Description
Lay summary of the article published under the DOI: https: 10.1186/s12902-020-0534-5
Yoruba translation of DOI: 10.1186/s12902-020-0534-5
Àìsàn ìtọ-ṣúgà (DM) jẹ́ ìṣòro ètò-ilera àgbááyé tí ó lè tani lóṣì.
Aìsàn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́ jẹ́ gbajúgbajà ìdààmú àwọn òpó kéékèèké inú ara DM tí ó ń mú àlékú bá àárẹ̀ àti àìlera nípasẹ̀ ọgbẹ́-inú àti ẹ̀yà ara gígé.
Lóòótọ́ ìyàtọ̀ tó lápẹẹrẹ wà láàrin àwọn ìwádìí ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ náà lórí DM nípa ìwọ́pọ̀ DPN ní ilẹ̀ Africa.
Fún ìdí èyí, iṣẹ́ ìwádìí náà fojú sun ìṣirò àpapọ̀ ìwọn ìwọ́pọ̀ DPN lára aláìsàn DM ní ilẹ̀ Áfíríkà.
PubMed, Scopus, Google Scholar, African Journals OnLine, WHO African Library, and the Cochrane Review di wíwá lórí ẹ̀rọ lẹ́sẹ-ẹsẹ láti gba àwọn àkọsílẹ̀ tí ó jọ mọ́ ọn.
Ohun-èlò Ìjábọ̀ tí ó yẹ fún Àtúngbéyẹ̀wò Ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé, àti àtúpalẹ̀ tó gbòòrò (PRISMA) jẹ́ títẹ̀lé.
Ìyapa káàkiri inú gbogbo àwọn iṣẹ́ ìwádìí náà jẹ́ wíwọ̀n pẹ̀lu òsùwọ̀n tó ń wọ ṣégeṣège (I2).
Àìṣedéédé àwọn iṣẹ́ ìwádìí jẹ́ yíyẹ̀wò pẹ̀lú ète fọ́nẹ́ẹ̀lì àti ète àyẹ̀wò Egger.
Òpó ipa-aláyìípo kájú ẹ láti ṣe ìṣirò ìwọ́pọ̀ àìsàn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́ láàrin àwọn aláìsàn ní ilẹ̀ Africa.
Ìtúpalẹ̀ tó gbòòrò náà jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú STATA™ ẹ̀yà 14 irin-iṣẹ́ aláìrídìmú.
Ẹ̀tàlélógún iṣẹ́ ìwádìí léyìí tí ó ní 269,691 àwọn akópa jẹ́ fífikún ìtúpalẹ̀ tó gbòòrò náà.
Àpapọ̀ ìwọ̀n ìwọ́pọ̀ àìsàn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́ jẹ́ 46% (95% CI:36.21–55.78%).
Pẹ̀lú àwọn àtúpalẹ̀ ọ̀wọ́lọ́wọ̀ọ́, ìwọ́pọ̀ àìsàn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́ tí ó ga jùlọ lára aláìsàn DM jẹ́ fífi léde ní ìwọ̀ oòrun Áfíríkà pẹ̀lú 49.4% (95% CI: 32.74, 66.06).
Iṣẹ́ ìwádìí náà fi hàn pé àpapọ̀ ìwọ́pọ̀ àìsàn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́ wọ́pọ̀ gan ní ilẹ̀ Áfíríkà.
Fún ìdí èyí, DPN nílò ọ̀nà-àbáyọ̀ àti ète ìdèènà tó bàsẹ̀lẹ̀ wí tí ó dá dúró fún orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan.
Ìwádìí tó gbòòrò nílò síwájú sí i láti dá àwọn okùnfà tí ó súnmọ́ mìíràn mọ̀ lórí ìjẹyọ àìsàn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́.
Ìlọgun tantan okùn-ìtarají bíbàjẹ́ lára àwọn aláìsàn ìtọ-ṣúgà ní ilẹ̀ Áfíríkà pọ̀ púpọ̀ ju ti ibikíbi káàkiri àgbááyé lọ.
Àwọn aṣèwádìí sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfíríkà gbọdọ̀ pèsè ohun èlò, kí wọn ó sì fiyè sí ààrùn adánigúnlẹ̀ yìí.
À̀ìsàn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́ (DPN) jẹ́ ìdágúnlẹ̀, ẹ̀yà-ara kíkú, àti oró léyìí tí okùn-ìtara-jí bíbàjẹ́ látàrí àìsàn ìtọ-ṣúgà (DM), àìsàn tí ó jẹ́ pé ara ènìyàn kò ní lè ṣe òdiwọ̀n ṣúgà inú ara dáadáa.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìwádìí ni ó ti wo ìwọ́pọ̀ ààrùn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́ ṣùgbọ́n àbájáde kọ̀ọ̀kan ní ìyàtọ̀ tó gbòòrò, pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ 8.4% ní China, 48.1% ní Sri Lanka, àti 29.2% ní India, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ.
Ní ilẹ̀ Áfíríkà, àbájáde yìí pẹ̀lú yàtọ̀ púpọ̀, fún àpẹẹrẹ 71.1% ni ó ní ìṣoro okùn-ìtarají bíbàjẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjííríà, 16.6% ní Ghana, àti 29.5% ni Ethiopia.
Ní inú iṣẹ́ ìwádìí yìí, àwọn aṣèwádìí ṣe àtúpalẹ̀ irúfẹ́ ìwádìí yìí ní ilẹ̀ Áfírikà láti ní òye tòótọ́ nípa ìwọ́pọ̀ rẹ̀.
Àwọn aṣèwádìí wo àwọn yàrá ìkàwé orí-ẹ̀rọ PubMed, Scopus, Google Scholar, African Journals OnLine, WHO African Library, àti the Cochrane Review láti wá àwọn àbọ̀ ìwádìí tí ó yẹ.
Iṣẹ́ ìwádìí náà lo Ohun-èlò Ìjábọ̀ tí ó yẹ fún Àtúngbéyẹ̀wò Ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé, àti àtúpalẹ̀ tó gbòòrò (PRISMA) ìtọsẹ̀ láti fi ara balẹ̀ ṣe àfiwéra gbogbo àwọn àbọ̀ ìwádìí náà pẹ̀lú ìṣàmúlò ọgbọ́n ìṣàtúpalẹ̀.
Wọ́n yan 23 iṣẹ́ ìwádìí tó ó ní àpapọ̀ 269 691 akópa.
Àwọn aṣèwádìí lo iṣẹ́ ìwádìí 10 láti orílẹ̀-èdè Nàìjííríà, 4 láti Ethiopia, 2 láti Cameroon, 2 láti Sudan, 2 láti Egypt, àti 1 láti ọ̀kọ̀ọ̀kan orílẹ̀-èdè Ghana, Uganda, àti Tanzania.
Ní àpapọ̀, wọ́n rí i pé ìwọ́pọ̀ ààrùn ìtọ-ṣúgà abokùn-ìtarají-jẹ́ nínú àwọn aláìsàn ìtọ̀-ṣúgà jẹ́ 46% fún gbogbo àpapọ̀ ilẹ̀ Áfíríkà, pẹ̀lú ìwọ́pọ̀ tí ó ga jù tí a bá pàdé ní Ìwọ̀ oorùn Africa gẹ́gẹ́ bi 49.4%.
Ìwádìí yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìtúpalẹ̀ orílẹ̀-èdè kan tí ìdàgbàsókè ti ń bá tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Iran tí ó fi ìwọ́pọ̀ hàn pẹ̀lú 53%.
Yàtọ̀ sí èyí, ìtúpalẹ̀ kan tí wọ́n ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ìdàgbàsókè ti bá fi ìwọ́pọ̀ hàn pẹ̀lú ẹyọ 35.78%, ń dá a lábàá pé kí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìdàgbàsókè ti pèsè àwọn ohun èlò láti ran àwọn alárùn ìtọ-ṣúgà lọ́wọ́ fún ìṣàmójútó ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ wọn láti lè dèènà okùn-ìtarají bíbàjẹ́.
Àwọn Aṣèwádìí gbà pé èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan ni àwọn wò, nítorí náà, wọ́n lè pàdánù àwọn àbọ̀ ìwádìí àwọn aláìsàn ní àwọn èdè mìíràn bí Spanish, French, tàbí Portuguese.
Akùdé iṣẹ́ ìwádìí mìíràn ni pé dátà àwọn ilé-ìwòsàn nìkan ni àwọn aṣèwádìí lò, léyìí tí ó yọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alárùn ìtọ-ṣúgà tí ó wà láàrin ìlú sẹ́yìn.
Ìṣẹ́ ìwádìí náà fi léde pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alárùn ìtọ̀-ṣúgà ní Áfíríkà ni ó ń bá okùn-ìtarají bíbàjẹ́ tí ó bá ààrun ara wọn mu fíra.
Pẹ̀lú àbọ̀ ìwádìí, àwọn aṣèwádìí dá a lábàá pé kí àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà ṣàgbékalẹ̀ ọ̀nà-àbáyọ̀ tó bàsẹ̀lẹ̀ wí àti ètè ìdèènà láti ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn alárùn ìtọ̀-ṣúgà.
Northern Sotho translation of DOI: 10.1186/s12902-020-0534-5
Amharic translation of DOI: 10.1186/s12902-020-0534-5
Hause translation of DOI: 10.1186/s12902-020-0534-5