Description
Summary of the research article published under the DOI: 10.1101/2020.04.21.20074435
Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.04.21.20074435v1#p-5
Àjàkálẹ̀ àrun Kòrónà tuntun (COVID-19) tí àìsàn àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà ajẹ́mọ-èémí 2 (SARS-CoV-2), jẹ jáde láti ìlú Wuhan, China ní oṣù Ọpẹ́ 2019.
Àmọ́ ṣá, ó pé kí àrùn náà farahàn ní kọ́ńtínẹ́ẹ̀tì Áfíríkà, ó ti hàn káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà níbẹ̀.
A pèse ọwọ́jà ati àkókò-ìtànkálẹ̀ ti COVID-19 láàárín ọjọ́ 62 àkọ́kọ́ tí àrùn náà fojú hàn ní kọ́ńtínẹ́ẹ̀tì Áfíríkà.
A lo módẹ́ẹ̀lì gbèdéke onípele-méjì Poisson láti ṣàtiúpalẹ̀ ìka òdo àti ìlemọ́ ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀.
A ṣe ìwádìí ipa lórí pàtàki àwọn ohun èlo ètò ìlera tí ibùsun ilé ìwòsán àti iye àwọn dókítà wà lára rẹ̀ ní oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè.
Àwọn èsì ìwádìí fi hàn pé ipa àjàkálẹ̀ àrùn náà yàtọọ láti ibìkan sí òmíràn káàkiri ilẹ̀ Áfíríkà pẹ̀lú ọ̀pọ ìṣẹ̀lẹ̀ tó hànde ní àwọn orílẹ̀-ède agbègbe Ìwọ̀-Oòrùn àti Àríwá Áfíríkà.
Ìdi àrùn náà (per 100,000) jẹ́ èyí tó nípa jùlọ ní Djibouti Tunisia, Morocco àti Algeria.
Fúgbà díẹ̀, fún ọ̀sẹ̀ 4 àkọ́kọ́, ìdì náà pọ̀ ní Senegal, Egypt àti Mauritania, ṣùgbọ́n láti àárín oṣù Igbe ó sún sí Somalia, Chad, Guinea, Tanzania, Gabon, Sudan, àti Zimbabwe.
Lọ́wọ́lọ́wọ́, Namibia, Angola, South Sudan, Burundi àti Uganda ní ìdì tó kéré jù.
Àwọn àwárí náà lè wúlò ní ṣíṣe ìdásí lọ́rí ìlànà fifálẹ̀mọ́ àjàkálẹ̀-àrùn àti ìpínká ohun èlò tó mẹ́he ní ìbámu pẹ̀lú ìṣonírúurú bátánì àrùn náà.
Àwọn aṣèwádìí lo módẹ́ẹ̀li ìṣirò láti ṣírò ibi tí ìkóràn COVID-19 ti gbinlẹ̀ jùlọ ní Áfíríkà, àti bí àrùn náà ṣe ń tàn kálẹ̀ lóríṣiríṣi ibi ní kọ́ńtínẹ́ẹ̀tì náà.
Wọ́n ri pé Ìwọ̀-Oòrùn àti Àríwá Áfíríkà ni ó palára jùlọ, nígbà tí àrùn náà yára tànkálẹ̀ jùlọ ní Àríwá Áfíríkà àti bó ti lọ káàkiri àárín àti gúùsù Áfíríkà.
Wọ́n ri pé ìgbégilé ìrìn-àjò kópa tó ṣe pàtàkì ní ṣíṣèdínwọ́ ìtànká COVID-19 àti ní ṣíṣèmúlò ohun èlo èto ìlera tí ò pọ̀ lọ́nà tó dára jùlọ.
Àrun tuntun kòrónà (COVID-19) yìí, tí àìsàn àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà ajẹ́mọ-èémí (SARS-CoV-2) ṣokùnfà jẹ jáde láti ìlú Wuhan, China ní oṣù Ọpẹ́ 2019, ó sì pé kó tó tàn dé ilẹ̀ Áfíríkà ṣùgbọ́n ó yára láti tàn káàkiri gbogbo orílẹ̀-ède kọ́ńtínẹ́ẹ̀tì náà.
Àwọn aṣèwádìí náà jáde láti ní ìmọ̀ tó yarantí lórí i bí iye àwọn dókítà àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìlera mìíràn ṣe ń kópa lórí i ibi àti bí àrùn COVID-19 ṣe ń jẹ jáde ní kíákíá.
Àbájáde náà lè ran ìjọba lọ́wọ́ láti ṣe ìpín ohun èlò ìlera tí kò tó sí àwọn ibi tọ́ ti nílò wọn jùlọ.
Láti ní òye bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀, àwọn aṣèwádìí ti lo módẹ́ẹ̀lì ìṣirò Poisson láti ṣírò ìgbà àti ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìkóràn COVID-19 ti ṣẹlẹ̀ ní Áfíríkà ju ọjọ́ 62 lọ, láti 14th Èrèlé 2020 sí 15th Igbe 2020.
Wọ́n lo data tí Ilé Iṣẹ́ Ìlera Agbáyé fi síta, fún orílẹ̀-ède 47.
Àbájáde èsì náà fi hàn pé Senegal, Egypt, àti Mauritania ni ó kọ́kọ́ ní ìpalára látara ìkóràn láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin.
Wọ́n ri pé Djibouti, Tunisia, Morocco, àti Algeria, ni àwọn orílẹ̀-ède tí ìkóràn náà ti pọ̀jù pẹ̀lú 100 000 ènìyàn tó ṣẹlẹ̀ ní bíi ọjọ́ 62.
Ìlàna ìṣirò náà túmọ̀ sí pé àwọn aṣèwádìí ní láti ṣe ìyapa àwọn àsìkò ìwádìí sí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà ọgbọọgba.
Ìwádìí náà ní ìdíwọ́ pẹ̀lú àìtó data ní ọ̀sẹ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́ nítorí náà àwọn aṣèwádìí náà wo ọ̀sẹ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀sẹ̀ kan, wọ́n sì ṣe ọ̀sẹ̀ olóṣù-gbọọrọ yìí sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀sẹ̀ tó kù.
Ìwádìí yìí fi hàn pé àwọn arìnrìnàjò láti òkè òkun wá sí kọ́ńtínẹ́ẹ̀tì ló wà nídi ìkówọlé COVID-19 àkọ́kọ́, àti pé ìṣàkóso ibodè àti àìsí ìgbégilé ìrìn-àjò ní kọ́ńtínẹ́ẹ̀tì náà ló fa ìtànkálẹ̀ ìkóràn náà si.
Amharic translation of 'The spatio-temporal epidemic dynamics of COVID-19 outbreak in Africa' - DOI: 10.21428/3b2160cd.c693b0f0
Hausa summary translation of DOI: 10.1101/2020.04.21.20074435
Northern Sotho translation of DOI: 10.1101/2020.04.21.20074435)
Luganda translation summary of DOI: 10.1101/2020.04.21.20074435
Zulu translation summary of: The spatio-temporal epidemic dynamics of COVID-19 outbreak in AfricaEzra Gayawan, Olawale Awe, Bamidele M Oseni, Ikemefuna C. Uzochukwu, Adeshindola Samuel, Damon P Eisen, Oyelola A AdegboyemedRxiv 2020.04.21.20074435; doi: