Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Ìlo Òògùn apa kòkòro ara, Ràlẹ̀rálẹ̀, Aṣàtakò àti Ìṣàkósọ Ẹ̀ka Ohun-jíjẹ àti Iṣé Àgbẹ̀, Tanzania

This is Yoruba translation of DOI: https://www.mdpi.com/2079-6382/10/4/454#

Published onJul 24, 2023
Ìlo Òògùn apa kòkòro ara, Ràlẹ̀rálẹ̀, Aṣàtakò àti Ìṣàkósọ Ẹ̀ka Ohun-jíjẹ àti Iṣé Àgbẹ̀, Tanzania
·

Ìlo Òògùn apa kòkòro ara, Ràlẹ̀rálẹ̀, Aṣàtakò àti Ìṣàkósọ Ẹ̀ka Ohun-jíjẹ àti Iṣé Àgbẹ̀, Tanzania

Abstract

Gbogbo àrùn ni ó ṣe é wò níwọ̀n ìgbà tí àwọn kòkòrò-àìfojúrí tí ń fa àrùn ò bá ní agbára tó òògùn apa kòkòro ara.

Iṣọwó tí ipá àwọn òògùn apa kòkòro ara ṣe ń díkùn ti ń di ewu fún ètò ìlèrà ágbàáyé èyí sì jẹ́ ewu ńlá tí ó lè mú ìfàsẹ́yìn bá òògùn apa kòkòro ara fún ìkápá àrùn.

Bí bíbéèrè fún àwọn oúnjẹ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ẹranko ṣe ń pọ̀ si, pàápàá jùlọ ẹyin, ẹran, àti mílíìkì èyí ló ṣokùnfa ètò ìṣelọ́pọ̀ àwọn oúnjẹ yìí fún títà, èyí sì lè jẹ́ kí àpọ̀jù àti àṣìlò àwọn ohun òògùn apa kòkòro ara.

Òògùn apa kòkòro ara, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àgbẹ̀ àti àwọn lamóòjútó ẹran ọ̀sìn, tí wọ́n ń lò ó láìní ẹ̀kọ́ ìwé, lè di àṣìlò àti ṣíṣe sí àìgbọ́ràn àsìkò dídínkù rẹ̀.

A ṣe ìwádìí yìí láti mọ àwọn òfin àti ìṣàkóso àwọn òògùn apa kòkòro ara, láti fí ọ̀nà àti òṣùwọ̀n ìlò wọn múlẹ̀, ṣàyẹ̀wò àwọn ràlẹ̀rálẹ̀ òògùn apa kòkòro ara àti aṣàtakò tó wà nínú oúnjẹ ohun ọ̀sìn àti ètò aṣàróbọ̀ ohun ọ̀gbìn, àti láti ṣe àkàwé ìwádìí yìí sí àwọn ọ̀nà ìgbà gbógun ti ìfarahàn aṣàtakò òògùn apa kòkòro ara ní Tanzania.

Oríṣi ọ̀nà ìgbà ṣe nǹkan (àtúnyẹ̀wò abẹ́lé, ìwádìí, ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò lọ́lọ́kan-ọ̀jọ̀kan) ni wọ́n ṣàmúò.

Àbẹ̀wò àwọn ilé-iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì sí ìwádìí.

Ìjábọ̀ wà pé ìtakò tó lágbára sí pẹnsilíí G, kilorafẹ́níkọ̀, sẹtẹtomisíí, ọsitẹtirasaikílíìnì, pàápàá fún jùlọ fún Actinobacter pyogenes, àti oríṣiríṣi àtọ̀sí láti ara màálù tí wọn fún wàrà pẹ̀lú àrùn ọmú nínú àwọn eniyan.

Wọ́n rí ohun tí ó jọmọ́ àrùn yìí ní ilé adìyẹ níbi tí àwọn eyin àti ẹran ti kó àrùn kọ́lì (E. coli) tí ó tako àwọn òògùn ìpa-kòkòkò-batéríà amọsilíì + kilafulanáàtì, sulphamethoxazole àti neomycin.

Ìṣọwọ́ jẹyọ àwọn òògùn atako òògùn apa kòkòro ara bí I E.coli, klebsiella pneumonia, staphylococcus aureus àti Salmonella pọ̀jù bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n jẹyọ nínú àwọn ẹran-an jẹ.

Ìjábọ̀ wà fún ìṣọwọ́ jẹyọ àrun methicillin-resistant staphylococcus aureus (MRSA) àti extended-spectrum beta-lactamase(ESBL) láàárín àwọn ẹ̀ka ohun ọ̀sìn ní Tanzania.

Àwọn afàìsàn tí a yà sọ́tọ̀ nínú àwọn ẹranko ń tako apicilíì, ọgumẹtíì, jẹtamisíì,co-trimoxazole, tẹtasaikíì, amosilíì, streptomycin, nalidixic acid, azithromycin,chloramphenicol, tylosin, erythromycin, cefuroxime, norfloxacin àti ciprofloxacin.

Wọ́n ṣe àkíyèsi ìṣọwọ́ lò àwọn ìpa-kòkòkò-batéríà láti dẹ́kun àwọn àrùn, àti ….. tí ó lòdì sí àwọn kòkòrò-àìfojúrí tí ó ń fa àrùn àti ìdàgbàsókè àwọn ẹranko, ẹran inú omi, àti àwọn ohun ọ̀gbìn.

Ìpè fún ị̀ṣọ̀kan ètò ìlera láti gbógun ti ìṣàtakò òògùn apa kòkòro ara (AMR) ní ẹ̀ka ètò oúnjẹ àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Tanzania.

Àwọn àbá tí ó ṣe é ṣàmúlò ni (a) àyẹ̀wò àwọn òfin àti ọ̀nà ìgbà lò wọ́n; (b) ìkéde mímọ̀ àti ìpè láàárín àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nínú ètò aṣàróbọ lóri ìlo òògùn apa kòkòro ara, AMR àti ràlẹ̀rélẹ̀ ohun ìpa-kòkòrò-batéríà; (d)ìmúnádoko àwọn ètò ìwádìí àti ìtọpínpín àwọn ètò fún AMU, AMR ati AR; (e) ìmúgbòòrò ìdàgbàsókè àti ìlo àyẹ̀wò àrùn tó yára ajẹmọ́ ìmọ̀ ọ̀tun àti ìlọsíwájú àbọ̀ lọ́wọ́ kẹ́míká; àti (ẹ) àmúlò ìtọ́jú tó péye fún àwọn ohun ọ̀sìn.

Ìlò àwọn àlàyé yìí láti ṣe àtúṣe sí ìlànà ètò ìlera gbogbogbò àti dídin ẹrù AMR kù yóò jẹ́ àǹfàní.

Summary Title

Ṣíṣe àmúlò ìlànà tó dáńgájíá lè dín àpọ̀jù ìṣàtakò òògùn apa kòkòro ara kù ní Tanzania

Tanzania ní ìṣàtakò òògùn apa kòkòro ara tí ó pọ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé àwọn òògùn tí wọ́n wò àwọn àrùn tí wọ́n jẹyọ láti ara ìkóràn batéríà kì í ṣiṣẹ́ fún wọn.

Àwọn aṣèwádìí ṣàyẹ̀wò ohun tí ó lè jẹ́ okùnfà ìṣàtakò òògùn apa kòkòro ara fínífíní, wọn sì ri pé ó yẹ kí wọ́n dín àwọm ìlànà tí ò tọ́ kù ní ẹ̀ka oúnjẹ àti iṣẹ́-àgbẹ̀ kí ìṣàtakò òògùn apa kòkòro ara lè dín kù.

Wọ́n máa n lo òògùn apa kòkòro ara lọ́pọ̀ yanturu nínú oúnjẹ tí wọ́n fi ẹran ṣe, bẹ́ẹ̀ náà wọ́n sì ti dábàá lílò rẹ̀ ní ẹ̀ka àwọn elétò ìlera, èyí sì dín ipa rẹ̀ kù.

Ewu ńlá ni òògùn apa kòkòro ara jẹ́ fún ìlera kárí-áyé.

A lè tọpasẹ̀ àlòjù òògùn apa kòkòro ara lára ẹran ọ̀sìn dé ọ̀dọ̀ àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹranko tí wọn kò ní àmúyẹ láti ṣe àmúlò àwọn òògùn apa kòkòro ara yìí látàrí pé wọn kò ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó yè kooro.

Ohun tí ìwádìí yìí gùnlé ni láti tọpínpín bí òfin ìjọba lóri lílò òògùn apa kòkòro ara ni Tanzania ṣe múlẹ̀ tó.

Àwọn aṣèwádìí tún fẹ́ mọ̀ bí àlòjù òògùn apa kòkòro ara ṣe tó nípa wíwo ràlèrálè rẹ̀ lára àwọn ọhun-ọ̀sìn àti ètò aṣàróbọ̀ ohun-ọgbin.

Àfojúsùn wọn ni láti dábàá àwọn ètè tí wọ́n lè fi kápá ìṣàtakò òògùn apa kòkòro ara ni orílè-èdè náà.

Àwọn aṣèwádìí ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìwé, wọ́n sì ṣàbẹ̀wò sí àwọn ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ń lo àwọn òògùn apa kòkòro ara.

Wọ́n kíyèsí, wọ́n sì fọ̀rọ wá èèyàn 32 lẹ́nu wò, bẹ́ẹ̀ ni wọn jíròrò pẹ̀lú àwọn ẹni 83 tó jẹ́ àgbẹ̀ ọlọ́sìn adìyẹ.

Ìwádìí yìí rí iṣàtakò sí òògùn apa kòkòro ara tí ó ga bí pẹnsilíì G, kọrafẹ́nikọ̀, sẹtọmisíì, ọsitẹtirasakilíì.

Wọn máa n lo àwọn òògùn apa kòkòro ara pàtàkì wọ̀nyí láti kojú àwọn afàìsàn bí i Àtọ̀sí, tí ó fa àrùn ọmú fún ènìyàn àti àwọn màálù tí wọ́n fún wàrà lara wọn.

Wọ́n rí àwọn èsì mìíràn tí ó dọ̀kan rú ni ẹ̀ka ẹran ọ̀sìn ní Tanzania, bíi àpọ̀jù aṣàtakò fún òògùn apa kòkòro ara (E.coli), tí ó le fa àìsàn inú dídàrú díẹ̀ tàbi gan-an.

Àwọn aṣèwádìí ṣèkìlọ̀ pé ìṣọwọ́ tí àwọn àgbè fi ń lo òògùn apa kòkòro ara fún ìdènà-àrùn (láti sénà mọ́ àrùn) àti láti jẹ kí àwọn ẹran ọ̀sìn tètè dàgbà ti pọ́jù.

Àwọn àṣèwádìí fi dábàá pé ẹ̀ka iṣẹ́-àgbẹ̀ ọlọ́gbìn ni Tanzania lo ọ̀na ètò ìlera, èyí tí ó nííse pẹ̀lú àyíká, ẹranko àti àwọn ènìyàn tó kópa nínú bi àrun ṣe máa ń tàn kálé-káko, láti kojú ìṣàtakò òògùn apa kòkòro ara.

Ìwádìí náà pète pé kí Tanzania ṣe àtúnwò àwọn ọnà-ìsòfin tó níṣẹ pẹ̀lú iṣẹ́-àgbẹ̀ àti bí wọn ṣẹ lè ṣe àmúlò rẹ̀.

Àwọn àṣèwádìí pè fún ṣíṣe àmúlò sísin ẹran-ìjẹ tó tún dára sí i fún àwọn eran ọ̀sìn àti pé kí wọn ṣe àyẹ̀wò àìsàn fún wọn láti mọ ìlera àti àbò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, kí àlòjù òògùn apa kòkòro ara tí wọn ò lérò lè díkùn.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?