Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àwọn Àṣèwádìí Ajẹmẹ́jẹ̀-ìbí ya àwòran ìtànká kòkòko párásáìtì ibà tí a kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ káàkiri àgbááyé

Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.06.01.127423

Published onAug 14, 2023
Àwọn Àṣèwádìí Ajẹmẹ́jẹ̀-ìbí ya àwòran ìtànká kòkòko párásáìtì ibà tí a kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ káàkiri àgbááyé
·

Ìgbòòrò onírúurú jẹ̀nẹ́tíìkì nínú kòkòrò Plasmodium vivax láti Sudan àti ìbáṣepọ̀ ẹ̀jẹ̀ tí ó ní pẹ̀lú àwọn ayakúrò yòókù.

Àìsàn iba Plasmodium vivax jẹ ààrùn abóòrùn rìn tí a kò kọbi ara sí ní ilẹ̀ Áfíríkà látàrí àìwọ́pọ̀ rẹ̀ àti àìsí àyẹ̀wò tó pé pérépéré.

Láìpẹ́ yìí, àlékún tó ga ti wà lórí ìṣẹ̀lẹ̀ P.vivax ní apá Ìlà-Oòrùn Áfíríkà, ìròyìn sì gbé e pé ó ti ń tàn wọ àwọn orílẹ̀-èdè ìlú Ọba.

Ìṣẹ́ ìwádìí yìí wo ibùdó orírun àti onírúurú ẹ̀jẹ̀ P.vivax ní Sudan pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ microsatellite 14.

Àpapọ̀ àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ P.vivax 113 jẹ́ gbígbà ní àwọn agbègbè méjì, New Halfa àti Khartoum ní Sudan.

Ní àfikún, dátà láti àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ ibùdó 841 tí a gbà lórí àtẹ-ìpadátàmọ́ fún àtúpalẹ̀ jẹ̀nẹ́tíìkì àgbááyé jẹ́ fífikún àtúpalẹ̀ náà láti tẹ̀síwájú àwọn ìbáṣepọ̀ ajẹmọ́-jẹ̀nẹ́tíìkì láàárín ayakúrò P.vivax ní ẹ̀kùnjẹkùn àti ní ipele ti àgbááyé.

Ní ipele ti ẹkùnjẹkùn, a ṣàkíyèsí hapílótáìpù 91 tó yàtọ̀ àti 8 tí ó jẹ́ pínpín láàrin àwọn àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ ti Sudan.

Irúfẹ́ ìgbésókè onírúurú jẹ̀nẹ́tíìkì yìí pẹ̀lú àfiwéra pẹ̀lú àwọn ayakúrò yòókù ṣèèrí sí àṣedánwò wí pé ilẹ̀ Áfíríkà ni P.vivax ti ṣẹ̀ wá.

Ní ipele ti àgbááyé, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe ṣàfihàn rẹ̀, a ṣàkíyèsí a rí ìṣùpọ̀ jẹ̀nẹ́tíìkì tó yàtọ̀ àwọn P.vivax ayakúrò láti Áfíríkà, South America, àti Asia (tí ó fi mọ́ Papua New Guinea àti Solomon Island) pẹ̀lú ìwọ̀nba ìdàpọ̀ nínú àwọn ìṣùpọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí.

Ìtúpalẹ̣̀ ẹ̀yà to jẹ́́ orí àti àtẹ ìtàn ìbáṣepọ̀ jẹ̀nẹ́tíìkì fi irúfẹ́ bátánì ìṣùpọ̀ yìí hàn ó sì tún ṣàgbéjéde ipa àwọn ayakúrò ilẹ̀ Áfíríkà sí ìyàtọ̀ inú jẹ̀nẹ́tíìkì tí a ṣàkíyèsí káàkiri àgbááyé.

P.vivax ti apá Ìlà-Oòrùn Áfíríkà fi ìjọra hàn pẹ̀lú àwọn ayakúrò Asian léyìí tó ń dábàá ìfarahàn ohun kan tó ṣe pàtàkì.

Àwọn èsì wa ṣe àfihàn Ìgbòòrò ìyàtọ̀ onírúurú jẹ̀nẹ́tíìkì tó ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìyara aláìmọye ọ̀nà, léyìí tí ó ṣe àfihàn ìpa lílo ohun-èlò makirosátẹláìtì gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìdèènà tó dójú àmì.


Àwọn Àṣèwádìí Ajẹmẹ́jẹ̀-ìbí ya àwòran ìtànká kòkòko párásáìtì ibà tí a kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ káàkiri àgbááyé

Àwọn Aṣèwádìí ya àwòran jẹ̀nẹ́tíìkì ọ̀kan nínú àwọn kòkò párásáìtì tó ń fa àìsàn ibà láti tọ pinpin bí oríṣiríṣi rẹ̀ ṣe lè di títàn káàkiri àgbááyé.

Wọ́n ní ó dà bí ẹni pé ilẹ̀ Áfíríkà ni orírun kòkòko párásáìtì, Plasmodium vivax náà.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn Aṣèwádìí kókó rò pé ìwọ̀n ibà tí kòkòrò párásáìtì yìí ń fà kéré níye.

Ṣùgbọ́n, ó ti ń jọ bí ẹni pé àlékún ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀ tí ń ga sí i ní Ìlà-Oòrùn Áfíríkà àti àwọn apá ibòmìíràn lágbàáyé.

Àìsàn ibà Plasmodium vivax (PV) kìí sábà mú ìnira dání, ṣùgbọ́n àwọn ìwádìí àìpẹ́ yìí ti fi hàn pé PV lè wararo lára ènìyàn tí yóò sì máa báwọn fíra lemọ́lemọ́, léyìí tí yóò jẹ́ kí wọn ó má sá lẹ́nu iṣẹ́ òòjọ́ wọn.

Èyí, pẹ̀lú ìfẹ́ àti máa gba ìtọ́jú lemọ́lemọ́, lè máa fa ọrọ̀-ajé nílẹ̀.

Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, àwọn aṣèwádìí fẹ́ ṣe ìtúpalẹ̀ jẹ̀nẹ́tíìkì kòkòrò párásáìtì PV tí a ṣàlábàápàdé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi káàkiri àgbááyé.

Àwọn dátà jẹ̀nẹ́tíìkì àti ti ibùdó lè ra àwọn aláṣẹ ètò-ìlera láti mú àdínkù bá ìtànkálẹ PV àti ìtọ́jú tó dára sí I fún àìsàn ibà.

Àwọn aṣèwádìí gba DNA láti ara àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ atìka-ọwọ́-gbà tí a gbà lára aláìsàn kan kí ó ní àìsan ibà PV ní New Halfa àti Khartoum, méjèèjì ní orílẹ̀-èdè Sudan.

Wọ́n tún lo àwọn dátà láti ara àwọn àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ tí a gbà ní àwọn ibòmìíràn ní ilẹ̀ Áfíríkà, South America, àti Asia.

Wọ́n ṣe àfiwéra àwọn àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ náà láti wá ìjọra àti ìyàtọ̀ káàkiri àwọn ibùdó.

Àwọn aṣèwádìi rí I pe jẹ̀nẹ́tíìkì àpẹẹ.rẹ ẹ̀jẹ̀ PV káàkiri ní ìjọra pẹ̀lú àwọn jẹ̀nẹ́tíìkì mìíràn ní ilẹ̀ kan náà.

Èyí túmọ̀ sí pé ó ṣeéṣe kí wọn ó lè sọ ibi tí àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ kan ti wá pẹ̀lú jẹ̀nẹ́tíìkì rẹ̀.

Ohun tó yani lẹ́nu ni pé, wọ́n rí i pé àwọn jẹ̀nẹ́tíìkì tí a gbà ní Áfíríkà wà lónírúurú ju ̀wọn àpẹẹrẹ láti àwọn ilẹ̀ mìíràn lọ.

Lọ́nà mííràn, àwọn àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ tí a gbà ní Asia, fún àpẹẹrẹ, ní ìjọra pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ Asia ju àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà sí ti àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfíríkà lọ.

Ìpónírúurú jẹ̀nẹ́tíìkì ní ilẹ̀ Áfíríkà yìí dábàá rẹ̀ pé ilẹ̀ Áfíríkà ni PV ti wá.

Wọ́n tún rí i pé àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà fara jo àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ ilẹ̀ Asia ju àpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ ilẹ South America lọ.

Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn tàbí ẹranko tí ó kó PV ṣeéṣe kí ó yí láàrin Áfíríkà àti Asia láìpẹ́ yìí.

Yáya àwòrán jẹ̀nẹ́tíìkì kòkòro párásáìtì ní ọ̀nà yìí fún àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní òye bí kòkòrò yìí ṣe ń tàn kiri ̀wọn ibùdó oríṣiríṣi.

Àwọn Aṣèwádìi sọ pé àwọn ìwádìí ọjọ́ iwájú lè ṣàmúlò àlàyé yìí láti ṣe ìdámọ̀ àbùdá ibùdó, bí àwọn òkè, tí ó da oríṣìí àwọn PV sọ́tọ̀.

Ilẹ̀ Sudan, Eritrea, France, àti USA ni àwọn aṣẹ̀wádìí tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwádìí yìí fìdímúlẹ̀ sí.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?