Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Kò si àṣàyàn oúnjẹ tí ó ṣe ara lóore kò púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n wà ní Yunifásitì Kenyatta.

Yoruba translation of DOI: 10.21203/rs.2.13949/v1

Published onMay 18, 2023
Kò si àṣàyàn oúnjẹ tí ó ṣe ara lóore kò púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n wà ní Yunifásitì Kenyatta.
·

Àgbéyẹ̀wò àṣẹkiri ìlànà-oúnjẹ́-yíyàn àti ipò ìfohúnjẹfáran àwọn ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ fóyè-àkọ́kọ́ tí wọ́n wà ní Yunifásitì Kenyatta ní Kenya

Èròǹgbà:

Èròǹgbà iṣẹ́ ìwadìí yìí ni láti ṣe àfilọ́lẹ̀ ìṣe-oúnjẹ́-yíyàn, ipò ìfohúnjẹfáran tí ó bá irúfẹ́ ara ẹni mu, àti ìbaṣepọ̀ tí ó wà láàárín onírúurú oúnjẹ́-yíyàn àti ipò ìfohúnjẹfáran àwọn ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ fóyè-àkọ́kọ́ tí wọ́n wà ní Yunifásitì Kenyatta ní Kenya.

Àwọn ọ̀nà:

 Iṣẹ́ ìwadìí náà ṣe àmúlò ìlànà ìwádìí aláṣẹkiri láàárín àwọn ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ gboyè-àkọ́kọ́ 422 tí wọ́n ṣàyàn kiri ní Yunifásitì Kenyatta.

Ìlànà tí wọ́n lò láti ní ìmọ̀ nípa ìlànà-oúnjẹ́-yíyàn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ní Ìlànà lílo àtòjọ ìbéèrè jẹ́ lílò fún ìṣe ìlànà oúnjẹ-yíyàn àwọn Akẹ́kọ̀ọ́-bìnrin.

Wọ́n ṣe òdiwọn bí àwọn akẹkọ̀ọ́bìnrin náà tí wúwo sí àti ìwọn gíga wọn láti ṣe òdiwọn ipòfohúnjẹfáran wọn.

Wọ́n ṣe àtúpalẹ̀ àwọn dátà tí wọn rí gbà nípa lílo ìgbéléwọ̀n ajẹmọ ìṣiro fún ẹ̀ka sáyẹ́ńsì àwùjọ (SPSS) ẹ̀dà 22.

Esi:

 Èsì fi hàn pé ìdá 64.0 àwọn akópa ní wọ́n máa ń jẹ́ oríṣìí ìpín oúnjẹ tó dín tàbí jẹ́ 5, nígbà tí ìdá 36 ń jẹ́ oríṣìí ìpín tí kò tó 5 láàárín wákàtí 24.

Ní ti ipò ìfohúnjẹfáran, ìdá méjìdínláàádọ́rin lé mérin (68.4%) nínú àwọn akópa ní wọ́n ní ìwọ̀n ara tí ó gúnrégé, nígbàtí ìdá mẹ́tàlélógún àti mẹ́sàn-án (23.9%) tóbijù bí ó ti yẹ, tí ìdá márùn-ún àti márùnléláàádọ́ta (5.55%) kéré ju bí ó ti yẹ, nígbàtí ìdá méjì lémẹ́ta (2.3%) sì jẹ́ àbéńtè.

Ìlànà onírúurú oúnjẹ́-yíyàn tí ó kéréjùlọ - Obìnrin ni ó so mọ́ ipò ìfohúnjẹfáran ní pàtó (p=0.044).

Ìyàjú:

 Èsì ìwádìí yànnàná ọ̀na oúnjẹ jíjẹ tí kò bá ìlera mu pẹ̀lú ipò ìfohúnjẹfáran láàárín iye àwọn akẹkọ̀ọ́bìnrin tí ó tó.

Àwọn aṣòfin aṣòfin jára mọ́ ìdásì ọ̀rọ̀ tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àtúnṣe ètòoúnjẹ́-yíyàn-jẹ àwọn obìnrin tí wọ́n ṣì wà ní ọdún ìbísi, pàápàá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yunifásítì.


Kò si àṣàyàn oúnjẹ tí ó ṣe ara lóore kò púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n wà ní Yunifásitì Kenyatta.

Kò si àṣàyàn oúnjẹ tí ó ṣe ara lóore kò púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n wà ní Yunifásitì Kenyatta.

Àwọn olùwádìí sọ pé àsàyà oúnjẹ́ tí kò dára àti àì sí àwọn onírúurú oúnjẹ ní o ṣe okùnfà àìlerà àti àrùn àbéńtè tí ó wọ́pọ̀, tí wọ́n ri láàárín àwọn àwọn ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ fóyè-àkọ́kọ́ tí wọ́n wà ní Yunifásitì Kenyatta ní Kenya.

 Àtúnṣe sí ìgbé-ayé àti ìsòṣedibárakú ní ó fàá tí àrùn àbéńtè fi wọ́pọ̀ ní Kenya lápapọ̀, àti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní pàtó, irúfẹ́ oúnjẹ́-yíyàn yìí le è kó ipa lórí ayé wọn títí láíláí.

Ìṣẹ ìwadìí láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fóyè-àkọ́kọ́ ní Nairobi fihàn pé ìdá méjìlélógún lé mẹ́sàn-án (22.9%) àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní wọ́n sanra jù bí ó ti yẹ tí wọ́n sì jẹ́ àbéńtè, nígbàtí ìdá márùn lé márùn-ún (5.5%) kéré ju bí ó ti yẹ.

 Iṣẹ́ ìwadìí ṣe àyẹ̀wò oúnjẹ́ jíjẹ àti ìlera àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Yunifásitì Kenyatta ní pàtó.

Àwọn olùwádìí fẹ́ láti da àwọn àṣàyàn oúnjẹ́ tí ó ń ṣokùnfa àrùn àbéńtè àti àìlerà mọ̀.

 Àwọn olùwádìí ṣe ìwádìí àṣẹkiri láàárín àwọn ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ gboyè-àkọ́kọ́ 422 tí wọ́n ṣàyàn kiri ní Yunifásitì Kenyatta.

Wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá àwọ́n akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́nu wò nípa ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àṣàyàn oúnjẹ́ wọn, àti bí wọ́n ṣe ń jẹun sí.

 Ìwádìí náà fi hàn pé ìdá 64.0 àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ní wọ́n máa ń jẹ́ oríṣìí ìpín oúnjẹ 5, nígbà tí ìdá 36 ń jẹ́ oríṣìí ìpín tí kò tó 5 láàárín wákàtí 24.

Ìpín irúfẹ́ oúnjẹ́ tí àwọn akohpa ṣábà máa ń jẹ jùlọ ni sírílì, èyí tí ìdá mẹjìléláàádọ́rùn-ún (92%) máa ń jẹ àti ewébẹ̀ tí ìdá méjìdínlọ́gọ́rin àti mẹ́rin (78.4%) máa ń jẹ.

Kóró àti èso ni ó kéré jùlọ nínú ohun tí wọ́n máa ń jẹ, èyí tí ó jẹ́ ìdá mejìdílógún àti mẹ́rin (18.4%).

 Ìwádìí fi hàn pé ìdá méjìdínláàádọ́rin lé mérin (68.4%) nínú àwọn akópa ní wọ́n ní ìwọ̀n ara tí ó gúnrégé, nígbàtí ìdá mẹ́tàlélógún àti mẹ́sàn-án (23.9%) tóbijù bí ó ti yẹ, tí ìdá márùn-ún àti márùnléláàádọ́ta (5.55%) kéré ju bí ó ti yẹ, nígbàtí ìdá méjì lémẹ́ta (2.3%) sì jẹ́ àbéńtè.

Àwọn olùwádìí fi múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ (68.4%) ní wọ́n wà ní ìlera pípé.

 Àwọn olùwádìí kò ṣàlàyé ìdí tí ó fi jẹ́ wí pé à obìnrin nìkan ni wọ́n ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.

Wọ́n mẹ́nuba ohunkóhun nípa ipò ọrọ̀-ajé àwùjọ tàbí ìṣòro tí àwọn obìnrin le è dojúkọ, bíi bí rírí tàbí wíwọ́n oúnjẹ́ tí ó ṣarelóore abbl.

Àwon olùwádìí dá àbá pé kí àwọn aṣòfin jára mọ́ àwọn ètò tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìlera oúnjẹ́-yíyàn lati mú ìgbéga bá oúnjẹ́-yíyàn-jẹ àwọn obìnrin tí wọ́n ṣì wà ní ọdún ìbísi, pàápàá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yunifásítì.

 Iṣẹ́ ìwadìí yìí dá àbá pé kí àwọn agbégbè oúnjẹ́ jíjẹ ní àwọn Yunifásíti rí i dájú pé wọ́n pèsè àwọn àṣàyàn oúnjẹ́ lóríṣìíríṣìí tí ó sì rọrùn.

Èyí yóò mú kí ó ṣe é ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti dẹ́kun ríra àwọn oúnjẹ tí kò dára fún ìlera wọn ní ilé oúnjẹ.


Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?