Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1101/2020.01.10.901470
Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.01.10.901470
Ibà Rift Valley jẹ́ àìsàn tí ìkóràn rẹ̀ lè wáyé láàárín ènìyàn àti ẹranko léyi tó jẹ́ pé ó ti gbinlẹ̀ tó si ń súyọ ní àwọn agbègbè mìíràn káàkiri àgbáyé, tó ń mú ẹran àti èyàn.
Àwọn ràkúnmí oníké kan jẹ́ ohun ọrọ̀-ajé tó ṣe pàtàkì ní Áfíríkà fún ìlò fún iṣẹ́, ììn-ajo, àti oúnjẹ.
Ìṣòwò ìgbèriko àti ti ilẹ̀ òkèrè ń jẹ́ kí eru ìkó àrùn náà pọ̀ si, ó ń tàn ká ó sì ń fa jàǹbá fún ọrọ̀-ajé àti ètò ìlera mùtúmùwà ní àwọn agbègbè tí àìsàn náà ti tàn dé.
Pẹ̀lú àwọn ewu yìí, ohun tí a mọ̀ nípa RVF nínú ràkúnmí ní orílẹ̀-ède Nàìjíríà ò tó nǹkan.
A ṣe ìwádìí yìí láti mọ ìdí ìtànkálẹ̀ RVF nínú àwọn ràkúnmí oníké kan ní Nàìjíríà àti láti mọ ewu tó rọ̀ mọ́ àìṣàn náà.
Ìwádìí ti a gbé jáde pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ ráńpẹ́ ní àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ méje ní ìpínlẹ̀ Jigawa àti Katsina.
Sírà tí a gbà lára ràkúnmí náà di yíyẹ̀wò fún ìgbógun-ti-RVFV IgG.
Wọ́n há ìwé ìbéèrè pélébé fún àwọn tí wọ́n ni ràkúnmí láti wo òye, ìwà àti ìṣe wọn.
Àpapọ̀ ìtànkálẹ̀ bí i iye 19.9% (95% CI; 17.07-22.90) ni a rí gbà sílẹ̀.
Fífi ti ọjọ́-orí ṣe, ìtànká tó pọ̀ jù 20.9% (95% CI; 17.00-25.31) jẹ́ èyí tí a rí láti ara àwọn rànkúnmí tí wọ́n ti dàgbà (6-10years), nígbà tí àwọn abo ràkúnmí ní 20.4% (95%CI; 15.71-25.80).
Sule Tankar-kar ni ó ní ìtànkálẹ̀ tó pọ̀ jù pẹ̀lúu 33% (95%CI; 1.31-4.72, p= 0.007) àti OR 2.47 ní ìpínlẹ̀ Jigáwá nígbà tí Mai’adua ni 24.7% (95%CI; 0.97-2.73, p=0.030) pẹ̀lú OR 1.62 ní ìpínlẹ̀ Katsina.
Látara máàpù, àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n wà níbodè pẹ̀lúu Niger Republic wà ewu púpọ̀ sí RVF.
Ìrọ̀ òjò púpọ̀ nìkan ni kò tan mọ́ ìjẹyọ̀ RVF láalárín àwọn ada ràkúnmí (95%CI 0.93-5.20; p=0.070).
Ibà Rift Valley (RVF) lè ṣàkóbá sí ìlera àti ọrọ̀-ajé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n sínmi lé okòwo rakúnmí.
Àwọn olùṣèwádìí tọpa ìtànkálẹ̀ àìsàn yìí ní agbègbè náà, wọ́n sì sọ pé dída àwọn ẹranko náà láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè yóò mú kí àrùn náà máa tàn kálẹ̀ si ni.
Àwọn ràkúnmih oníké kan jẹ́ ohun ọ̀sìn ọrọ̀-ajé pàtàkì ní Áfíríkà tí wọ́n lò fún iṣẹ́, ìrìn-àjò, àti oúnjẹ, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi èèyàn àti àwọn ẹranko mìíràn, wọ́n máa ń tètè ní àkóràn RVF, àrùn ibà ìsun ẹ̀jẹ̀ nínú ara.
Àwọn okòwò ìgbèríko àti ti ilẹ̀ òkèrè tí ó máa ń tan àrun náà ká ti jásí rògbòdìyàn lóríi ọrọ̀-ajé àti ètò ìlera mùtúmùwà lóríi àwọn ràkúnmí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Láburú ni pé, àmójútó fí RVF ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní Áfíríkà wa ní ìwọ̀ǹba, àti pé ìtànkálẹ̀ lè jẹ́ èyí tí àwọn ènìyàn ò ní tètè mọ̀ léyìí tí wọn kì í fọn ìpe rẹ̀ síta.
Kódà, orílẹ̀-ède Nàìjíríà ò tíì gbé ìròyin ibà Valley Fever jáde, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú sẹ́rọ́mù nínú oríṣiríṣi ẹranko ni wọ́n ti rí àrùn náà wọn ò tíì ri lára ràkúnmí; ìwádìí yìí gbèrò láti ṣe àwárí láborí ìtànkálẹ̀ àrun RVF nínú àwọn ràkúnmí oníké kan ní orílẹ̀-ède Nàìjíríà, kí a sì ṣàfihàn àwọn ewu tó wà pẹ̀lú àrùn náà.
Àwọn olùṣèwádìí ṣe ìwádìí ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ méje ní àwọn ìpínlẹ̀ Jigawa àti Katsina.
Wọ́n gba àpẹẹrẹ àgbàálẹ̀ sẹ́rọ́mù lára àwọn ràkúnmí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò lórí wọn fún oògùn apakòkòrò inú ara tó fi ìwa RVF hàn.
Wọ́n ri pé oògùn apakòkòrò inú ara tó ń gbógun ti RVF wà nínú 19.9% àwọn ràkúnmí tó wà ní ìpínlẹ̀ méjì ní ìhà àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Àwọn ìpínlẹ̀ wọ̀nyí wà ní ibode pẹ̀lú orílẹ̀-ède Niger Republic, léyìí tó ṣẹ́ ẹ kéde ìtànkálẹ̀.
Ìwádìí náà fihàn pé àwọn ràkúnmí tó ti dàgbà, láàárín ọdún 6 sí 10, ní ìtànkálẹ̀ tó ga jùlọ, pẹ̀lú 20.9% nípa níní oògùn apakòkòrò inú ara tó ń gbógun ti RVF nínú u àpẹẹrẹ àgbàálẹ̀ sẹ́rọ́mù wọn.
Ìwádìí fi hàn pé àwọn àkúnmí ní Sule Tankar-Kar wà ní 2.47 ìgbà láti kó àrun RVF, pẹ̀lú ìtànkálẹ̀ iye 33%.
Ìwádìí yìí ri pé okùnfa ewu tó lágbára jùlọ ni ìkúnye àdàká àwọn ràkúnmí láti orílẹ̀-ède Nàìjíríà sí àwọn orílẹ́-èdè ayíká rẹ̀ kí wọ́n sì tún da àwọn ràkúnmí náà padà sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà.
Àwọn iye nọ́ḿbà wọ̀nyí dínkù sí ti àwọn eyí tí wọ́n ṣe ni orílẹ̀-èdè mìíràn, níi Niger Republic (47.5%), Mauritania (45%), àti Tanzania (38.5%).
Àwọn olùṣèwádìí náà wí pé kí Nàìjíríà gbèrò àti ṣàgbékalẹ̀ yàrá ìyàsọ́tọ̀-àìsàn ní àwọn ibode wọn kí àwọn ẹranko tí ó ń ti àwọn orílẹ̀-èdè àyíká bọ̀ lè di yíyẹ̀wò fún àìsàn ibode bíi RVF.
Northern Sotho(Sepedi) translation of DOI: 10.1101/2020.01.10.901470
Luganda translation of DOI: 10.1101/2020.01.10.901470
Hausa translation of DOI: 10.1101/2020.01.10.901470
Zulu translations of DOI: 10.1101/2020.01.10.901470