Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1371/journal.pone.0234585
Yoruba translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0234585
Àìsàn náà láti ara (COVID-19) ti jẹ́ ohun ìkọminú àti ìtànkállẹ̀ àrùn káàkiri àgbáyé bẹ̀rẹ̀ láti ìkéde ti Àjọ tó ń rí si Ọ̀rọ̀ Ìlere Lágbaáyé (WHO) gẹ́gẹ́ bí i àjàkálẹ̀ aàrùn.
Kókó iṣẹ́ ìwádìí yí ni láti wo ète ìdádúró ìmọ̀ àti ìṣe sí àjàkálẹ̀ aàrun COVID-19 láàárín àwọn olùgbé Ethiopia.
Ìwádìí oríṣiríṣi ẹgbẹ́ lórí ayélujára di ṣíṣe láàárín in ọ̀wọ́ àwọn olùgbé Ethiopia nípa lílo àwọn ìkọ̀ọ̀nì tí olùkọ̀wé náà máa ń lò pẹ̀lú àwọn ìkọ̀ọ̀nì tó gbajúmọ̀ bí i Facebook, Telegram, and Imeèì.
Àwọn àpẹẹrẹ ìṣájú jẹ́ èyí tí a ṣe láti ṣe àwárí àwọn olùkópa.
Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a gba èsì àwọn olùkópa 341 láti ọjọ́ 15 sí 22 oṣù Igbe, ọdún 2020.
Àwọn détà tí a gbà jẹ́ èyí tí a yànnàná pẹ̀lú oríṣi STATA 14 àti ìmọ̀ oníye alálàyé láti ṣe àgbálọ-àgbábọ̀ ìmọ àti ìṣe àwọn ará àdúgbò sí àjàkálẹ̀ àrun COVID-19.
Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n kópa jẹ́ ìpín 80.5% léyìí tó ṣe pé ọkùnrin ni wọ́n jẹ́.
Bí i 91.2% àwọn olùkópa ni wọ́n gbẹ́ nípa àjàkálẹ̀ aàrùn COVID-19.
Àti pé, nínú àwọn 341 tó jẹ́ olùkópa 90.0%, 93.8% nínú wọ́n mọ pé àjàkálẹ̀ aàrun COVID-19 jẹ́ èyí tí a lẹ̀ yẹra fún nípa àìsúnmọ́-ara-ẹni láwùjọ àti ìfọwọ́ ẹni lóòrè-kóòrè.
Èyí fi hàn pé ìmọ ìdádúró aàrùn náà tí àwọn olùkópa ní sí COVID-19 nípa àìsúnmọ́-ara-ẹni àti ọwọ́ fífọ̀ lóòrè-kóòrè pọ̀ jọjọ.
Ẁàyí o, nínú olùkópa 341 61% nìkan, 84% nínú wọn ni ó ń lo ète àìsúnmọ́-ara-ẹni láwùjọ àti ọwọ́ fífọ̀ lóòrè-kóòrè sí COVID-19.
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn olùkópa náà ni wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo ara wọn kúrò lọ́wọ́ ọ aàrun COVID-19, àmọ́ idojúko ńlá wà nípa yíyí ìmọ̀ yí sí ìṣe.
Èyí fi hàn pé àlàfó wà láàárí níní ìmọ ìdádúró aàrùn COVID-19 àti mímú ìmọ̀ náà lò láti lè dojúkọ ìtànkálẹ̀ aàrùn COVID-19 láàárín àwọn ènìyàn inú àwùjọ.
Nítorí náà, àwọn àjọ tórọ̀ kàn ní láti gbájú mọ́ ìpolongo àti ẹ̀kọ́ fún àwọn ènìyà inú àwùjọ nípa ìṣàmúlò àwọn ìmọ ìdádúró sí ìṣe.
Ní 2021, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Ethiopia ni ó nímọ̀ bí wọ́n ṣe lè dẹ́kun COVID-19, àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kò fi ìmọ wọn sí ojú ìṣe.
Ní 2021, àwọn olùṣèwádií jẹ́ ka mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Ethiopia ni ó mọ̀ pé àìsúnmọ́-ara-ẹni láwùjọ àti ọwọ́ fifọ̀ ń ṣe ìrànwọ́ láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ SARS-CoV-2, aalrùn tó ṣokùfa àjàkálẹ̀ àrun COVID-19.
Àmọ́ àwọn olùṣèwádìí sọ pé ọ̀pọ̀ ni kò ṣàmúlò àwọn ète wọ̀nyí, nítorí náà wọ́n rọ àwọn adarí ìlú láti gba àwọn ènìyà níyànjú àti máa mú àwọn ohun tí wọ́n mọ̀ wọ̀n yí sí ìṣe.
COVID-19 jẹ́ àrun inú ẹ̀yà ara èémí tí ó ń tàn kálẹ̀ káàkiri àgbáyé tí ó sì ń rin orí ilé iṣé ètò ìlera àti ọrọ̀ ajé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ ń gbèrú bíi Ethiopia mọ́lẹ̀.
Àwọn ìjọbá ń fi ìkéde síta fún àwọn ará ìlú, lára èto ìmójútó ojúẹsẹ̀, láti lè ṣe ìrànwọ́ sí ìdádúró ìtàkálẹ̀ náà nípa fífọ ọwọ́ lóór-kóòrè àti àìsúnmọ́-ara-ẹni àti àwọn ẹlòmíràn.
Ìwádìí náà ṣe àwòfiní àwọn olùgbé ọmọ orílẹ̀-ède Ethiopia láti lè ṣe ìgbéléwọn ohun tí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ète ìdádúró wọ̀nyí, àti bóyá wọ́n ń fi sí ojú ìṣe.
Àwọn olùṣèwádìí náà ṣe ìwé ìb́éèrè lórí ayélujára wọ́n sì pin káàkiri orí ̀àwọn ìkọ̀ọ̀nì.
Wọ́n bi àwọn ènìyàn ní ìbéèrè ajẹmágbègbè, bóyá wọ́n gbọ́ nípa àjàkálẹ̀ aàrun Covid-19 àti àwọn ète ìdádúró rè, àti bóyá wọ́n máa ń fọ ọwọ́ wọn tí wọ́n sì tún máa ń ṣe ìyẹra fún àwọn ẹlòmíràn.
Àwọn ènìyan 341 ni ó kópa nínú ìbéèrè alátẹ̀jíṣé orí ẹ̀rọ ayélujára náà, èyí tó jẹ́ pé ìdá 80% wọ́n jẹ́ ọkùnrin.
Àwọn olùṣèwádìí náà sọ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn olùkópa jẹ́ àwọn ẹni tó ń gbé ní ìgboro tí wọ́n sì kàwé, wọ́n mọ ohun tí èt ìdékun àrún bí i àìsúnmọ́ ara ẹní, àìfọwọ́-kan-ojú àti lílọ́ mọ́ ara ẹni jẹ́, láti lè ṣe ìdádúró fú àìsàn náà.
Ní láborí, ìdá bí i 90% mọ bí a ṣe lè ṣe ìdádúró fún ìtànkálẹ̀ Covid-19, àmọ́ bí I ìdá 61% nìkan ni ó ń ṣàmúlò ète àìsúnmọ́-ara-ẹni, àti ìdá 84% wí pé àwọn máa ń fọ ọwọ́ àwọn lóòrè-kóòrè.
Pẹ̀lú ìwádìí yìí, Ethiopia ti wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wo bí àwọn ọmọ ilú wọ́n ṣe mọ̀ nípa àwọn ète ìdádúró aàrun Covid-19.
Àmọ́ àwọn olùṣèwádìí sọ pé àwọn kò rí iṣẹ́ ìwádìí mìírá̀n lórí bí ìmọ̀ nípa ète ìdádúró ìtànkálẹ̀ àrùn nahà se ń di múmúlò ní ìṣe.
Àti pé, wọ́n ní, iṣẹ́ àwọn fi hàn pé ìkéde àti ìmọ̀ kò túmọ̀ sí àyípadà ìṣe.
Àwọn olùṣèwádìí náà sọ pé èsì iṣé àwọn kìí ṣe ìṣàfihàn gbogbo iye àwọn tí ń bẹ ní orílẹ̀-èdè náà níwọ̀n ìgbà tí ìwé ìbéèrè àwọn jẹ́ èyí tí àwọn tí wọ́n lè lo ẹ̀rọ̀ ayélujárà àti àwọn tí wọ́n wá̀ ní orí orisiríṣi ìkọ̀ọ̀ní lè rí.
Wọ́n ní kí àwọn adarí ṣe ju kíkéde nípa àwọn ète ìdádúró fún àisàn Covid-19, kí wọ́n wá ọnà láti ri pé àwọn ará ìlú ń fi ohun tí wọ́n mọ sí ìṣe.
Gbobo àwọn olùṣèwádìí tí wọ́n ṣiṣẹ́ ìwádìí yìí wá láti àwọn ilé-ìwé gíga ní orílẹ̀-ède Ethiopia, àti pé gbogbo àwọn olùkópa náà jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ethiopia.
Amharic translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0234585
Hausa translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0234585
Luganda translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0234585
Northern Sotho translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0234585
Zulu translation of DOI: 10.1371/journal.pone.0234585