Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ṣèwádìí bí ibà ṣe ń kó àwọn hóró ní pápá mọ́ra láti gbìyànjú fífẹ àṣàyàn ìtọ́jú lójú.

Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.08.31.275867

Published onMay 23, 2023
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ṣèwádìí bí ibà ṣe ń kó àwọn hóró ní pápá mọ́ra láti gbìyànjú fífẹ àṣàyàn ìtọ́jú lójú.
·

Àṣàyẹ̀wo CRISPR-Cas9 tọ́ka sí CENPJ gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò aṣèmúdúró àkójọ àwọn oje aláìlétò tí ò fẹjú lásìkò ìkóràn àfòmọ́ agbébàrìn nínú ẹ̀dọ̀

 Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ láti fi àmì àisàn ibà hàn, àfòmọ́ agbébàrìn kan a máa ṣe ìkóràn hóró-ẹ̀dọ̀ tí yóò sì di ẹgbẹgbẹ̀rún mẹ́rósáìti, lára fífá àwọn ohun-èèlò olùgbàlejò.

A ṣàfihàn pé àwọn oje tí ò fẹú nínú ara olùgbàlejò wọn yóò gba àrà-ọ̀tọ̀ ṣe ìṣùjọ yíká àfòmọ́ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà nínú ẹ̀dọ̀.

Lílo òpó àyẹ̀wò apó ẹ̀yọ́-ìran CRISPR-Cas9, a rí àwọn olùgbàlejò kaitosíkẹ́lẹ́tínì, àgbéká èrònjà inú iṣan, àìtó èròǹjà aṣaralóore àti baiogẹ́nẹ́sísi lípíìdì tí ó ń ṣàkóso ìdàgbàsókè ibà.

Àwọn adarí ìkóràn tuntun yìí, tí Centromere Protein J (CENPJ) wà lára wọn, ṣe atọ́nà wa láti tọpinpin àwọn ọlgangan fún oje tí ò fẹu láti ṣètò ara wọn (MTOCs) ṣe darí lásikò ìkóràn.

Ṣíṣe ẹ̀dínkù CENPJ ní ó jẹ́ kí ìsọdonílé yìí burú sí i, kí ìkóràn sì pọ̀ sí i.

Síwájú sí i, a ṣàfihàn rẹ̀ pé Golgi kò ṣiṣẹ́ èyí tí a máa ń bá pàdé lẹ́gbẹ̀ẹ́ kókó-hóró tí ó ń ṣètò γ-tubulin láti ṣe ìrànwọ́ àwọn oje tí ò fẹjú ní agbègbè àfòmọ́.

Lápapọ̀, a fi hàn pé àfòmọ́ agbébàrìn LS yóò mú Golgi olùgbàlejò ṣiṣẹ́ láti di ìlànà MT èyí tí yóò gbà àwọn ẹ̀yà ara olùgbàlejò wọ PVM, láti ran ìtànká inú ẹ̀dọ̀ lọ́wọ́.

Àwọn àbájáde wa dábàá pé ọ̀pọ̀ aṣèdálẹ́kun ajẹmégbògi ni yóò se ìdálẹ́kun ìkóràn LS.


Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ṣèwádìí bí ibà ṣe ń kó àwọn hóró ní pápá mọ́ra láti gbìyànjú fífẹ àṣàyàn ìtọ́jú lójú.

 Ọ̀pọ̀ àfòmọ́ ni ó ń ṣàmúlò àwọn mùdùnmúdùn àti àwọn èròjà inú àwọn hóró ènìyàn tàbí ẹranko tí ó olùgbàlejò wọn láti lè ṣe ẹ̀dà ara wọn.

Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí àwọn aṣèwádìí tọ́ka sí àwọn ẹ̀yọ́-ìran kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń kópa nínú bí àwọn hóró inú ẹ̀dọ̀ ṣe ń kó ibà, èyí tí ó le yọrí sí àfojúsùn oògùn agbógun ti ibà tuntun lọ́jọ́ iwájú.

 Ibà ti tan kalẹ̀ gan-an àrùn tí ó sì lágbárá láti ṣe ìjàmbá fún ẹ̀mí tí àwọn àfòmọ́ agbébàrìn ń ṣokùnfà rẹ̀ ni, èyí tí ó ń tẹnu ẹ̀fọn tàn ká.

Àwọn àkókó ìbẹ̀rèpẹ̀pẹ̀ yìí dára fún gbígba ìtọ́jú àwọn agbógun ti ibà tórí pé kò tí ì sí àwọn àmì àìsàn kankan ìpínka-àrùn náà kò sì lè tí ì ṣẹ̀lẹ̀.

Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, àwọn aṣèwádìí fẹ́ wá àwọn àyípà tó bá àwọn ẹ̀yọ́-ìran àti èròjà purotéènì nínú hóró ẹ̀dọ̀ tí ìkóràn ti bá tí ó lè ṣe àyípadà bí ìkóràn ṣe ń dàgbà.

 Nípa lílo ẹ̀rọ aṣolóòtú-ẹ̀yọ́-ìran CRISPR-Cas9, àwọn aṣèwádìí ráàyè láti gba gbára lọ́wọ́ tàbí “gbígbá-dànù” àwọn ẹ̀yọ́-ìran kọ̀ọ̀kan láti wo àwọn ìyàtọ̀ tí yóò wà bí àwọn ẹ̀yọ́-ìran bẹ́ẹ̀ kò bá ṣiṣẹ́.

Wọ́n wá kó àwọn àfòmọ́ ibà ran àwọn hóró ẹ̀dọ̀ tí nǹkan òṣe àti àti àwọn “àgbá dànù”.

Ní pàtó, ohun tí ó jẹ wọ́n lógún ni àwọn àyípadà tó dé bá ìsọdodidi àwọn oje tí kò fẹjú.

Àwọn ìhun afarapẹ́túùbù yìí ń kópa nínú, láàrin àwọn ohun mìíràn, bí àwọn mùdùnmúdùn àti àwọn ohun-èèlò ṣe ń gbéra nínú hóró, wọ́n sì máa ṣùgbà yí àwọn kókó-hóró ká.

 Kàkà kí àwọn oje tí ò fẹjú ṣarajọ sí ipa kókó-hóró kí wọ́n máa darí àwọn mùdùnḿdùn àti ohun-èèlò sí ibi tí hóró ti nílò rẹ̀, àwọn oje tí ò fẹjú a máa ṣarajọ sí ipa ibi tí àfòmọ́ ti ń ṣètò mùdùnmúdùn àti ohun-èèlò láti ran àfòmọ́ lọ́wọ́ kí ó lè ṣe ẹ̀dà ara rẹ̀.

Àwọn aṣèwádìí rí i pé nígbà tí àwọn gbá purotéènì tí wọ́n ń pè ní CENPJ dànù, àfòmọ́ náà ṣe àṣeyọrí nínú gbígba àwọn oje tí ò fẹjú yíra rẹ̀ ká, àwọn àfòmọ́ náà sì tóbi síi wọ́n sì ṣe ẹ̀dà ara wọn ní ìlọ́po.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì náà tún rí onírúnrú àwọn ẹ̀yọ́-ìran mìíràn tí ó ní ipa lórí bí ìkóràn àfòmọ́-agbébàrìn ṣe burú tó.

 Àwọn àṣèwádìí ti fi hàn tẹ́lẹ̀ pé àwọn àfòmọ́ yòókù máa ń ṣe àtúntò àwọn oje tí ò fẹjú láti darí àwọn ohun-èèlò inú hóró sọ́dọ̀ ara wọn.

Nínú ìwádìí yìí, àwọn aṣèwádìí rí àrídájú pé àwọn àfòmọ́ agbébàrìn náà lè lo ète yìí láti darí àwọn mùdùnmúdùn àti àwọn ohun-èèlò mìíràn fún ìlò ìdàgbàsókè tara wọn.

Ní ọjọ́-iwájú, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì gbà á lérò láti lo ìlòyé nípa ìbáṣepọ̀ àwọn ẹ̀yọ́-ìran àti àfòmọ́ nínú àwọn hóró láti tóka sí àwọn ìtọ́jú tuntun fún ibà.

Bí ó tilẹ̀ jé pé àwọn aṣèwádìí tọ́ka sí àwọn àyípadà kọ̀ọ̀kan tí ó jọjú nínú àwọn purotéènì hóró inú ẹ̀dọ̀ lásìkò tí ibà bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọra, iṣẹ́ ṣì pọ̀ síwájú sí i láti lóyé bí àfoọmọ́ agbébàrìn ṣe ń mú àyípadà bá ìṣe àti iṣẹ́ hóró kí wọ́n lè mọ àwọn ibi tí wọn yóò dojú ògùn kọ ní pàtó.

 Ibà ṣì ń ṣe okùnfà ikú ogunlọ́gọ̀ ẹgbèrún ènìyàn lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ nínú iye àwọn wọ̀nyí ni ó wà ní Áfíríkà.

Gẹ́gẹ́ bi àjọ tí ó ń rí sí Ètò Ìlere Àgbáyé, ó lé ní ìdá 90 nínú àrùn ibà kárí-ayé tí ó ṣẹlẹ̀ ní 2019 ní ilẹ̀ Áfíríkà, èyí sọ ọ̀ràn náà di pàtàkì tí ó nílò àwọn akitiyan tí ó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́.


Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?