Description
Lay summary of the research article published under the DOI: http://medrxiv.org/content/10.1101/2020.05.12.20099424v2
This is a Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.05.12.20099424
Jẹjẹrẹ abonú ni ó wọ́pọ̀ jùlọ tí ìṣọwọ́-pani rẹ̀ sì ga jù láàrin àwọn obìnrin kárí-ayé tí iye obìnrin tí ó pa ní ọdún 2019 tó 250,000.
Ó fẹ́rẹ̀ tó ìdá márùndínlọ́gọ́rùn-ún àwọn tí àìsan jẹjẹrẹ abonú ti mú ni ó lọ́wọ́ àìsàn kòkòrò ìbálòpọ̀, nígbà tí ìdá àádọ́rin nínú àwọn wọ̀nyí ni ti ara àpàpọ̀ oríṣìíríṣìí kòkòrò nínú jíìnì ara.
Kíkó HPV máa ń nípa lórí ṣíṣe atọ́nà àwọn sẹ́ẹ̀lì tí jẹjẹrẹ ti mú tí wọ́n wà fún àyẹ̀wò, àyẹ̀wò ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, tí ó sì ṣe pàtàkì.
Níbí, a ṣe ìtupalẹ̀ ní ìpele àwọn ètò tí wọ́n ń se atọ́nà fún àwọn àyípadà, àti àwọn èròjà amáradàgbà tí wọ́n wà níbẹ̀, lárá àwọn aláìsàn jẹjẹrẹ abonú tí wọ́n ní HPV.
A ṣe àmúlò ṣíṣe ìtúpalẹ̀ ipa rẹ̀ láti fi hàn pé àìsàn jẹjẹrẹ tó ní ọwọ́ HPV nínú ní àbùdá àìbalẹ̀ ọkàn lóríṣìíríṣìí, pàápàá jùlọ àwọn tí wọ́n bá ní iṣ e pẹ̀lú ìpín sẹ́ẹ̀lì sí ọ̀nà púpọ̀, àwọn sẹ́ẹ̀lì tí wọ́n bá nípa lórí àwọn sẹ́ẹ̀lì mìíràn, àti àwọn sẹ́ẹ̀lì àjẹsára.
Nípasẹ̀ lílo sààkun tí ẹ̀rọ kọ̀mpútà wò, a ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn aláìsàn jẹjẹrẹ abonú tí wọ́n tún ní HPV, ohun tí kò ní mú àìsàn wọn gbòòrò si ni àwọn ohun bí SOX2, E2F, NANOG, OCT4, and MYC, èyí tí ó ń se àkósọ onírúnrú ìlànà àtúnṣe fún àwọn sẹ́ẹ̀lì àìsàn jẹjẹrẹ àti bí àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ó ń fa ìwúnú ṣ eń pọ̀ sí àti bí wọ́n ṣe ń yara sọ́tọ̀.
Nípa ṣíṣe ìtúpalẹ̀ àọn èròjà amáradàgbà tí ó ń rí sí ìdàgbàsókè àwọn sẹ́ẹ̀lì, a rí àwọn ẹ̀yà ara tí wọ́n ń ṣ eìtanijí fún àwọn sẹ́ẹ̀lì, láàrin àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀, MAPK1, MAPK3 àti MAPK8, àti àwọn èròjà amáradàgbà tí wọ́n nílò ààyè tiwọn, lára wọñ ni CDK1, CDK2 and CDK4, gege bi àwọn ohun tí ó ń gbé èròjà lọ bá mólékù tí ó se kókó, tí wọ́n ń darí ìlànà tí àwọn àìsàn jẹjẹrẹ tí ó ní ọwọ́ HPV nínú.
Lápapọ̀, a tú ojú àwọn ìlànà tó ṣe kókó àti àwọn èròjà amáradàgbà tí ó dára fún jẹjẹrẹ abonú, tí gbogbo rẹ̀ sì fún wa ni àfojúsùn àwọn tí wọ́n nílò ìtọ́jú lọ́jọ́ iwájú.
Àwọn aṣèwádìí ti ya àwọn ẹ̀hun àti àwọn ìlànà kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn wọn lásìkò ìtọ́jú àwọn obìnrin tí wọ́n bá ní àìsàn jẹjẹrẹ abonú tí ó ti ipasẹ̀ kòkòrò papilómà jẹyọ (HPV).
Láti ara dátà àwọn aláìsàn àti àfojúsùn ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà, wọ́n dábàá pé ọ̀pọ̀ èròjà amáradàgbà tí wọ́n ń rísí ìdàgbàsókè àti ìpínsọ́wọ̀ọ́ sẹ́ẹ̀lì ní ìtọ́jú lè dojú kọ lẹ́ẹ̀kanṣo.
Ó fẹ́rẹ̀ tó ìdá 90% àwọn tó ní àrùn jẹjẹrẹ abonú ni wọ́n ti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò tí ì dàgbà wá, ibẹ̀ ni ìṣòro àrun tí ó fì síbìkan ti ga jù.
Òun ni jẹjẹrẹ tí ó burú jù fún àwọn obìnrin, ẹ̀mí obìnrin tí ó ń gbà lọ́dún lé ní 300,000 kárí-ayé.
Ṣaájú iṣẹ́ ìwádìí yìí, àkànṣe iṣẹ́ Cancer Genome Atlas, àti àwọn mìíràn ti tọ ìpa púpọ̀ nínú àwọn àbùdá yìí àti àwọn èròjà amáradàgbà tí wọ́n níiṣe pẹ̀lú àìsàn jẹjẹrẹ abonú.
Ní ìpele mólékù, wọ́n fi han kedere bí abonú ẹni tó ní jẹjẹrẹ ṣe yàtọ̀ sí èyí tí ó dáńgájíá.
Iṣẹ́ yìí yóò tọ́ka sí àwọn òkùnfà ìyàtọ̀ náà ní pàtó, ní kúkúrú èdè, ohun tí ó ń jí àwọn èròjà amáradàgbà àti àbùdá jíìnì tí wọ́n ń ṣokùnfà àìsà jẹjẹrẹ abonú, ohun tí ó le pa wọ́n, ohun tí ó ń gbé wọn sókè, sílẹ̀.
Nípa títọ́ka sí àwọn molékù tí ó ṣe kókó nínú àwọn ètò tí ó ń ṣe atọ́nà fún àwọn jíìnì àti èròjà amáradàgbà wọ̀nyí, àwọn aṣèwádìí lè ṣe òògùn tí yóò dènà gbogbo ipa tí wọ́n ń tọ̀.
Láti fúnka mọ́ àwọn mólékù àti àwọn ipa wọ̀nyí, àwọn aṣèwádìí láti Zambia àti ilẹ̀ South Africa ṣe àfiwéra dátà jíìnì àwọn tí wọ́n ní àìsà jẹjẹrẹ abonú tí wọ́n sì ni kòkòrò papilloma (HPV), àọn tí wọ́n ní jẹjẹrẹ, àmọ́ tí wọn kò ní HPV, àti ti àwọn aláìsàn tí wọn kò ni àìsàn jẹjẹrẹ abonú.
Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rí àrídájú ìyàtọ̀ tó fojú hàn kedere nínú ti àwọn ọ̀wọ́ tí wọ́n ní HPV, wọ́n lo ẹ̀rọ orí kọ̀m̀pútà tí ó lágbárá láti wo sààkun ipa tí ó ń tọ̀, àti àwọn mólékù tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà.
Kókó àbọ̀ ìwádìí ni pé HPV a máà ṣe àkóbá fún àwọn ipa tí sẹ́ẹ̀lì ń tọ̀ dàgbà tí wọ́n sì fi ń pín arawọn sí ọ̀wọ́, àwọn aṣèwádìí wá dábàá pé òògùn tí ó bá dojú kọ àwọn ipa yìí lè wo àìsàn jẹjẹrẹ abonú.
Èyí gbe ìwádìí ìṣègùn tí ó wà tẹ́lẹ̀ lẹ́yìn pé jẹjẹrẹ abonú máá ń gba ìtọ́jú bí ó bá rí àwọn òògùn tí ó le kó àwọn sẹ́ẹ̀lì náà ní pápá mọ́ra.
Ìwádìí yìí tún bojú wo àwọn ipa tí àwọn ẹ̀yà tó ń dáàbò bo ara àti àwọn àjẹsára ń tọ̀.
Àwọn aṣèwádìí náà sọ pé iṣẹ́ ṣì kù lórí wíwá àwọn ìyàtọ̀ ipa tí àwọn mólékù tí ó fà àìsàn jẹjẹrẹ lóríṣìíríṣìí ń tọ̀.
Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ pé ó fẹ́rẹ̀ tó ìdá 95% jẹjẹrẹ abonú ni wọ́n ti ipa kíkó HPV tí ó léwu púpọ̀ wá, èyí fi hàn pé wíwá àṣírí bí àìsàn náà ṣe ń bá àwọn mólékù inú ara ṣiṣẹ́ ṣe pàtàkì sí wíwá ìtọ́jú tó tún dárá sí i fún àwọn obìnrin ilè Áfíríkà àti kárí-ayé.
This is Amharic translation of DOI: 10.1101/2020.05.12.20099424
This is a Zulu translation of DOI: 10.1101/2020.05.12.20099424
This is Northern Sotho translation of DOI: 10.1101/2020.05.12.20099424