Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Rògbòdìyàn ní ó ṣíwájú ìbújáde Èbolà ní orílẹ̀ èdè Congo

Yoruba translation of DOI:

Published onMay 18, 2023
Rògbòdìyàn ní ó ṣíwájú ìbújáde Èbolà ní orílẹ̀ èdè Congo
·

Ìlo Bayensia fún Awòṣe irúfẹ́ ìgbòdekan Ebola ní Orílẹ̀ èdè Congo nípaṣe ìlànà INLA-SPDE

Káárí-ayé ni wọ́n ti mọ kòkòro àrùn Èbólà (EBV) gẹ́gẹ́ bí àrùn arànmọ́ni tí ó jẹ́ pàjáwìrí fún ìlera gbogboogbò ní ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà àti àwọn agbègbè tó gboná ní Áfíríkà.

Láti ní òye nípa ìmọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn, pàápàá àrà ọ̀tọ̀ tí kòkòrò àrùn Èbólà (EBV) ní, a ṣe àtúpalẹ̀ àwọn dátà tí ó ṣe àfihàn ní pàtó àwọn tí ó ní àrùn náà àti àwọn tí àrun náà ti pa nínú ìbújáde tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè Congo (DRC) láàárín ọdún 2018 àti 2019, a sì ṣe àgbéyẹ̀wò ipa tí àwọn rògbòdìyàn tó ń lọ ní lórí ìrankiri kòkòrò náà.

Nípa lílo ìlànà ìṣirò-ajẹmọ ayé tí Bayensia láti ṣe àtúpalẹ̀ pèlú ìlò (SPDE), èyí tí ó fi àyè sílẹ̀ láti ṣe ìgéléwọ̀n ìrísí ní ìgbà gbogbo.

Ọ̀nà iṣàtúpalẹ̀ èyí tí ó dah lórí (INLA).

Ìwádìí wa fi hànde pé àjọṣepọ̀ tí ó dán mọ́rán wà láàárín ìṣẹ̀lè rògbòdìyàn ní àwọn agbègbè kan àti ìfọ́nkálẹ̀ kòkòrò àrùn Ebola (EBV) àti ikú, pèlú àṣùpọ̀ tí ó wà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ikú, tí méjèèjì ràn sí àwọn agbègbè tí wọn jọ ara wọn.

Ohun tí a rí fàyọ láti ara ìwádìí yìí wúlò fún ìdámọ àwọn ibí tí ó jẹ́ orírun, àwọn àrùn a-jẹ-mọ ibikan pàtó, sọ́féè àti ìlọ́wọ́sí.

Àwọn ipa ní 2018, fihàn pé ní 40 ọdún sí ìsìnyí, oríle èdè Congo (DRC) yóò kéde àjàkálẹ̀ àrùn ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá.

Ì̀bújáde yìí jẹ́ èyí tí ó tóbi jùlọ ní orílẹ̀ èdè náà, tí ó sì jẹ́ èyí tí ó tóbi ṣe ìkejì ní àkọsílẹ̀ lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Afíríkà ní ọdún 2014 sí 2016.

Ìbújáde tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ní wọ́n fi yé ni pé àwọn ibùdò tí a ti mọ̀ mọ rògbòdìyàn ni ó ti ṣẹ́yọ, ìwádìí yìí gbájúmọ́ ìwádìí àyè-ìpíkiri ìṣẹ̀lẹ̀ Èbólà ní DRC àti ipa tí ìṣẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn kó.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn ní àwọn agbègbè kan ni a rí pé ó ó so pọ̀ mọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Èbólà tí wọn kéde, èyí tí ó ṣe pàtàkì sí ìdámọ àwọn ibí tí ó jẹ́ orírun, àwọn àrùn a-jẹ-mọ ibikan pàtó, sọ́féè àti ìlọ́wọ́sí.


Rògbòdìyàn ní ó ṣíwájú ìbújáde Èbolà ní orílẹ̀ èdè Congo

Rògbòdìyàn ní ó ṣíwájú ìbújáde Èbolà ní orílẹ̀ èdè Congo

Kòkorò àrùn àìrí Ebola (EBV) jẹ́ àrùn arànmọ́ni, àrùn aṣekúpani, èyí tí rògbòdìyàn tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní Cong (DRC) tún jẹ́ kí ó le púpọ̀.

Ó ti wa rọrùn fún awọn olùwádìí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórí ibí tí ìgbòdekan Kòkorò àrùn àìrí Ebola yóò ti búyọ nípa ìlò dátà láti ara ibi ìṣẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn.

Káárí-ayé ni wọ́n ti mọ Ebola gẹ́gẹ́ bí àrùn arànmọ́ni tí ó jẹ́ pàjáwìrí fún ìlera gbogboogbò ní ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà àti àwọn agbègbè tó gboná ní Áfíríkà.

Ìbújáde tí ó wáyé láìpẹ́ yìí ní Congo (DRC) jẹ́ èyí tí ó tóbi ṣìkeji tí ó wà ní àkọsílẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà.

Rògbòdìyàn tí ó wà ní orílẹ̀ èdè yìí, jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ tí ó sì gbòde kan, nítorí gbogbo àwọn ohun amayedẹrùn àti àwọn irinṣe ìlera gbogbo ni wọ́n ti bàjẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì fara kááṣá.

Nínú iṣẹ́ ìwadìí yìí, àwọn olùwádìí ṣe àwárí àjọṣepọ̀ tí ó wà láàárín ìfọ́nkálẹ̀ àrùn Ebola àti rògbòdìyàn náà, nípa wíwo àwọn agbègbè tí rogbòdìyàn náà wà ní orílẹ̀ èdè Congo (DRC) ní ọdún 2018 àti 2019.

Wọn lo ìlànà ìṣirò ajẹmọ tíọ́rì Baye, èyí tí ó ṣe àmùlò ọ̀pọ̀ dátà láti lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà tàbí ibití ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ti máa ṣẹlẹ̀.

Wọ́n lo dátà nípa ìgbòdekan rògbòdìyàn ní pàtó ní àwọn agbègbè kan láti le è sọ àsọtẹ́lẹ̀ ibi tí àrùn Ebólà ti máa bẹ́ sílẹ̀.

Iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àwárí wípé àwọn agbègbè tí rògbòdìyàn wà wọ̀nyí wà lára àwọn ibi tí àrun Ẹbólà ti ràn jùlọ tí àwọn ènìyàn si ti kú pẹlú, èyí tí ó sì tún ràn káàkiri gbogbo agbègbè rẹ̀ pẹ̀lú.

Àwọn olùwádìí tún jábọ̀ lórí ìrànkiri àti ikú Èbolà ní àwọn ibi tí wọnkò ì tíì gba dátà nítorí rògbòdìyàn tí ó ń lọ níbẹ̀ lọ́wọ́.

Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní DRC, iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé wọ́n le ṣe àmúlò ìlànà Bayensia fún Awòṣe irúfẹ́ ìgbòdekan láti ṣe àwárí ibi pàtó tí Èbólà wà ní ìgbà tí dátà ko báì tíì sí.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀, àwọn olùwádìí kò lè ṣe ìyàtọ̀ láàárín irúfẹ́ rògbòdìyàn àti irú ipa tí wọ́n kó ní pàtó lórí ètò ìlera ní àwọn ibí tí iṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀.

Bákan náà wọ́n kò na ọwọ́jà dátà wọn dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn ní ọ̀nà tí wọn fi le è sọ ní pàtó ìgbà tí ìbújáde Èbólà le è wáyé.

Àwọn olùwádìí gbàá ni ìmọ̀ràn pé kí àwọn aláṣẹ ní DRC pèsè ọ̀nà tí wọ́n lè fi sọ̀féè àìsàn àti ọ̀nà tí wọ́n lè gbà máa tètè dá àwọn ènìyàn lóhùn ní àwọn agbègbè tí ọ̀rọ̀ kàn gbọ̀ngbọ̀n, àti pàápàá ní gbogbo orílẹ̀ èdè náà lati mú kí wọ́n le è tètè máa mọ, kí wọ́n sì lè dènà ìtànkálẹ̀ àrùn Èbólà.

Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?