Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1007/978-3-319-76222-7_5
Yoruba translation of DOI: 10.1007/978-3-319-76222-7_5
Ipa tí ó lápẹẹrẹ ni àwọn obìnrin ń kó nínú pípèsè ohun-ọ̀gbìn àti ìdáàbòò oúnjẹ jíjẹ nínú ilé.
Àmọ́ ṣá, ìkópa àwọn obìnrin nínú ìsedánwò àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n pèsè fún ohun-ọ̀gbìn nínú-oko kéré.
Nínú ìwádìí yìí, a lo àtòjọ-ìbéèrè tó ní ètò láti gba dátà, wọ́n fún àwọn àgbẹ̀ obìnrin 80 nínú ìṣedánwò àgbàdo tí ó lè fara da ọ̀gbẹlẹ (DT)̀ ní ilẹ̀ Pápá Southern Guinea (SGS) Ajẹmọ́-ohun-ọ̀gbìn ojú ọjọ́ Ẹkùn ti Nigeria.
Ìwádìí náà fi hàn pé gbogbbo àwọn àgbẹ̀ obìnrin náà ni wọ́n ti lọ́kọ, bíi 23% wọn ni wọn kò lọ ilé-ìwé rárá, tí ìgbèdéke ọjọ́-orí wọn sì tó ẹni ọdún 43.
Ní gbogbo àwọn ìbùdó ni àwọn àgbẹ̀ obìnrin ti gbé ẹ̀yà àgbàdo DT sí ipò tí ó dára jùlọ.
Fún ìdí èyí a gbà á níyànjú pé kí àwọn àgbẹ̀ obìnrin máa kópa nínu ṣíṣe ìgbéǹde àti ìdánwo ráńpẹ́ fún àwọn òye tuntun lẹ́nu iṣẹ́ ohun ọ̀gbìn láti rí dájú pé ààbò wà fún oúnjẹ kí wọn ó sì ní ìdàgbàsókè ọlọ́jọ́ pípẹ́ nípasẹ̀ ìpèsè ìrànwọ́ fún iṣẹ́ ohun ọ̀gbìn.
Àwọn àgbẹ̀ obìnrin láti Nàìjíríà, tí wọn kì í pè sí ibi ìṣèpinnu ohun ọ̀gbìn, ni wọ́n kópa nínú ìṣedánwò nínú-oko láti wo sààkun èwo nínú ẹ̀yà àgbàdo afada-ọ̀gbẹlẹ̀ (DT) tí ó tẹ́ wọn lọ́rùn jù, tí ó sì lérè nínú jùlọ.
Àwọn àgbẹ̀ aládàá kẹ́kéré ni wọ́n ń pèsè 70% àwọn ìrúgbìn ní Nàìjíríà.
Àwọn àgbẹ̀ obìnrin, tí wọ́n jẹ́ 50% ọ̀wọ́ yìí, ni wọ́n kì í sáábà kówó lé lórí, wọn kì í sì í kópa nínú ṣíṣe ìpinnu tí ó jẹmọ́ ìgbéǹde ohun ọ̀gbìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń kó ipa pàtàkì láti rí dájú pé ìdáàbòbò wà fún oúnjẹ fún agbègbè.
Àwọn àgbẹ̀ obìnrin lè kórè irúgbìn tí ó tún pọ̀ sí bí wọ́n bá ń gbin àgbàdo afada-ọ̀gbẹlẹ̀ (DT), níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àgbàdo DT lè hù lásìkò ọ̀gbẹlẹ̀ tàbí lásìkò tí ilẹ̀ bá gbẹ háúháú.
Àwọn aṣèwádìí wá fẹ́ ṣèpinnu lórí ẹ̀yà DT tí àwọn àgbẹ̀ obìnrin fẹ́ràn jù, nípa jíjẹ́ kí wọ́n kópa nínú ìṣedánwò nínú-oko láti yan àgbàdo DT.
Ọ̀wọ́ àwọn àgbẹ̀ obìnrin, láti abúlé 7 ní ẹkùn Ohun ọ̀gbìn Ajẹmójú-ọjọ́ Southern Guinea ti Nàìjíríà, ni wọ́n fún ní ilẹ̀ péréte láti gbin ẹ̀yà DT 2 àti ẹ̀yà oko gidi 1.
Ní àkópọ̀, àwọn obìnrin àgbẹ̀ 80 ni wọ́n kópa.
Àwọn aṣèwádìí náà ṣe àbẹ̀wò sí orí ilẹ̀ péréte yìí nígbà tí irúgbìn náà ṣì ń hù, àti ńgbà tí wọ́n ti yọ òdòdó kí wọ́n lè ṣe àyẹ̀wò èsò irúgbìn náà.
Àwọn aṣèwádìí gba àalàyé tí ó jẹmọ́ ọjọ́-orí, ipò ìgbéyàwó, àti ìpele ìmọ̀ mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà àwọn àgbẹ̀ nípa lílo àtòjọ ìbéèrè, wọ́n sì wo ìṣúná oko àti àwọn èrè.
Àwọn àgbẹ̀ obìnrin, tí ó jẹ́ pé gbogbo wọ́n ni wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó tí wọ́n sì to ẹni ọdún 43, fẹ́ràn ẹ̀yà àgbàdo DT ju àwọn ẹ̀yà àgbàdo lásán lọ.
Onírúnrú ẹ̀yà DT ni wọ́n fẹ́ràn láti agbègbè kan dé òmiràn ṣá.
Àwọn àgbẹ̀ obìrin náà tún rí pé àwọn ẹ̀yà DT náà túnbọ̀ lérè lórí.
Àwọn aṣèwádìí àti àwọn àgbẹ̀ mọ̀ pé wọ́n nílò àgbàdo DT láti ran ìdáàbò bo oúnjẹ lọ́wọ́, a sì mọ̀ pé àwọn obìnrin ń kó ipa tó lápeẹẹrẹ nínú ìpèsè ohun ọ̀gbìn àti ìdáàbò bo oúnjẹ ní ọ̀dẹ̀dẹ̀.
Ìwádìí yìí so àwọn èrò méjèèjì yí pọ̀ nípa jíjẹ́ kí àwọn òbìnrin kópa nínú ìdánwò ránpẹ́ fún àwọn ẹ̀yà DT lásìkò ìṣedánwò nínú oko.
Àwọn aṣèwádìí sọ pé ó yẹ kí àwọn ìlànà-ìmúṣẹ́ṣe àti àwọn ètò tí yóò jẹ́ kí àwọn obìnrin kópa nínú ìgbéǹde àti ìdánwò ráńpẹ́ fún ohun-ọ̀gbìn wà; àmọ́ ṣá, ó kù sọ́wọ́ ìjọba láti ríi dájú pé èyí wáyé.
Àgbàdo ni ohun ọ̀gbìn oúnjẹ tí wọ́n ń gbìn jùlọ tí ó sì ṣe pàtàkì jùlọ ní apá gúúsù-Sahara ilẹ̀ Áfíríkà.
Àyípadà ojú-ọjọ́ ń dúnkookò mọ́ ààbò oúnjẹ, fún ìdí èyí, gbígbé àgbàdo DT dìde ṣe pàtàkì láti tọ́jú ìpèsè oúnjẹ tó lérè nínú.
Nàìjíríà ni gbogbo àwọn aṣèwádìí tí wọ́n kópa nínú ìwádìí yìí fi se ìbudó, ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríyà ni gbogbo àwọn àgbẹ̀ obìnrin tí wọ́n jẹ́ akópa náà.
Amharic translation of DOI: 10.1007/978-3-319-76222-7_5
Hausa translation of DOI: 10.1007/978-3-319-76222-7_5
Luganda translation of DOI: 10.1007/978-3-319-76222-7_5
Northern Sotho translation of DOI: 10.1007/978-3-319-76222-7_5
Zulu translation of DOI: 10.1007/978-3-319-76222-7_5