Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Ó ṣe é ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Kenya ti ní COVID-19 láìmọ̀ ní 2021.

Yoruba translation of DOI: 10.1101/2021.02.05.21250735

Published onAug 12, 2023
Ó ṣe é ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Kenya ti ní COVID-19 láìmọ̀ ní 2021.
·

Ṣíṣe àyẹ̀wò-ẹ̀jẹ̀ fún IgG sí SARS-CoV-2 ní ilé-ìtójú àwọn aláboyún ní ilé ìwòsàn méjì tó wà ni orílẹ̀-èdè Kenya

Àpọ̀jù ìkóràn SARS-CoV-2 tí okùnfà rẹ̀ kò tí ì di mímọ̀ jẹ́ ohun ìdíwọ́ fún títako ìlọsíwájú àjàkáyé aàrùn àti kíká apá rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Kẹnya.

A ṣe àwárí ìtànkálè IgG sí SARS-CoV-2 nínú èyí tókù nínú èjẹ̀ tí a gbà fún àyèwò láti ara àwọn ìyá tí wọ́n ń wá sí ilé-ìtọ́jú aláboyún ní ilé ìwòsàn 2 lórílẹ̀-èdè Kenya.

A lo IgG ELISA tí wọ́n fi òǹtẹ̀ lù fún SARS-CoV-2 ìwásókè purotéènì àti àtúnṣe sí èsì ìtúpalè àti pàtó nǹkan.

Ní ọṣù Ògún ọdun 2020, ònkà àìsàn aṣàfihàn nínú èjẹ̀ jẹ́ 49.9% ní ilé-ìwòsàn gbogbogbò ti Kenyatta, Nàíróbì (95% CI 42.7-58.0).

Ní oṣù Belu, ọdun 2020, òǹkà àìsàn aṣàfihàn gbéra láti 1.3% (95% CI 0.04-4.7) SÍ 11.0% (95% CI 6.2-16.7) ní ọsu kankànlá ní ilé-ìwòsàn Kilifi County.

Àwọn ọ̀nà àìfọkànsí ni ìkóràn SARS-CoV-2 fi ń peléke sí i ní àpá orílẹ̀-èdè Nairobi àti Kilifi.


Ó ṣe é ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Kenya ti ní COVID-19 láìmọ̀ ní 2021.

Àwọn aṣèwádìí jábọ̀ ní ọdún 2021 pé àwọn ẹ̀jẹ̀ aláboyún tí wọ́n gbà fún àyèwò ní Kenya ṣe àfihàn pé sójà ara láti kojú àwọn kòkòrò tí ó ń fa COVID-19.

Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ti fi Ìgbà kan kó aàrùn yìí rí, tàbí wọ́ kó o ní ìgbà náà, àmọ́ èsì àyèwò ẹnsàìmu (PCR) kò tí ì ṣe àwárí ọ̀pọ̀ àwọn ìkóràn yìí.

Àwọn aṣèwádìí ṣọ pé ó ṣe é ṣe kí Kenya má kọbi ara sí ìtànkálẹ̀ COVID-19 ní ìgbà náà.

Ní àpapọ̀, ìjọba nílò láti ní ìmọ̀ nípa iye àwọn ènìyàn tí ó ṣe é ṣe kí wọ́n ní aàrùn yìí ní pàtó láti lè wá ọ̀nà àti kápá àti ìtọ́jú tó yẹ.

Ní orílẹ̀-èdè Kenya, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò lọ fún àyèwò COVID-19 sí bẹ̀.

Èyí lè rí bẹ́ẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyan ni wọ́n kéré, ati wí pé ọ̀pọ̀ kò ní àmì àìsàn rárá tàbí kí àmì àìsàn náà má le.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì sọ pe ṣíṣe òdiwọ̀n ìtànkálè sójà ara sí SARS-CoV-2 jẹ́ ọ̀nà kan láti dẹ́kun ìkóràn pátápátá.

Sójà ara jẹ́ àwọn proteẹni kọọkan nínú ara tí ó má ń ṣiṣé fún aàrun kan pàtó, àti pé ohun tí ó ṣokùnfà wíwà nínú èjẹ̀ ni tí ìkóràn bá ti wà tẹ́lẹ̀ tàbí ìṣílẹ̀ sí ewu.

Nínú ìwádìí ìjìnlẹ̀ yìí, àwọn asèwádìí ṣe àkíyèsi ìtànkálẹ̀ àwọn sójà ara SARS-CoV-2 nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn aláboyún ní ilé-ìwòsàn 2 ní Nairobi àti Kilifi ní orílẹ̀-èdè Kenya.

Wọ́n ṣẹ àyẹ̀wò fún SARS-CoV-2 sójà ara nínú sámpùlù ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára àwọn obìnrin náà.

Wọ́n ṣe àfiwéra àwọn sáḿpùlù tó ní sójà ara pẹ̀lú iye PCR- tí wọ́n mọ̀ àti ìkóràn SARS-CoV-2 tí wọ́n gbà lọ́wọ́ Mínísítà ètò ìlera fún agbègbè kan náà.

Àwọn aṣèwádìí ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ ètò ìlera àti àkọsílẹ̀ tí wọ́n bá gba sáḿpúlù pẹ̀lú ọjọ́ orí, ibùgbé, oṣù mẹ́ta-mẹ́ta tí oyún wà, wíwà tàbí àìsí àmì aàrùn COVID-19.

Wọ́n ṣe àwárí pé ìdajì nínú àwọn sáḿpùlù tí wọ́n gbà ní Nairobi ní o ní sójà ara fún SARS-CoV-2, ti Kilifi sì ní láàárín 1.3% sí 10%.

PCR- sọ ọ́ di mímọ̀ pé ìkóràn ní àwọn agbègbè kò jú 1%, èyí túmọ̀ sí pé àbọ̀ lórí iye ìkóràn kò tó.

Wọ́n tún ṣe àwárí pé 7% àwọn obìnrin ní wọ́n jábọ̀ àmì àìsàn tó jọmọ́ COVID-19, èyí túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ àwọn ìkóràn jẹ́ àìsàn aláìlámì.

Àwọn asèwádìí dábàá pé ó dára kí wọ́n ṣe àyèwò sójà ara SARS-CoV-2 láti ṣe ìdiwọ̀ iye àwọn tó ní ìkóràn ní Kenya.

Wọ́n máa ń kìlọ̀ pé data àwọn aláìsàn aláìlórúko ni wọ́n lò, fún ìdí èyí wón kò le ṣe àfiwéra pẹ̀lú orísun mìíràn láti kín ìwádìí wọn lẹ́yìn.

Àwọn aṣèwádìí tún mẹ́nuba pé àwọn kò ní dátà lórí ìpàdánù sójà ara, èyí tó wúlò fún ṣíṣẹ òdiwọ̀ fún iye ìkóràn lápapọ̀.

Ìwádìí ìjìnlẹ̀ yìí jẹ ara ètò ńlá fún ṣíṣọ́ SARS-CoV-2 nípa líló sójà ara ní Kenya, KEMRI Wellcome Trust Research Prigramme ló ṣíwájú ìwádìí ìjìnlẹ̀ náà.


Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?