Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1371/journal.pone.0230984
Yoruba translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0230984
Àwọn jíìnì atako-oró kòkòrò máa ń sábà nííṣe pẹ̀lú nínípa tó pọ̀ lórí àbùdá ìtàn-ìran oríṣiríṣi ẹ̀fọn.
Àmọ́ ṣá, ẹnu àlàyé kékeré nìkan ló wà lórí ipa ìtako kòkòrò lórí ìgbésẹ̀ ìmùjẹ̀ nínú àwọn ẹ̀fọn.
Níbí, pẹ̀lú ìṣàwárí àwọn agbára ìtakò àwọn kẹ́míkà agbé-ẹ̀mí-dúró afi-DNA-pilẹ̀ lára àwọn kòkòrò agbé-ibà-rìn An.Fúnẹtọ̀sì, a ṣèwádìí bí àwọn jíìnì agbára ìtakò àwọn kẹ́míkà agbé-ẹ̀mí-dúró ṣe lè nípa lórí ouńjẹ ẹjẹ̀.
Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ààyè gba àwọn Anofẹ́líìsì fúnẹtọ̀sì ohun èlò oko ìwádìí F1 àti ti láàbù F8 láti mu ẹ̀jẹ̀ lápá ènìyàn fún ìṣẹ́jú 30, wọn wo ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin àwọn pàrámítà tó ṣe kókó fún ìgbésẹ mímùjẹ̀, tí ó fi mọ́ àsìkò ìdáru, iye àsìkò ìmùjẹ, àṣeyọrí ìmùjẹ̀, ìwọn ẹ̀jẹ̀ tí ó jẹ́ mímu, àti aṣààmì markers of gilutatìónì S-tiransiferase (L119F-GSTe2) àti sáítókíróòmù P450 (CYP6P9a_R)— agbára ́ ìtakò ti àwọn kẹ́míkà agbé-ẹ̀mí-dúró tí kò fì síbìkan.
Kò sí Kankan nínú àwọn ìgbésẹ̀ ẹ̀jẹ̀ mímu yìí tí ó nííṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ L119F-GSTe2.
Ní ìyàtọ̀, fún CYP6P9a_R, àwọn ẹ̀fọn atako homosígíọ̀sì pẹ̀lú ìyàtọ̀ tó lápẹẹrẹ lè mu ẹ̀jẹ̀ ju àwọn ẹ̀fọn agba homosígíọ̀sì lọ (OR = 3.3; CI 95%: 1.4–7.7; P = 0.01).
Ju gbogbo ẹ, iye ẹ̀jẹ̀ tí àwọn ẹ̀fọn CYP6P9a-SS mu kéré sí ti CYP6P9a-RS (P<0.004) àti CYP6P9a-RR ((P<0.006).
Èyí dá a lábàá pé jíìnì CYP6P9a so mọ́ ìkésẹjárí mímu àti ìwọ̀n oúnjẹ ẹ̀jẹ̀ An.Fúnẹtọ̀sì.
Àmọ́ ṣá, kò sí ìjọra tí a rí nínú ìṣesí CYP6P9a àti ti àwọn jíìnì tí ó kórajọ fún ìpèsẹ̀ itọ́ inú èròjà amáradàgbà ní ó ń jẹyọ nínú ouńjẹ ẹ̀jẹ̀.
Iṣẹ́ ìwádìí yìí dábàá pe agbára ́ ìtakò àwọn ti kẹ́míkà agbé-ẹ̀mí-dúró afi- P450-pilẹ̀ ni lè nípa lórí ìgbésẹ̀ ẹ̀jẹ̀ mímu ẹ̀fọn Anofẹ́líìsì fúnẹtọ̀sì tí yóò sì fa níní agbára láti tan kòkòrò ibà.
Àwọn ẹ̀fọn agbébàrìn ti faramọlé sí àwọn kẹ́míkà atakò tí ó yẹ kí ó pa wọ́n (apakòkòrò).
Àwọn onímọ̀ sọ pé ìyípadà ẹ̀jẹ̀-ìran tí ó ń fa “ìtako apakòkòrò” nínu ẹ̀fọń Anopheles funestus, tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè jẹun síi lára ènìyàn.
Àbọ̀ èyí lè ṣàlékún agbára wọn láti lè tan ibà ká.
Àwọn ẹ̀fọn kan ní agbára àti lè tako ìgbẹ̀mí inú apakòkòrò pẹ̀lú ìṣàmúlò kẹ́míkà agbẹ́mìídúró, tí yóò ṣiṣẹ́ lórí àwọn kẹ́míka náà nínú ara wọn.
Irú àwọn ìtakò yìí sí àwọn apakòkòrò ń di fífàsíṣẹ́ pẹ̀lú ìfaramọlé ẹ̀jẹ̀-ìran, ṣùgbọ́n kò sí ohun púpọ̀ tí a mọ̀ nípa àwọn àǹfààní mìíràn tí ẹ̀fọn lè ní nítorí ìfaramọlé ẹ̀jẹ̀-ìran yìí kan náà.
Ní inú iṣẹ́ ìwádìí yìí, àwọn aṣèwádìí fẹ́ wádìí bóyá jíìnì tó wà nídìí agbára ìtako apakòkòrò ti àwọn kẹ́míkà agbé-ẹ̀mí-dúró le mú ìdàgbàsókè bá ìgbésẹ̀ ìmùjẹ wọn.
Wọ́n fẹ́ mọ̀, bí àpẹẹrẹ, bóyá àwọn ẹ̀fọn alátakò yìí lè yára mùjẹ̀ tàbí mùjẹ̀ lọ́pọ̀ síi lásìkò oúnjẹ-jíjẹ wọn.
Àwọn aṣèwádìí náà wo bí àwọn oríṣìí ẹ̀fọn Anofẹ́líìsì fúnẹtọ̀sì méjì ṣe mùjẹ̀ ní apá èèyàn fún ìṣẹ́jú 30.
Wọ́n wọn apá ìgbéṣẹ oúnjẹ ẹ̀jẹ̀, bí ó ṣe pé tó láti mu ẹ̀jẹ̀ àti iye ẹ̀jẹ̀ tí ó fà.
Wọ́n ṣàtúpalẹ̀ ẹ̀jẹ̀-ìran ẹ̀fọn náà láti mọ̀ bóyá ọ̀nà ìgbàmùjẹ̀ ọ̀tọ̀ lè di títọpasẹ̀ dé oríṣìí jíìnì méjì tó yípadà tí ó ń tako apakòkòrò.
È̀sì wọn fi hàn pé ọ̀kan lára àwọn jíìnì ìtakò nípa lórí ọ̀nà ìgbàmùjẹ̀.
Irú àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n ní ìyípadà jíìnì yìí máa ń ní ara fífúyẹ́, wọ́n sì máa ń mu ẹ̀jẹ̀ ju àwọn tí kò ní lọ.
Àmọ́ ṣá, ìyípadà jíìnì yìí kò fẹ́ jọ pé ó yí àsìkò tí wọ́n fi ń mu ẹ̀jẹ̀ padà, kò sì mú àlékún tàbí àyọkúrò bá àwọn èròjà amáradàgbà kan tí ẹ̀fọn ń ṣàmúlò láti mu ẹ̀jẹ̀.
Ìwádìí yìí pèsè àwọn ẹ̀rí pé ìyípadà jíìnì tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtako apakòkòrò tún jẹyọ nínú ẹ̀jẹ̀ ìmáramọlé.
Fún ìdí èyí, àwọn aṣèwádìí ṣàrídárú pé irú jíìnì kan náà pẹ̀lú lè nípa lórí ọ̀nà ìgbàmùjẹ̀ ẹ̀fọn.
Èyí ṣe pàtàkì nítorí pé nígbà tí ẹ̀fọn bá ń mu ẹ̀jẹ̀ ni ó máa ń taari kòkòrò ibà.
Àwọn aṣèwádìí sọ pé àwọn iṣẹ́ ìwádìí ọjọ́ iwádìí, ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, wọ́n gbọdọ̀ wọ bí jíìnì ṣe ń nípa lórí ọ̀nà ìgbàmùjẹ̀, àti bí ó ṣe lè nípa lórí bí ìbálòpọ̀ àwọn ẹ̀fọn àti ìtànká ibà.
Wọ́n tún kìlọ̀ pé púpọ̀ nínú àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe nínú iṣé. ìwádìí wọn ni kò kẹ́sẹ járí tí ó sì le nípa lórí àwọn èsì wọn.
Ó ṣe pàtàkì láti ní òye bí ẹ̀jẹ̀-ìran àwọn ẹ̀fọn ṣe ń yí padà àti àyípadà ìṣesí wọn lára bí a ṣe ń gbìyàjú láti pa wọn, bí lílo apakòkòrò lọ́pọ̀ yanturu àti nígbogbo ìgbà.
Àwọn òǹkọ̀wé iṣẹ́ ìwádìí yìí kalẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Cameroon, níbi tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò púpọ̀ nínú a[wọn ẹ̀fọn tí wọ́n lò fún iṣẹ́ ìwádìí náà.
Zulu translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0230984
Amharic translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0230984
Hausa translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0230984
Luganda translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0230984
Northern Sotho (Sepedi) translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0230984