Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì dábàá ẹ̀rọ amómigbọ́ná afagbára-oòrùn-ṣiṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú tí ó sì dára

Yoruba translation of DOI: 10.1007/978-3-319-93438-9_1

Published onAug 04, 2023
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì dábàá ẹ̀rọ amómigbọ́ná afagbára-oòrùn-ṣiṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú tí ó sì dára
·

Àwòṣe Thermo-Economic fún Ṣíṣe Ìrànwọ́ fún Yíyan Ohun Ìṣàkójọ àti Olúborí Títóbi fún Ẹ̀rọ Amómigbọ́ná Afagbára-oòrùn-ṣiṣẹ́

 Ìpinnu yíyan irú aṣàkójọ oòrùn tí wọn yóò lò àti nọ́ḿbà iye aṣàkójọ tí wọ́n yàn tí wọn yóò sì padà lò jẹ́ ìpinnu pàtàkì nínú ṣíṣe ètò, èyí tí ó lè kó ipa ńlá nínú bí ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná ṣe lè jọjú sí nínú ètò ọrọ̀-ajé.

Nínú bébà yìí, a ṣe àgbékalẹ̀ àwòṣe thermo-economic kan fún ṣíse àkójọpọ̀ ìwọ̀n tí ó le ṣe ìrànwọ́ fún yíyan ohun ìṣàkójọ tí yóò jẹ́ lílò fún ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná léyì ìgbà tí wọ́n bá ti yan ohun ìṣàkójọ tí ó wù wọ́n.

Ìṣàfiwé òdiwọ̀n aagbára-kan-ní dọ́là tí wọ́n ṣe ìsirò gẹ́gé bi agbára ooru tí ó ń jáde nínú ohu ìṣàkóso kan láàárin ọdún kan, níbi “ọ̀gangan ìgbàmúṣẹ́ṣẹ tí ó rọrùn jù” tí wọ́n fi iye rẹ̀ yípo ọdún kan ṣe ìdá rẹ̀, ni wọ́n dábàá gẹ́gẹ́ bi atọ́nà fún ṣíṣe àfiwé láti mọ iye tí ó dára jù láàrin oríṣìíríṣìí ìṣàkójọ oòrùn.

Láti lè mọ títóbi ọ̀gangan ìgbàmúṣẹ́ṣe tí ó rọrùn jù fún ohun ìṣàkójọ tí wọn yóò lò fún ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná kan, èyí tí wọ́n fi ṣe ìsirò òdiwọ̀n-agbára-kan ní dọ́là, Àpapọ̀ Iye Àkójọ Oòrùn Tí-ó-wà ni wọ́n lò gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn láti gbé e dé òtéńté.

Àwòsè mẹ́wàá (10) ọ̀tọ̀tọ̀tọ̀ tí wọ́n jẹ́ ohun ìṣàkójọ tí ó ń fi agbára oòrùn gbóná (pẹrẹsẹ 5 àti onítúùbù 5) tí àjọ SRCC ṣe òṣùwọn wọn, wọ́n fi òdiwọ̀n-agbára-kan ní dọ́là tò wọ́n sí ipò nípasẹ̀ àwòṣe thermo-economic tí a ṣàpèjúwe nínú ìwádìí.

Ní ọ̀gangan ìgbàmúṣẹ́ṣe tí ó rọrùn jù fún ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná, ìbádọ́gba fọ́lúùmù táǹkì omi gbígbóná àti olúborí ìpín oòrùn ni wọ́n ṣe ipinnu rẹ nígbàkan náà.

Iye fọ́lúùmù omi gbígbóná tí ó wà ní ìpamọ́ dínkù bí ohun ìṣàkójọ tí wọ́n lò ṣe ń kéré sí i nígbà tí ìpín oòrùn rẹ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i, títí tí ó fi tànka ní ìṣọ̀kan.

Fún ìwádìí èyí tí ó jẹ́ pé ìgbóná-gbooru tí wọ́n nílò ni 50 °C tí ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná wà ní ààrin-gbùngbùn Zimbabwe (19° bí ó dorí kọ Gúuụsù àti ìwọ̀n 30° bí ó bá dorí kọ Ìlà Oòrùn), ohun ìṣàkójọ tí a yàn jẹ èyí tí ó pẹrẹsẹ, òun sì ni ó ní máàkì Òdiwọ̀n-agbára-kan-ní dọ́là 26.1 kWh/$.

Olúborí àwòṣe tí wọn ó lò fún títóbi ohun ìṣàkójọ nínú ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná ní ìbúdò ìwádìí ni 18 m2 per m3 fún omi gbígbóná tí wọ́n nílò lójoojúmọ́; pẹ̀lu àkoonú omi gbígbóná 900 l/m3; pẹ̀lú olúborí ìpín oòrùn 91%.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná pẹ̀lụ àṣàyàn ìgbóná-gbooru nìkan ni a fi ọ̀nà ìmúṣẹ́ṣe inú bébà yìí sọrí, ní ọ̀gangna tí a ṣàyàn, a tún lè lò ó fún ìṣàyẹ̀wò ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná mìíràn ní àwọn ibòmìíràn.


Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì dábàá ẹ̀rọ amómigbọ́ná afagbára-oòrùn-ṣiṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú tí ó sì dára jùlọ fún Zimbabwe

Summary Body Text

 Bí Zimbabwe ṣe bá ìpèsè iná mọ̀nàmọ́ná yí, ìjọba ti fi dábàá àkànṣe ẹ̀rọ amómigbọ́ná afagbára-oòrùn-ṣiṣẹ́ láti lè dín ìlò iná mọ̀nàmọ́ná kù.

Ìwádìí náà ṣàwárí/tọkasí ẹ̀rọ amómigbọ́ná afagbára-oòrùn-ṣiṣẹ́ tí ò gani lára, tí ó sì jẹ́ pé òun ló yẹ Zimbabwe jùlọ, nípa ṣíṣe àmúlò àwòse tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn náà lè lò.

 Ìtànṣán oòrùn ni ẹ̀rọ amómigbọ́ná afagbára-oòrùn-ṣiṣẹ́ láti mú omi gbóná kí ó lè ṣe é lò nínú ilé, àti ní Zimbabwe, ẹ̀rọ yìí ṣẹ̀ ń di ìlúmọ̀ọ́nká ni bí orílẹ̀-èdè náà ṣe ń la ìdágbárakù kọjá.

Àmọ́, ó ṣe-é-se kí owó àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí wọ́n, ìrísí àti títóbi oríṣìí kọ̀ọ̀kan àti ilé-iṣẹ́ tí ó ń se wọ́n sì yàtọ̀, agbára wọn láti mú omi gbóná náà sì yàtọ̀.

Àwọn aṣèwádìí náà lo àwòse ajẹmọ́ṣirò láti wá ìwọ̀n páátì alákójọ ẹ̀rọ amómigbóná tí ó lè gba agbára oòrùn tó pọ̀ jù lówó pọ́ọ́kú.

 Láti ṣe àwárí “ọ̀gangan ìgbàmúṣẹ́ṣe tí ó rọrùn jù” yìí, àwọn aṣèwádìí fi òte de iye agbára ooru tí ẹ̀rọ kọ̀ọ̀kan máa gbà láti ara òòrùn fún ọdún kan, wọ́n sì fi iye rẹ̀ ní owó dọ́là gé e láti mọ odìwọn iye dọ́là-agbára-kan.

Ìwádìí náà ṣàmúlò àwòṣe Àpàpọ̀ Iye Agbára-òòrùn ní Ìpamọ́ Lọ́wọ́lọ́wọ́ fún oríṣìí 10 ẹ̀rọ amómigbọ́ná afagbára-oòrùn-ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì fi ìdá dọ́là-agbára-kan tó wọ́n láti àwọn tí ó ga jùlọ dorí àwọn kékeré.

 Àwọn asèwádìí náà tún ṣàmúlò fọ́lúùmù, tàbí iye omi tí ẹ̀rọ kọ̀ọ̀kan lè sọ di gbígbóná láti pinnu lórí òdiwọ̀n iye dọ́là-agbára-kan.

Ìdí èyí ni pé bí ẹ̀rọ tí ó ń gba agbára oòrùn bá ṣe tóbi tó, bẹ́ẹ̀ náà ni omi gbígbóná tí yóò gbà yóò se kéré tó, ìfojúsùn ìwádìí yìí láti wá “ọ̀gangan ìgbàmúṣẹ́ṣetí ó rọrùn jù” láàrin iye omi tí wọ́n gbé kanáàti títóbi ohun ìgbà náà.

 Ìẃadìí yìí dan ẹ̀rọ amómigbóná tí́ wọ́n ń lo agbára oòrùn 10 wò ń ìpele 50 C, èyí tí ó jẹ́ ìwọn ìgbóná-gbooru fún ààrin gbùngbùn Zimbabwe ni ìwọ̀n 19° bí ó dorí kọ Gúuụsù àti ìwọ̀n 30° bí ó bá dorí kọ Ìlà Oòrùn.

Àwọn aṣèwádìí ríi pé ẹrọ afagbára òòrun mómigbóná tí ó dára jù, tí kò sí wọ́n jùlọ ni èyí tí ó pẹlẹbẹ tí ó ní òdiwọ̀n-agbára-kan-ní dọ́là tí ó ga jùlọ àti máàkì 26.1 kiloWaati láàrin wákàti fún òdiwọn dọ́là kan (kWh/$).

Pẹ̀lú àwòṣe ẹrọ afagbára òòrun mómigbóná yìí ní pàtó, àwọn aṣèwádìí ṣe ìṣirò pé ó lè sọ omi lítà 900 di gbígbóná nípa lílo ìdá 91 nínú ìtàṣán oòrùntí ó ń gbà láti ara oòrùn.

Àwọn èsì yìí ni ń sọ nípa ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná ní Zimbabwe, àmọ́ àwọn aṣèwádìí dábàá pé àwọn tí àwọn lò nínú ìwádìí yìí le jẹ́ lílò fún ẹ̀rọ afagbára oòrùn mómigbóná mìíràn níbikíbi.


Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?