Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àfarawé àti Ìṣepépé ti Èto Agbára Alálòtúnlò Onípeleméjì fún Semonkong, Lesotho

Yoruba Translation of DOI: 10.1007/978-3-319-93438-9_9

Published onJul 22, 2023
Àfarawé àti Ìṣepépé ti Èto Agbára Alálòtúnlò Onípeleméjì fún Semonkong, Lesotho
·

Abstract

Àwọn òkè àti àpáta tí àwọn ilú kéréjẹ́ yí ká ni ó pọ̀jù lọ ní Lesotho, léyìí tó mú kí àsọpọ̀ pọ́ gíríìdì iná àpapọ̀ jẹ́ èyí tí yóò náni lówó púpọ̀.

Àyì ní àǹfààní sí iná yìí fa ìdíwọ́ fún awọn ohun amáyédẹrùn àti ìdàgbàsókè okòòwò nítorí i iná ò lè di fífà sí àwọn ilé, ilé-ìwé, àgọ́ ọlópàá, ilé-ìlera àti ìsọ̀.

Àbọ̀ ìwádìí yìí gbàáníyànjú pé kí a lo agbára-alálòtúnlò ni àwọn ilú bí i Semenkong ní agbègbe Maseru ni Lesotho.

Módẹ̀lì ìwádìí náà, fi àǹfààní ètò iná onílòméjì hàn nípa lílo Semonkong àti iye amáyédẹrùn ìlòtúnlò dátà sólà, eré afẹ́fẹ́ àti ìṣàn omi láti ibi odò Maletsunyane.

Àwọn ẹ̀rọ HOMER jẹ́ lílò fún àtúnwáyée ẹ̀rọ nílò pẹ̀lúu LCOE àti ìpín agbára-alálòtúnlò tó níṣe pẹ̀lú onírúurúu àòtúnlò àti irúfẹ́ àwọn ònà agbára mìíràn ti ìfanádimọ̀nàmọ́náa sólà, ẹ̀rọ asafẹ́fẹ́dináamọ̀nàmọ́ná, ẹ̀rọ asomidináamọ̀nàmọ́ná ẹ̀rọ amúnáwá oní dísù àti ìpamọ́ọ bátíìrì. Àwọn ìfọ̀wọ̀wérọ̀ nípa sólà, erée afẹ́fẹ́, ìṣàn omi, owó iye epo àti agbára jẹ́ èyí ti a lè fi wo ìṣeéṣe èto agbára ìlòtúnlò dé ìparí tí ó dára jùlọ fún àwọn agbègbè ìgbèríko.

Èsì ìwádìí fún ìkójú-ìwọn omi/afẹ́fẹ́/PV/dísù/ èto bátíìrì onílòméjì LCOE ti US$0.289/kW ni ìpín agbára-alálòtúnlò ni 0.98.

Fun ìdí náà, ẹ̀rọ amúnáwá oní dísù náà yóò máa jẹ́ lílò láti ṣe ìfikún sí iná fún Semonkong pàápàá nígbà oṣù ẹ̀rùn àti òtútù ní Èbìbí sí Ọwẹ́rẹ̀ nígbà tí ìpè fún ìlò iná bá wà ní òtéńté ṣùgbọ́n tí sólà àti ìṣàn omi wà ní ìsàlẹ̀.

Summary Title

Àwọn agbára-alálòtúnlò tó dínwó ṣeéṣe fún Semonkong, Lesotho.

Àwọn olùṣewádìí sọ pé àwọn ìgbèríko Semonkong ní Lesotho lè ṣe ẹ̀dínwó iná ọba pẹ̀lú ìdá 40% nípasẹ ìmúgbóòrò agbára-alálòtúnlò nínú ìdàpọ̀ gíríìdì ìbílẹ̀ láti ìdá 66% sí ìdá 98% nípa lílo afẹ́fẹ́, ìsomidiná, bátìrì àti ìfanádimọ̀nàmọ́ná.

Ìdá 2% tó kù yóò jẹ́ èyí tí a ó lo epo dísù fún.

Ilú kékeré Semonkong, ni dísíríìtì Maseru, ẁ ní agbègbè tí àwọn òkè àti àpata wà ni Lesotho, léyìí tó mú àti ṣètò iná ìjọbá wọ́n lágbègbè náà.

Nítorí náà, Semonkong ń lo ète ìsomidiná lọ́wólọ́wọ́ tí odò ìbílẹ̀ Maletsunyane ń gé jáde láti ṣe àfikún ìdá 66% sí àpapọ̀ iná rẹ̀.

Ìdá 34% tó kù yóò jẹ́ èyí tí a ó lo epo dísù fún.

Ìmọ̀ náà pinu láti lo àwọn ẹ̀rọ HOMER láti fi ṣe ìṣirò iye iná tí a lè ṣẹ̀dá látara àwọn èrònja agbára-alálòtúnlò náà tí ó wà ní agbègbè náà ní iye tí ò ga jara lọ.

Àwọn olùṣèwádìí lo èrọ HOMER nínu gíríìdì iná ìbílẹ̀ Semonkong nínú ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà nípa ṣíṣàyẹ̀wo ìṣesí fífikún àwọn agbára-alálòtúnlò ìgbàlódé bí i ìfanádimọ̀nàmọ́ná, afẹ́fẹ́, ìsomidiná, àti ìpamọ́ọ bátíìrì.

Àwọn olùṣèwádìí ṣèṣirò iye tí ẹ̀rọ amúnáwá loopt (LCOE) fún ọ̀kọ̀ọ̀kan gíríìdì àpòpọ̀ iná láti ṣàwárí iye tí yóò nọ́ni fún ìṣeparí iṣẹ́ náà.

Àwọn olùṣèwádìí ri pé gíríìdì iná tó dínwó jùlọ fún Semonkong ni agbára-alálòtúnlò tí a ṣàpòpọ̀ pẹ̀lú afẹ́fẹ́, ìsomidiná, àti bátírì.

Àpòpọ gíríìdì náà yóò jẹ́ ìdá 94% agbára-alálòtúnlò, léyìí tí ìdá 6% tó kù yóò jẹ́ èyí tí a ó fi ẹ̀rọ amúnáwá oní dísù gbé.

Ẹ̀da àṣàyàn tó ga jùlọ ti agbára alálòtúnlò ní ìdá 98% fi kún ìfanádimọ̀nàmọ́ná sí àpapọ̀ gíríìdì iná tó dínwó jùlọ, nípa fífi ìdá 2% sílè tí yóò jẹ́ pé ẹ̀rọ amúnáwá oní dísù ni yóò gbe.

Tí àwọn ẹ̀rọ HOMER kọ̀mpútà yìí bá di ṣíṣe, yóò ṣe ìgbèrú fún àpapọ̀ gíríìdì iná ti alálòtúnlò ìsomidiná láti inú odò Maletsun yane, léyìí tí yóò jẹ́ 66%, tí ẹ̀rọ amúnáwá yóò kájú ìdá 34% tó kù.

Ìwádìí náà fi hàn pé gíríìdì tó bá ní ìdá 98% agbára-alálòtúnlò yóò dínwó pẹ̀lúu ìdá 40%.

Ìwádìí náà lo dátà sí Semonkong, léyìí tó mú kí àbájáde iwádìí náà fì sí Semonkong nìkan.

Wàyí o, iwádìí yìí fi hàn pé àwọn ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ bí i afẹ́fẹ́, odò, àti àwọn agbègbè tí òrún ti pọ̀ lè jẹ́ lílò fú gíríìdì ìbílẹ̀ àti àpapọ̀ ní owó tí ò ga jara lọ.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?