Description
Lay summary of the research article published under the DOI: https://www.preprints.org/manuscript/201806.0106/v1
This is Yoruba translation of DOI: 10.20944/preprints201806.0106.v1
Lóde-òní, àwọn èèyàn ti ń bèèrè fún àwọn epo mìíràn ti owó wọn kò ga jara lọ, tí wọ́n bá àwùjọ rẹ́, tí wọ́n sì tó ní ìwọ̀n iye ohun tí wọ́n nílò.
Orísun agbára-alálòtúnlò tí ó wuyì, tí ó sì ní àfẹ́fẹ́-è̀èmí tí ó pọ̀ ni ẹtanọ́ọ̀lù.
Wọ́n lè ṣe ẹtanọ́ọ̀lù nípa ṣíṣe àkànṣe iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ ẹtanọ́ọ̀lù, àmọ́ fún iṣẹ́ yìí, a gbìyànjú ṣíṣe àdàlú epo dísù, epo tí a fún láti ara ike tí a kò lò mọ́, ẹtanọ́ọ̀lù àti àwọn èròjà amépodáwáṣá CI-0808 tí a rà láti ilé-iṣẹ́ Innospec.
Kókó pàtàkì tí a ṣe fi èròjà amépodáwáṣá kún un ni lati jẹ́ ki àbúdá jíjó epo náà dára sí i pẹ̀lú ó kérẹ́ tán 1-3 nípa bí ó ṣe lè tètè ranná sí.
Ìwọ̀n márùn-ún ni a yàn láti pò wọ́n pọ̀, bí wọ́n ṣe tò tẹ̀léra nìyí, 50:25:25, 60:20:20, 70:15:15, 80:10:10 àti 90:5:5 fún epo tí a fún láti ara ike tí a kò lò mọ́, ẹtanọ́ọ̀lù àti epo dísù. Àmọ́, fún ìwọ̀n ohun tí a pòpọ̀ mọ́ epo, a wo ìdá gbogbo ẹ̀ lódiidi, a sì fi ìdá 0.01 sí epo tí a ṣe àdàlú rẹ̀.
Nínú iṣẹ́ yìí, àdàlú epo dísù, àti àwọn èròjà amépodáwáṣá ni a lo dípò epo.
Èyí ni láti ṣe àyẹ̀wò bí wọ́n ṣe ṣiṣẹ́ sí, àti àwọn àbùdá èèfín afẹ́fẹ́ gáàsì tí ó ń ti inú wọn jáde, nínú éńjíìnì onísìlíńdà kan, tí a gbé sójú kan, tí a sì ń fi omi dín gbígbóná rẹ̀ kù.
Wọ́n fi CI-0808 kún un torí pé wọ́n lérò pé ó lágbára láti dín ìtànká afẹ́fẹ́ gáàsì CO, UHC, NOX, PM kù, kí ó sì fún éńjíìnì lágbára láti ṣiṣẹ́ tó péye.
A ṣe àfiwé àwọn èsì tí a gbà pẹ̀lú ASTM, a sì fi máá̀sì ṣe àlàyé rẹ̀ nípa lílo àwòrán gíráàfù, nọ́ḿbà àti tébù.
Àgbálọgbábọ̀ tí ó jáde ni pé àpòpọ̀ ẹtanọ́ọ̀lù àti WPPO ṣe é lò nínú ẹ́ńjíìnì tí ó jẹ́ ti dísù gẹ́gẹ́ bí epo mìíràn láìyí ohunkóhun padà.
Afẹ́fẹ́ gáàsì tó ń fán jáde dín kù nígbà tí a pa àwọn èròjà amépodáwáṣà pọ̀ mọ́ ọn, ìṣọwọ́ṣịṣẹ́ rẹ̀ náà sì gbé pẹ́ẹ́lí, débi pé ó bá ti epo dísù mu.
Ipá àwọn aṣèwadìí ká ṣíṣe àdínkù fífẹ́ tí epo dísù máa ń fẹ́ afẹ́fẹ́ gáàsì nípa ṣíse àdàlu epo náà mọ́ àwọn èròjà alálòpẹ́.
Àdàlú náà, tí ó ní epo ẹtanọ́ọ̀lù, àti epo tí a ṣẹ̀dá láti ara ike tí a kò lò mọ́ nínú, kì í ṣe èèfín tí ó lè fa àrùn jẹjẹrẹ púpọ̀.Síbẹ̀, ó ṣì ń ṣe iṣẹ̀ tí dísù gan-an alára ń ṣe.Dísù gan-an alára jẹ́ epo tí a ṣẹ̀dá láti ara àwọn èròjà tí wọn kò ṣe e tún lò, àwọn èròjà wọ̀nyí sì ni wọ́n ń ṣe okùnfà gáàsì adóorumúni.
Àwọn ẹ́ńjíìnì tí wọ́n ń lo epo dísù kì í fepo mu to àwọn tó ń lo gáàsì, àmọ́ gáàsì àti kẹ́míkà tí ó ń ti inú wọn jáde léwu púpọ̀, tí wọ́n sì lè fa àìsàn sí ènìyàn lára, wọ́n sì tún lè ṣẹ àkóbá fún àyíká.
Ohun tí ìwádìí yìí dojú kọ ni láti tọpinpin ọ̀nà tí a lè gbà lo àwọn epo alálòpẹ́ mìíràn láti dín ìṣọwọ́tànká epo dísù kù.
Iṣé yìí dábàá lílo epo ẹtanọ́ọ̀lù tí a lè ṣẹ̀dá láti ara àwọn nǹkan àyíká bí igi àti epo ìsebẹ̀, bí a bá pa wọ́n pọ̀ mọ́ epo tí afún láti ara ike ti a ṣe àlòtúnlò rẹ̀.
Láàyè tiwọn, àwọn epo mìíràn yìí kò dára tó epo dísù, a sì nílò láti ṣe àkànṣe ẹ́ńjíìnì láti ṣe àmúlò wọn.Àmọ́ èròńgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni lílò wọn láti dín ìṣọwọ́tànká epo dísù tí ó ti di bárakú kù, kí á sì lo àdàlú epo náà nínú àwọn ẹ́ńjíìnì tí a ṣe fún epo dísù.
Àwọn aṣèwádìí ṣe àdàlú epo dísù tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ mọ́ epo ẹtanọ́ọ̀̀lù, àti epo ti wọ́n fún láti ara ike tí ò wúlò mọ́.
Wọ́n fi kẹ́míkà kan tí a mọ̀ sí ‘cetane improver’, tí kò wọ́n lọ́jà kún un, èyí ni wọ́n fi gbe dídára dísù lẹ́sẹ̀, kí ẹ́ńjíìnì le ṣàmúlò rẹ̀, láìfọ́n àfẹ́fẹ́ gáàsì ká.
Eńjíìnì onísìlíńdà-kan tí ó ń ṣàmúlò epo dísù ni àwọn aṣèwádìí lò nínú láàbù tí wọ́n ti ṣe ayẹ̀wò bí àwọn éńjíìnì náà ṣe ṣiṣẹ́ sí bí wọ́n bá da àdàlú orísìí epo kọ̀ọ̀kan sí i.
Wọ́n tún ṣe àfiwéra ìmọ̀ọ́nṣe rẹ̀ pẹ̀lú dísù nìkan.
Àwọn aṣèwádìí náà se àṣeyọrí nípa pípo ẹtanọ́ọ̀lù mọ́ epo tí wọ́n fún latí ara ike tí ò wúlò mọ́, tí wọ́n sì dà á pọ̀ mọ́ dísù lọ́nà tí ó gbà ṣe àdínkù fịfẹ́ afẹ́fẹ́ gáàsì láìṣàkóbá fún bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́.
Àpapọ̀ 90% dísù: 5% òróró oníke: Ìdá 5% ẹtanọ́ọ̀lù ni ó ní ìtànká tó kéré jùlọ, tí ó sì ṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí dísù gan-an alára.
Wọ́n tún fi hàn pé ṣíṣe àmúlò/àlòpọ̀ àwọn epo mìíràn tí a pòpọ̀ yìí mọ́ epo dísù kò ní kí gáàsì tí ó ń ti inú ẹ́ńjíìnì jáde gbóná si, èyí túmọ̀ sí é kò sí ewu kankan fún ẹ́ńjíìnì.
This is Amharic translation of DOI: 10.20944/preprints201806.0106.v1
This is Northern Sotho translation of DOI: 10.20944/preprints201806.0106.v1
This is Zulu translation of DOI: https://www.preprints.org/manuscript/201806.0106/v1
This is Hausa translation of DOI: 10.20944/preprints201806.0106.v1
This is Luganda translation of DOI: 10.20944/preprints201806.0106.v1