

Oríṣìí àṣùjọ mẹ́rin pàtó ni wọ́n rí tí ó wà káàkiri gbogbo àgbáyé, ṣùgbọ́n wọn kò rí ìyàtọ̀ tí ó pọ̀ nínú ọjọ́ orí tàbí ipò ọ̀rọ̀-ajé-awùjọ àwọn ènìỳn tí wọ́n ní àrùn yìí.

 Nígbà tí wọn ṣe àfiwẹ́ra irúfẹ́ GAS tí ó wà ní ilẹ̀ Áfíríkà dórí abẹ́rẹ́ àjẹsárà tí wọ́n ń lò fún ààbò rẹ̀, wọn ríi dájú pé ó ṣe é ṣe kí abẹ́rẹ́ àjẹsárà náà ṣiṣẹ dunra fún bí ìdá 60 onírúurú àwọn ààrùn náà.

Àwọn olùwádìí fàá yọ pé, ó ṣe é ṣe kí abẹ́rẹ́ àjẹsárà náà ṣiṣẹ́ fún ààbò fùn irúfẹ́ àwọn àṣùjọ emm kan náà.

Ní ṣíṣe, èyí lè túnmọ̀ sí pé abẹ́rẹ́ àjẹsárà máa dáàbò bo àwọn èèyàn ní kíkó ìdá 80 ààrùn irúfẹ́ GAS tí wọ́n ṣàwárí ní ilẹ̀ Áfíríkà.

 Ìwádìí yìí fi hàn pé ó ṣe é ṣe kí abẹ́rẹ́ àjẹsárà GAS tuntun ṣiṣẹ́ dáàdáà ní ilẹ̀ Áfíríkà, ṣùgbọ́n àwọn olùwádìí pé àkíyèsí sí pé àṣùpọ emm ti ó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà kìí ṣe nǹkan kan náà pẹ̀lú irúfẹ́ àwọn tí wọ́n rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibi yòókù ní àgbàyé.

Ní ọjọ́ iwájú, tí wọn bá ṣe àfikùn àwọn èyí ti kò hàn nínú iṣẹ́ ìwadìí ní ìgbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsárà yìí, yóò mú kí ó túbọ̀ ṣiṣẹ́ síi ní ti Áfíríkà.

 Àwọn olùwádìí fi ẹnu bà pé, ìmọ̀ kò pọ̀ tó nípa GAS ní àwọn orílẹ èdè tí ọrọ̀-ajé wọn kò dára tó.

Ṣíṣe àfikún dátà tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn agbègbè wọ̀nyí le è fún àwọn sayẹntísitì ní àwòrán kíkún lórí ìṣòro náà.

 Ní àfikún, irúfẹ́ àwọn GAS kan wà tí kò sí ní ara àwọn ètò àṣùpọ̀ emm, ó ṣe ẹ́ ṣe kí ó jẹ́ nítorípé wọ́n ti dí irú ẹ̀yà tuntun.

Awọn iṣẹ́ iwadìí ọjọ́ iwájú tí ó bá gbájúmọ́ ibi tí àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí le è wolé sí, yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìṣàtúnṣe abẹ́rẹ́ àjẹsárà, yí ò sí tún mú kí.

 Iṣẹ́ ìwádìí yìí pé àkíyèsí sí àwọn ibi tí ó ṣe pàtàkì fún iṣẹ́ iwadìí lórí ilẹ̀ Áfíríkà ní ọjọ́ iwájú, bẹ́ẹ̀ si ni òhun ni iṣẹ́ ìwadìí àkọ́kọ́ lórí àṣùpọ̀ emm GAS fún àgbáyé.

Iṣẹ́ náà jẹ́ èyí tí àwọn olùwádìí láti South Africa àti USA fọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?