Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì tọ́ka sí àyípadà DNA tí ó ń fún àwọn ẹ̀fọn ilẹ̀ gúúsù Áfíríkà ní àǹfààní láti ye ìpakòkòrò

Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.05.05.078600

Published onAug 07, 2023
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì tọ́ka sí àyípadà DNA tí ó ń fún àwọn ẹ̀fọn ilẹ̀ gúúsù Áfíríkà ní àǹfààní láti ye ìpakòkòrò
·

Ìyàtọ̀ ìhun ajẹmẹ́yọ-ìran 6.5kb kan ń ran èrò ìgbógun ti ìpakòkòrò tí ó tipasẹ̀ P450 nínú ìbà tih ó ń dín agbára àwọn ìbùsùn kù.

Ní ọ̀gangan yìí, a fọ́ ipa ìyàtọ̀ ìhun (SV) 6.5kb ní gbígbé agbára ìdojúkọ párẹ́tọ́ìdì sátókóòmù P450 nínú ibà Anopheles funestus.

Odidi apó jíìnì tí wọ́n ṣà tí wọ́n ṣì tò ló ṣàwárí àdàpọ̀ jíìnì 6.5kb SV nínú àlòtúnlò àwọn CYP6P9a/b P450 lára àwọn àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n lágbára ìdojúkọ párẹ́tọ́ìdì bí wọ́n ṣe ń gbé wọn láti ibìkan sí òmíràn.

Ìtúpalẹ̀ àwọn agbátẹrù fi iṣẹ́ ìlọ́po 17.5 (P<0.0001) hàn lórí èyí tí ó ní SV yàtọ̀ sí èyí tí kò ní.

Ìṣọ̀nà qRT-PCR tí ó sọ CYP6P9a/b fún ìran SV náà fara mọ́ ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ aṣàmúdúró níwọ̀ ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn SV+/SV+ ní ìapa tí ó gbòòrò lórí àwọn gíìnì náà ju ti àwọn ẹlẹ́yọ kan lọ SV+/SV- (1.7-2-fold) àti ẹllẹ́yọ kan SV-/SV- (ìlọ́po 4-5).

Pípilẹ̀ wíwo àkókónú PCR fi hàn pé ìbáṣepọ̀ tí ó gbópọn wà láàrin SV yìí àti agbára-ìdojúkọ párẹ́tọ́ìdì (SV+/SV+ vs SV-/SV-; OR=2079.4, P=<0.001).

6.5kb SV pọ̀ ni apá gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà (80-100%) àmọ́ kò sí rárá ní ìlà-oòrùn/ìwọ̀-oòrùn àti ààrin gbùngbùn Áfíríkà.

Àyẹ̀wò-ìdànwo inú héré fi hàn pé àwọn ẹ̀fọn SV tí gíìnì wọn jọra ni àǹfàní tó jọjú láti yè é bí wọ́n bá kọlù àwọn àwọ̀n (OR 27.7; P < 0.0001) tí a fi párẹ́tọ́ìdì tọ́jú kí wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ.

Síwájú si, ìdojúkọ àwọn gíìnì onílọ̀ọ́po mẹ́ta (SV+/CYP6P9a_R/CYP6P9b_R) ní agbára ìdòjúkọ tí ó g tí ó sì lè jásí ipa láti ye àwọ̀n ìpẹ̀fọn tí wọ́n lo ìlọ́po mẹhta èròjà láti pèsè, èyí tí ó ṣàfihàn ìmọ́lára tó ga.

Ìwádìí yìí mẹ́nu ba pàtàkì ipa ìyàtọ̀ ìhun nínú ìgbèǹde agbára-ìdojúkọ ìpakòkòrò nínú àwọn afabà àti ipa burúkú wọn lórí bí àwọn tí wọ́n fi párẹ́tọ́ìdì tọ́jú ṣe ń ṣiṣẹ́.


Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì tọ́ka sí àyípadà DNA tí ó ń fún àwọn ẹ̀fọn ilẹ̀ gúúsù Áfíríkà ní àǹfààní láti ye ìpakòkòrò.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ti tọ́ka sí àwọn DNA tí ó ran àwọn ẹ̀fọn láti dojúkọ àwọn kẹ́míkà tí ó yẹ kí ó pa wọ́n (ìpakòkòrò).

Ó dà bí ẹni pé ìfàgùn DNA yìí ń ṣègbè fún àwọn gíìnì tí wọ́n ń jẹ́ kí àwọn ẹlfọn apá gúúsù Áfíríkà lè gbà párẹ́tọ́ìdì dáadáa, tí ó jẹ ìpakòkòrò tí ó wọ́pọ̀ tí wọ́n ń fi sí àwọn lahti di àwọn ẹ̀fọn lọ́wọ́ nípa títan ibà káàkiri àwọn ènìyàn.

Àwọ̀n tí fi ìpakòkòrò tọ́jú rẹ̀ ni ọ̀nà kan gbòógì láti dẹ́kun àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n ní ibà ṣè lè tàn án ká sára àwọn ènìyàn.

Àmọ́ sa, ó jọ bí ẹni pé àwọn ẹ̀fọn ní kòpẹ́-kòpẹ́ ń rù ú là kódà bí wọ́n bá ko apakòkòrò burúkú.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńì fẹ́ wo ọ̀gangan ìdí ajẹmọ́bàólọ́jì tí ó ń tì agbára-ìdojúkọ ìpakòkòrò lẹ́yìn kí wọn ó lè túnbọ̀ ṣe àwọn àwọn ìpẹ̀fọn kí wọn ó dára sí i.

Nínú ìwádìí yìí, àwọn aṣèwádìí fẹ́ ṣàfihàn bí ìfàgùn àyípadà DNA nínú àwọn ẹ̀fọn ibà ṣe ń ṣe àlékún agbára ìdojúkọ sí ìpakòkòrò párẹ́tọ́ìdì.

Wọ́n tún fẹ́ mọ̀ bóyá ìyípadà ajẹmọ́ran yìí wà nínú àwọn ẹ̀fọn ní àwọn agbègbè mìíràn ní Áfíríkà.

Àwọn aṣèwásìí ṣe ìtúpalẹ̀ DNA onírúnrú òǹkà iye ẹ̀fọn, wọ́n sì wọ bí ìdojúkọ wọn sí párẹ́tọ́ìdì ṣe tó.

Wọ́n ṣe àmúlò àwòṣe oníkọ̀mpútà, àyẹ̀wò-ìdáwò inú láàbù, àti fífi ẹ̀fọn ṣe àṣedánwò nínú ahéré kí wọn oh lè fẹ́nu kò lórí ìpinnu wọn.

Wọ́n rí i pé wíwà DNA náà ló jásí kí àwọn ẹ̀fọn ibà lè ṣe ìgbédìde ìdojúkọ sí àwọn tí wọ́n ti fi apakòkòrò dáàbòbò.

Gbogbo àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n dojúkọ párẹ́tọ́ìdì ní àyípadà DNA fífẹ̀.

Àmọ́ ó dùn mọ́ni pé, láti apá gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà ni àwọn ẹ̀fọn yìí ti wá, àwọn àyípadà náà kò sí nínú àwọn ẹ̀fọn oníbà tí ó wà ní ìwọ̀-oòrùn, ìlà-oòrùn, àti ààrin-gbùngbùn Áfíríkà.

Àwọn onímọ̀ sáyéńsì ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n ń fa ibà dojúkọ àwọn kẹ́míkà tí à ń lò láti pa wọ́n, ìwádìí yìí ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń yẹra fún apakòkòrò ní ìpele ajẹmẹ́yọ-ìran.

Àwọn olùṣèwádìí náà ti ṣèdá ìlànà tuntun mìíràn láti mójú tó DNA nínú ẹ̀fọn, léyìí tí yóò wúlò fún àwọn akóṣẹ́mọṣẹ́ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ lọ́jọ́ọwájú.

Àwọn aṣèwádìí dábàá pé kí àwọn iṣẹ́ ọjọ́-ìwájú ṣe àwòjinlẹ̀ irú àwọn àyípadà DNA wọ̀nyí àti bí wọ́n se nípa lórí agbára-ìdojúkọ gíìnì tí àọn ẹ̀fọn oníbà ní.

Ìwádìí tí àwọn aṣèwádìí ilẹ̀ Cameroon ṣe yìí fi hàn pé a nílò àwọn ọ̀nà tuntun láti darí ìtànkálẹ̀ ibà, pàápàá jùlọ ní apá gúsù Áfíríkà, níbi tí a ti ní àwọn ẹ̀rí DNA tí ó fi ìdí tí àwọn ẹ̀fọn fi ń ráàyè pẹ́ àwọ̀n tí wọ́n ti fi apakòkòrò sí sílẹ̀.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?