Description
Lay summary of the research article published under the DOI: 10.1101/2020.04.14.20064717
This is Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.04.14.20064717
Ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́ ni èyí tó bá ṣẹlẹ̀ sáájú ọ̀ṣẹ̀ 37.
A ṣe ìwádìí láti ṣe ìgbédìde fún àṣepọ̀ ipò abo lórí i sẹ́lẹ́líómù, kọ́pà, síǹkì, àti ìkúnlẹ̀ à̀ìtọ́jọ́.
Àwọn obìnrin 181 ni ó wà nínú iṣẹ́ ìwádìí ná̀, 90/181 (49.7%) tó jẹ́ àti 91/181 (50.3%) tí ò jẹ́ aláboyún.
Èyí túmọ̀ sí pé àpapọ̀ sẹ̀lẹ́níómù jẹ́ 77.0; SD 19.4µg/L, kọ́pà jẹ́ 2.50; SD 0.52 mg/L and síǹkì jẹ́ 0.77; SD 0.20 mg/L pẹ̀lú ìtọ́ka iye 47-142µg/L, 0.76-1.59mg/L and 0.59-1.11 mg/L, ní ṣíṣe-n-tẹ̀lé.
For preterm birth, mean serum concentrations for selenium was 79.7; SD 21.6µg/L, copper was 2.61; SD 0.57 mg/L, and zinc was 0.81; SD 0.20 mg/L compared to that of term births: selenium (74.2; SD 16.5µg/L; p=0.058), copper (2.39; SD 0.43 mg/L; p = 0.004), and zinc (0.73; SD 0.19 mg/L; p = 0.006) respectively.
In adjusted analysis, every unit increase in maternal selenium concentrations gave increased odds of being a case OR 1.01 (95% CI: 0.99; 1.03), p=0.234, copper OR 1.62 (95% CI: 0.80; 3.32); p = 0.184, zinc OR 6.88 (95% CI: 1.25; 43.67); p=0.032.
Àbájáde ìwádìí fi hàn pé kò dí kùdìẹ̀kudiẹ sẹ̀líníọ́mù, àti síǹkì, àti akópọ̀ kọ́pà nínú ìlóyún.
Ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́ jẹ́ èyí tí a yín mọ́ àpapọ̀ kọ́pà àti síǹkì lára obìnrin.
Àwọn olùṣèwádìí rí àpọ̀ju àwọn èròjà aṣaralóore kékèké bí i sẹ̀rílíọ́mù, cọ́pà, àti síǹkì, nínú àwọn obìnrin tí ó ní ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ bóyá àwọn àpọ̀jù wọnyí wá́ látara oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ.
Ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́ máa ń ṣẹ̀ tí obiùnrin bá bímọ ṣáájú ọ̀ṣẹ̀ 37 tí ó lóyún.
Ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́ jẹ́ èyí tó ní ìbáṣe pẹ̀lú àwọn àìlera fún ọmọ láti kí ara ọmọ́ má dà á sí ikú.
Ohun tí ó lè fa ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ipa tí àpọ̀jù àwọn èròjà aṣaralóore kékèké tí à ń rí nínú oúnjẹ àti agbègbè wá jẹ́ èyí tí a ò tí ì mọ̀.
Àwọn àpapọ̀ àwọn èròjà aṣaralóore kékèké yìí ṣe pàtàkì sí ìdàgbàsókẹ̀ ọmọ náà, ṣùgbọ́n àwọn olùṣèwádìí fẹ́ mọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá pò jù.
Fún ìwádìí yìí, àwọn olùṣèwádìí gbèrò láti mo iye ìwọn sẹ̀rílíọ́mù, cọ́pà, àti síǹkì nínú obìnrin tí ó ní ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́, àti láti bí ipa tí ọ̀kọ̀ọ̀nkan àwọn èròja yí ń kó nínú ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́.
Àwọn olùṣẹ̀wádií náà gba èjẹ̀ àwọn obìrin 181 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bímọ tán ní họsibítù méjì ní Lilongwe, ní olú ìlúu Malawi, láàárín June 2016 àti March 2017.
Wọ́n gbé àwọn àpẹẹrẹ èjẹ̀ náà lọ sí inú láàbù ní orílẹ̀-ède Norway níbi tí wọ́n ti ṣe àfàyọ sẹ́rúmù tí wọ́n sì ṣe ìwọn sẹ̀rílíọ́mù, kọ́pà àti síǹkì.
Bí i ìdajì lára àwọn 181 obìrin náà tí wọ́n lò nínú ìwádìí náà ló ní ìkúlẹ̀ àìtọ́jọ́, bẹ́ẹ̀ àwọn olùṣèwádìí rí àpọ̀ju sẹ̀rílíọ̀mù, kọ́pà àti síǹkì.
Wọ́n sì ṣe àtúnṣe ìṣirò wọn láti ṣàfihàn fún àwọn ìdí mìíràn bí i ọjọ́-orí, àjíǹde ara, àti ìtàn ìlóyún láti lè rí okùnfa àwọn èròjà aṣaralóore kékèké tí ó ń fa ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́ náà.
Wọ́n pinnu pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ sẹ̀rílíọ́mù àti cọ́pà kò kó ipa tó kọjú nínú ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ síǹkì ń fi ewu kún ìwáyée ìkúnlẹ̀ àìtọ́jọ́ ju ìgbà 6.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye cọ́pà jẹ́ ohun ìkọminú fún àwọn olùṣèwádìí náà, nítorí àwọn ohun ewu ló wà níbẹ̀.
Nípa níní obìnrin 181 tí ó kọ́pa nínú ìwádìí náà ṣe ìdíwó fú àwọn olùṣèwádìí náà láti lè wá àwọn ewu tó so pọ̀ mọ́ níní ọ̀pọ̀lọpọ̀ sẹ̀rílíọ́mù, léyì tó jẹ́ pé àwọn olùkópà tó yèkooro jẹ́ 600.
A kò ṣe àyẹ̀wò fún oúnjẹ tí àwọn olùkópa náà ń jẹ láti mọ ibi tí àwọn èròjà kékèké náà ti wá, àti pé BMI wọn kò sí ní àkọsílẹ̀.
Èyí ni iṣẹ́ ìwádìí irú rẹ tí yóò wo ìwọn ìjẹyọ sẹ́líómù, kọ́pà àti síǹkì ní ara aláboyún ni Malawi.
Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni ó ní ìkúlẹ̀ àìtójọ́ tó ga jùlọ ní ìwọn – léyìí tó ju 18% lọ tí a bá ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilú òyìnbó tọ́ ní 5% nítorí náà àwọn olùṣèwádìí fẹ́ mọ̀ bóyá ìjẹṣaralóore ní ipa tó ń kó.
This is Amharic translation of DOI: 10.1101/2020.04.14.20064717
This is Hausa translation of DOI: 10.1101/2020.04.14.20064717
This is Zulu translation of DOI: 10.1101/2020.04.14.20064717
This is a Luganda translation of DOI: 10.1101/2020.04.14.20064717
This is a Northern Sotho translation of DOI: 10.1101/2020.04.14.20064717