Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1101/2021.02.08.21251393)
Yoruba translations of DOI: 10.1101/2021.02.08.21251393
SARS-CoV-2 ìṣàkíyèsí ìyídà àìsàn ní Uganda ṣe ìpèse àyè láti lè pèse àlá̀yé tó péye lórí ìdàgbàsókè aàrùn náà ní ilú ḱkeré tí ilẹ̀ yí ká ní apá ìlà oòrun Áfíríkà.
Níbí ni a ti ṣe àfihàn ìsún lórí I àjàkálẹ̀ aàr̀n náà lábẹ́lé pẹ̀lú irúfẹ́ ìtàn tuntun A.23 tí ó ń yí sínú u A.23.1 léyìí tó ń jẹ́ láboríaàrùn ní Uganda tó sì ti tàn ká sí orílẹ-ède 26 mìíran.
Wàyí o ìyípadà nínú u A.23.1 léyìí tó ti ń di mọ́lí yàtọ sí àwọn ìyípadà nínú irufẹ́ èyí tí ọ̀rọ́ kàn (VOC), ìdàgbàsókẹ̀ náà fi ìparapọ̀ lórí I ọ̀wọ́ purotéènì kan.
A.23.1 náà ṣe ìrúsóke agbègbe purotéènì náà ti ó ń ́yídà léyìí tí ó jọ ọ̀pọ ìyíd̀à tí a rí nínú VOC pẹ̀lú ìyídà ipò ní 613, ìyídà ní agbègbe fúríìnì tí ó ṣe ìfikún fún àmínó asiìdì, àti ọ̀pọ̀ ìyídà nínú àká imunojẹ̀nẹ́tíìkì ìwa-N.
Láfikún, irúfẹ́ A.23.1 náà ní ìyídà lára àwọn purotéènì tí kò ń ṣe ìrúsókè tí àwọn VOC mìíran máa ń gbẹ́ yọ (nsp6, ORF8 àti ORF9).
Ipa ìmọ́tótó irúfẹ́ ẹ A.23.1 náà kò tí ì hàn dáradára, ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì kí a tẹ̀síwájú láti máa mójú tó ̀ẹ̀dà yìí, àti isègbéléwọ̀n àwọn aṣemáṣe irúsókè ìyídà purotéènì náa fún èsi àjẹsára tó tẹ̀wọ̀n tó.
Ní 2021, àwọn olùṣèwádìí jábọ pé oríṣí ẹ̀dà tuntun SARS-CoV-2, aàrùn tó ṣokùnfa Covid-19, gbèrú ní Uganda tó sì tànká sí àwọn orílẹ̀-ède 26 mìíràn.
Wọ́n sọ ẹ̀dà náà ní “A.23.1”, wọ́n sì sọ pé ó ní ọ̀pọ àwọn ìyídà nínú u purotéènì tí àwọn olùṣèwádìí ti wòye nínú àwọn ẹ̀da èyí tí ọ̀rọ́ kàn lágbàáyé lásìkò yí.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ń tọ pinpin bí ìyídà ṣe máa ń bá ẹ̀da àrun kòrónà láti lè jẹ́ kí wọ́n ní òye kíkún nípa bí àjẹsára ṣe lè bá ẹ̀dà tuntun náà jà.
Covid-19 ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn káàkiri àgbáyé.
Nínú ìlàkalẹ̀ ètò tí a mọ̀ sí ìṣàkíyèsí ìyídà àìsàn, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì máa ń mójú tó bí jẹ̀nẹ́tíìkì àti purotéènì aàrùn náà ṣe ń tàn ká.
Wọ́n máa ń lo àwọn ìròyìn wọ̀nyí láti lè mójú tó àìsàn àti láti fi ṣe ìtọ́nà fún ìdàgbàsókè àjẹsára.
Fún àpẹẹrẹ, nípa mímọ èto ìrú purotéènì aàrùn náà, àwọn olùṣèwádìí lè ṣẹ àwọn àjẹsára tí ó lè fojú sun àwọn purotéènì náà láti lè dẹ́kun aàrùn náà láti wọlé sínú sẹ́ẹ̀lì ara ènìyàn.
Nínú ìwádìí yìí, awọn olùṣèwádìí tọ pinpin bí SARS-CoV-2 ṣe ń lọ ní orílẹ̀-ède Uganda.
Àwọn olùṣèwádìí pinu àwọn ète ìṣàfihàn jẹ̀nẹ́tíìkì aàrùn inú àwọn àpẹẹrẹ tí a gbà sílẹ̀ lára àwọn tí ó ní aàrun COVID-19 káàkiri Uganda.
Wọ́n lo àwọn ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà láti tọ pinpin ẹbí (tàbí ìtàn ìdílé) ti ẹ̀dà tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ dámọ̀ (tí a pè ní A.23.1), wọ́n sì rí ibi tí ẹ̀dà náà wà lára igi ìdílé SARS-CoV-2.
Àwọn èsi wọ́n fi hàn pé ẹ̀da A.23.1 jẹ́ ìyídà ẹ̀dà mìíràn tí í ṣe A.23, tí a rí nínú 90% àwọn àpẹẹrẹ àgbàsílẹ̀ àwọn tí ó ní aàrùn náà.
Ní ọ̀nà ìgbàsọ mìíràn, ó ti jẹ gàba lórí àwọn àpẹẹrẹ àgbàsílẹ àwọn ẹni tí ó ní aàrùn náà ní Uganda láti oṣù Ọ̀wàwà ọdún 2020.
Wọ́n tún ri pé ẹ̀ya A.23.1 náà ní ìyídà lóríṣiríṣi nínú ìrú purotéènì tí ó fara pẹ́ ìyídà tí a máa ń rí nínú àwọn ẹ̀ya irúfẹ́ èyí tí à ń sọ.
Àwọn ìyídà náà lè jẹ́ kí ẹ̀yà náà ní àkóràn (ìtànkálẹ̀ rẹ̀ yára), àti kó sì máa gbógun ti abẹ́rẹ́ àjẹsára àti ìtọ́jú.
Ìwádìí yìí fi kún akitiyan tó ń lọ lọ́wọ́ láti kápá ẹ̀ya SARS-CoV-2 lágbàáyé.
Èsì náà fi kún ẹ̀rí pé SARS-CoV-2 ń dàgbà nínú ìyídà si bí ó ti ń tànkálẹ̀ láti mú àwọn ènìyàn àti láti bọ́ lọ́wọ́ agbára abẹ́rẹ́ àjẹsára.
Ìwádìí gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú láti ní òye ohun tí ìyídà ìrú purotéènì A.23.1 yóò jẹ́.
Àwọn olùṣèwádìí náà gbóríyìn fún ọ̀pọ ìṣàkíyèsí ìyídà àìsàn láti lè fún wa ní òye bí àwọn ẹ̀dà aàrun náà ṣe ń fèsì sí abẹ́rẹ́ àjẹsára tó wà ní Uganda àti àwọn orílè-èdè mìíràn.
Wọ́n sì sọ pé mímú ojú tó ìrìn-àjò onílùú-sí-ìlú ṣe pàtàkì latì lè fún àwọn olùṣèwádìí ní òye bí àrun náà ṣe ń tànkálẹ̀ lábẹ́lé.
Zulu translation of DOI: 10.1101/2021.02.08.21251393
Northern Sotho (Sepedi) translation of DOI: 10.1101/2021.02.08.21251393
Luganda translation of DOI: 10.1101/2021.02.08.21251393
Hausa translation of DOI: 10.1101/2021.02.08.21251393