Description
Lay summary of the article published under the DOI: 10.1101/2020.05.28.121301
This is a Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.05.28.121301
Idi
Ewu ààrùn tó ń kọlu àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ nínú àwọn aláìsàn RA ń lé sí i lábaadì nípa ara wíwú káàkiri gbogbo ara.
Kókó ipa àwọn ìyéròjàpadà àsọmọ́- àkógunjara-Adèènà-Ààrùn lórí ipò àti kókó ìṣe ìmẹ́jèdì amẹ́jẹ̀dì jẹ́ àìmọ̀ síbẹ̀.
Nítorí náà, a ṣe àfiwéra ìwọ̀n iṣẹ́ òpó ẹ̀jẹ̀, ara wíwú, ẹ̀jẹ̀ dídì àti àpapọ̀ ohun tí ṣarajọ di ẹ̀jẹ̀ dídì lára aláìsàn RA pẹ̀lú ti àwọn ẹ̀nìyàn tí àlàáfíà wọn pé, a sì ṣe ìgbéléwọ̀n àjọṣepọ̀ wọn.
Àwọn ọ̀nà àágbegbà.
Àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ jẹ́ gbìgbà lára àwọn aláìsàn RA 30 àti àwọn ẹ̀nìyàn tí àlàáfíà wọ́n pé tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn 25 pẹ̀lú ìṣedéédé nípa ọjọ́ orí àti ẹ̀yà-ìbí.
Àwọn ipele SAA, CRP, ICAM-1 àti VCAM-1 jẹ́ wíwọ̀n pẹ̀lú ìṣàmúlò àyẹ̀wò èròjà amáradàgbà Alálàbò.
Gbogbo ẹ̀jẹ̀ dídì ni a yẹ̀wò pẹ̀lú ìṣàmúlò Ìgbéléwọ̀n-ayẹ̀jẹ̀dídìwò.
Àwọn ìbáṣepọ̀ ìméjẹ̀dì Amẹ́jẹ̀dì àti ipò fáíbà jẹ́ ṣíṣèwádìí pẹ̀lú ẹ̀ro tó ń ya àwòrán kòkòrò.
Ìṣàwárí àti ìgbéléwọ̀n ìyéròjàpadà nínú ẹ̀jẹ̀ dídì jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú lílo ohun-èlò adèènà ààrùn àtọwọ́dá pẹ̀lú ẹ̀rọ̀ awokòròrò ńlá.
Esi.
Àkìyèsí SAA, CRP àti ICAM-1 jẹ́ mímójú tó dunjú lára aláìsàn RA ju ti àwọn tí kò ní i lọ.
Òsùwọ̀n wíwọn TEG tí ó nííṣe pẹ̀lú pípilẹ̀ ẹ̀jẹ̀ dídì (R àti K), iye àwọn Amẹ́jẹ̀dì tí wọ́n ní àsopọ̀ (α-Angle), àti iye àkókò tí ìmẹ́jẹ̀dì ojú òpó ẹ̀jẹ̀ tí ó ga jùlọ fi ń ṣẹlẹ̀ (TMRTG) jẹ́ díndínkù lára àwọn aláìsàn RA.
Òsùwọ̀n tó nííṣe pẹ̀lú bí ẹ̀jẹ̀ tó dì ṣe lágbára tó (MA, MRTG, TGG) kò fi gbogbo ara yàtọ̀ láàrin RA àti àwọn tí kò ní i.
Apata àbá àyẹ̀wò fi ìbáṣepọ̀ tó nípọ̀n hàn láàrin ẹ̀yà èròjà amáradàgbà tó ń bá ara wíwú ṣiṣẹ́ (CRP, SAA) pẹ̀lú Òsùwọ̀n wíwọn TEG ju àwọn iṣẹ́ àwọn okùn to gbé ẹ̀jẹ̀ wọnú ọkàn lọ.
Àbọ̀ àyẹ̀wò ẹ̀rọ awokòkòrò fi hàn pé ìṣe ìdìpọ̀ fáíbà amẹ́jẹ̀dì lára aláìsàn RA sí ti àwọn tí kò ní i [[[[idá méjì (ipò idá mẹ́rin) 214 (170-285) vs 120 (100-144) nm bí wọ́n ṣe tò tẹ̀lé ara wọn, p<0.0001, Odds ratio=22.7).
Ìṣàwárí ọ̀pọ̀ ibi ayéròjàpo láàrin ipò ẹ̀jẹ̀ dídì lára aláìsàn RA léyìí tí kò wọ́pọ̀ nínú àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ àwọn tí kò ní i (p<0.05, OR=2.2).
Ìkádìí.
Aláìsàn RA tó múná máa ń fi irúfẹ́ ara wíwú hàn jáde léyìí tí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn okùnfa ara wíwú yòókù.
Ìkọwọ́bọ ipò èròjà amáradàgbà lójú láti ọ̀dọ̀ Ayéròjàpo tí ó ń bá ìkógunja-adèènà-ààrùn ṣiṣẹ́ lè kó ipa láti sọ ipò amẹ́jẹ̀jì àti kókó ṣíṣàlékún ewu ìmẹ́jèdì lára aláìsàn RA.
Iṣẹ́ ìwádìí tuntun lórí Àìsàn ìkógunjara-Adèènà-Ààrùn tó ń mára wú, ti jẹ́ ká ní òye sí i nípa àwọn ìbáṣepọ̀ tó ṣe kókó nípa ipò yìí àti àlékún ewu ààrùn tó ń kọlu àwọn òpó ẹ̀jẹ̀.
Àìsàn ìkógunjara-Adèènà-Ààrùn tó ń mára wú (RA) jẹ́ àìsàn akógunjara-adèènà-ààrùn adánigúnlẹ̀ tí ó nííṣe pẹ̀lú oríkeríkèé ara híhù káàkiri gbogbo ara.
Lẹ́nu àkókò díẹ̀, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ti rí i mọ̀ pé àwọn tí àìsàn yìí ń bá fínra ní ewu ìdá 50% làti ní ààrùn tó ń kọlu àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ (CVD) àbájáde – bí i àìsàn rọpárọsẹ̀, àìsàn ọkàn.
Kókó kan pàtàkì nínú ewu yìí ni ipa tí ara wíwú ní lórí ìgbésẹ ẹ̀jẹ̀ dídì.
Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, àwọn aṣèwádìí ti ṣèwádìí àjọṣepọ̀ yìí, láti mọ̀ ìdí rẹ̀ pàtó tí RA fi ń ṣàlékún ewu CVD.
Ní pàtàkì, àwọn aṣèwádìí ṣàgbéyẹ̀wò ipa ara wíwú àti àyípadà ipò lórí àwọn èròjà amáradàgbà tí ó nííṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ dídì tí à ń pè ní amẹ́jẹ̀dì.
Àwọn èròjà amáradàgbà wọ̀nyìí ń wáyé bí i asopọ̀ tí ó parapọ̀ di “ojú ẹsẹ̀” fún ẹ̀jẹ̀ dídì, kí àyípàdá yìówù kí ó dé bá àwọn amẹ́jẹ̀dì fúnra wọn lè ní ipa ìtẹ̀síwájú lórí apapọ̀ ìgbésẹ̀ ẹ̀jẹ̀ dídì gbogbo.
Àwọn Aṣèwádìí ṣàfiwéra àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ aláìsàn tí ó ní RA pẹ̀lú ènìyàn tí ìlera rẹ̀ pé.
Ní ọ̀gangan ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan, àwọn Aṣèwádìí ń “afààmìhàn” nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó ṣe àfihàn ara wíwú, bákan náà fún irú àwọn àyípadà tí kò wọ́pọ̀ nínú ìgbésẹ̀ ẹ̀jẹ̀ dídì tí ó lè ṣàlékún ewu CVD.
Ẹ̀jẹ̀ dídì ọ̀hún gan alára jẹ́ yíyẹ̀wò pẹ̀lú ẹ̀rọ awokòkòrò wò, láti ṣèdámọ̀ àwọn àyípadà yìówù sí ipò àwọn èròjà-amáradàgbà amẹ́jẹ̀dì wọn.
Àwọn Aṣèwádìí ṣàkíyèsí pé ẹ̀jẹ̀ dídì lára aláìsàn RA ń tètè ṣarajọ ju ti àwọn ẹ̀nìyàn tí àlàáfíà wọn pé lọ, bákan náà pé àwọ̀n èròjà amáradàgbà tí a fi ṣẹ̀dá, wọn nípọn lọ́pọ̀lọpọ̀ jù amẹ́jẹ̀dì lásán lọ.
Ìyàtọ̀ wà bákan náà lára àwọn àmáínò tí ó papọ̀ di èròjà amáradàgbà amẹ́jẹ̀dì, tí ó mú wọn ta Adèènà-Ààrùn jí léyìí tí ó ń yọrí sí ara wúwú síwájú sí i.
Àwọn Aṣèwádìí mìíràn ti ṣàkíyèsí ìyípadà nínú ipò àmáínò amẹ́jẹ̀dì ní oríkeríke ara àwọn aláìsan RA tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn Aṣèwádìí yóò rí irú ìṣe yìí nínú ẹ̀jẹ̀.
Papọ̀ mọ́ àwọn àyípadà mìíràn tí ó jẹ́ rírí nínú ẹ̀jẹ̀ dídì, ìwádìí náà lè ra àwọn onímọ̀-sáyẹ́ǹsì lọ́wọ́ láti ní òye jinlẹ̀ sí i nípa ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin RA àti CVD, àti bí a ṣe lè ṣàwárí ìṣẹ́yọ ààrun náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ìwádìí àtẹ̀yìnwá yìí wúlò, ó yẹ̀ láti kíyèsí i pé àpẹẹrẹ tí a lò fún iṣẹ́ náà kéré níye púpọ̀.
Àwọn aṣèwádìí náà tún mẹ́nu bà á pé ìlànà tí wọ́n lò láti ṣàwárí ìyípadà àmáínò nínú èròjà amáradàgbà ṣeéṣe kí ó ti mú èsì láti inú òhun mìíràn tí kò jọra wọn, èyí túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ ìwádìí àdáṣe tí yóò fojú sun amẹ́jẹ̀dì yóò nílò láti ṣẹ̀rí èsì àbájáde náà lọ́jọ́ iwájú.
Ní ọjọ́ iwájú, níní òye ìbáṣepọ̀ tó gbópọn láàrìn RA àti àlékún ewu CVD le mú ìdàgbàsókè bá àwọn àbájáde fún àwọn aláìsàn RA gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń kọ́ láti ní òye ìdámọ̀ àti ìtọ́jú àwọn kòkòrò yìí dáadáa.
Àwọn Aṣèwádìí láti orílẹ̀ èdè South Africa, Denmark àti United Kingdom lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, léyìí tí South African Medical Research Council ṣe onígbọ̀wọ́ fún.
This is Amharic translation of DOI: 10.1101/2020.05.28.121301
This is Zulu translation of DOI: 10.1101/2020.05.28.121301
This is Northern Sotho translation of DOI: 10.1101/2020.05.28.121301
This is Hausa translation of DOI: 10.1101/2020.05.28.121301
This is a Luganda translation of DOI: 10.1101/2020.05.28.121301