Description
This is a lay summary for the article published under the DOI: 10.1186/s12891-020-03341-y
Yoruba translation of DOI: 10.1186/s12891-020-03341-y
Láì sí àní àní àwọn nọ́ọ̀sì ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni òṣìṣẹ́ ètò ìlera àkọ́ọ́rí tó wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ohun ẹ̀lò ìlera tó ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́.
A ka irú àwọn iṣẹ́-ṣíṣe yìí kún ìdí pàtàkì tí ó ń ṣokùnfà agbára iṣẹ́.
A ka iṣẹ́ nọ́ọ́sì kún ara àwọn iṣẹ́ akọ́ṣẹmọṣẹ́ tí ewu ẹ̀yìn ríro rẹ̀ ga jù.
Iṣẹ́ nọ́ọ́síìnì wà lára àwọn iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mẹ́wàá tó gbegbáarókè tó sì ní ewu ẹ̀yìn ríro ọwọ́ ìsàlẹ̀.
Nítorí náà, àgbéyẹ̀wò yìí wà láti ṣe àrídájú bóyá ẹ̀yìn ríro ọwọ́ ìsàlẹ̀ yìí jẹ́ ohun tó pè fún àkíyèsí àwọn nọ́ọ̀sì ní ilé ohun èlò ètò ìlera ilẹ̀ Adúláwọ̀.
A wá oríṣiríṣi ìpadátàmọ́ lórí i lítírésọ̀ ọjọ́ tí ò ní gbèdéke láàárín oṣù ọ̀wẹ̀wẹ̀ sí béélú 2018 nígbà tí wọ́n sì lo ìlànà ìtọ́sọ́nà PRISMA.
Wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wò bi ìwádìí náà ṣe dára tó nípa ṣiṣàmúlò òṣùwọn oní nǹkan-12.
Wọ́n ṣe àyèwò àtúnpín-ẹgbẹ́ àti ti ìfàmọ́ra.
Wọ́n lo Cochran Q àti ìdánwò I2 láti fi ṣe àyẹ̀wò àwọn ìyàtọ̀ amúyẹ.
A ṣẹ àyẹ̀wò ìyàtọ̀ àtẹ̀jáde tí ó wà nípa lílo ìdánwò Egger pẹ̀lú wíwò ó ní ṣísẹ̀ntèlé.
Nínú àgbéyẹ̀wò yìí, ìwádìí 19 láti àwọn oríṣiríṣi agbègbè ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ṣàfikún ẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n àwọn nọ́ọ̀sì 6110.
Gbogbo àwọn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ni wọ́n gbé wò ní àárín 2000 àti 2018.
Lára àwọn èyí, a rí i pé èyí tí ó kéré jù àti èyí tí ó tóbi jù jẹ́ 44.1 àti 82.7% lọ́lọ́ kan ò jọ̀kan.
Àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀yìn ríro láàárín àwọn nọ́ọ̀sì hànde nípa ṣíṣàmúlò ipá àwòṣe jẹ́ 64.07% (95% CI: 58.68–69.46; P-value < 0.0001).
Àwọn ìyàtọ̀ àmúyẹ inú ìwádìí tí a yẹ̀wò jẹ́ I2=94.2% àti ìyàtọ̀ àmúyẹ =310.06(d.f=18), ipò-P <0.0001.
Àtúpalẹ̀ ìpínsísọ̀rí yìí fi hàn pé èyí tí ó ga jù nínú LBP láàárín àwọn nọ́ọ̀sì iwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ hànde pẹ̀lú 68.46% (95% CI:54.94-81.97; nínú ipò-P jẹ́ <0.0001) tí apá Gúúsù ilẹ̀ Adúláwọ̀ sì tèlé e pẹ̀lú òṣùwọ̀n 67.95% (95% CI: 55.96–79.94; P-value < 0.0001).
Bí ó tilè jẹ́ pé ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ kéré tí a ba fi wé ti ìmọ̀ Ìwọ̀-Oòrùn àti Éṣíà, ó fi hàn pé ẹ̀yìn ríro ọwọ́ ìsàlẹ̀ àárín àwọn nọ́ọ̀sì ní ìkìmí.
Ó lé ní 60% àwọn nọ́ọ̀sì ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ló ní ẹ̀yìn ríro ọwọ́ ìsàlẹ̀
Ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ àwọn nọ́ọ̀sì jẹ́ òṣìṣẹ́ oníṣẹ́ ìlera àkọ́ọ́rí tó ṣe pàtàkì jùlọ níbi tí àwọn orísun ìlera bá ti ṣọ̀wọ́n.
Ìwádìí yìí ṣe àgbéyèwò lórí iṣẹ́ ìwádìí ọdún 19 tí ó ṣàfihàn pé ó lé 60% àwọn nọ́ọ̀sì ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni ẹ̀yìn ríro ọwọ́ (LBP) ìsàlẹ̀ ń bá fínra.
Kòṣeémánìí ni àwọn nọ́ọ̀sì jẹ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, àti pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe máa ń fàbọ̀ sí àgọ́ ara wọn.
Kárí ayé, iṣẹ́ nọ́ọ̀sì wà lára àwọn iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ 10 ní àgbáyé tí ó ba ti dé ibi ewu LBP.
Kódà, ìròyìn tó wa létí pé LBP láàárín àwọn nọ́ọ̀sì ní ìlú Ọsiturélíà ga tó 63%, 56% ni ìlú Ṣáínà, tí ó sì ga tó 82.7% ní àwọn orílé-èdè Adúláwọ̀ kọ̀ọ̀kan.
Àwọn olùṣèwádìí wo àwọn iṣẹ́ ìwádìí tó tó ọdún 19 láti wo bí LBP gbilẹ̀ tó láàárín àwọn nọ́ọ̀sì ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Wọ́n wo àwọn lítíréṣọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ní oríṣiríṣi ìpadátàmọ́ láti wá àwọn ìmọ̀ oríṣiríṣi tí a tẹ̀ jáde ní àárín 2000 àti 2018.
Ìwádìí náà lo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àpapọ̀ 19 ti àwọn nọ́ọ̀sì 6110 tí o wá láti àwọn agbègbè oríṣiríṣi káàkiri ilẹ̀ Adúláwọ̀.
64.07% àwọn nọ́ọ̀sì ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni ẹ̀yìn ríro ọwọ́ ìsàlẹ̀ ń bá fínra.
Ìwádìí ìjìnlẹ̀ fihàn pé àwọn nọ́ọ̀sì Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí LBP ń dà láàmú ló pọ̀ jù tí wọ́n sì jẹ́ 68.46% nígbà tí Àríwá ilẹ̀ Adúláwọ̀ tẹ̀lé e pẹ̀lú 67.95%.
Àwọn olùṣèwádìí sọ pé, pẹ̀lú ohun tí wọ́n ti mọ̀, ìwádìí yìí ni ìtúpalẹ̀- yáágbóyaájù àti àgbéyẹ̀wò fínnífínní àkọ́kọ́ tó ṣe ìtọpinpin lórí bí LBP ṣe pọ̀ tó ní á̀árín àwọn nọ́ọ̀sì ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Ó ṣeni láàánú pé,àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ò ní dátà ńlẹ̀, èyí tí ó lè ṣe ìpa lára fún àwọn èsì kọ̀ọ̀kan tí a fi jábọ̀ nínú ìwádìí yìí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nọ́ḿbà tí a fi jábọ̀ síbí kéré bí a bá fi wé ìmọ̀ ti iwọ̀-Oòrùn àti ti Éṣíà, wọ́n sì ga gidi gan.
Àwọn olùṣèwádìí ṣe ìdúró pé àwọn ìjọba ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ṣàgbékalẹ̀ ipò àti ṣiṣẹ́ dáada, àwọn ònà àti dín wàhálà kù, àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn nọ́ọ̀sì tí yóò dín ewu LBP kù ní ọ̀nà pàtàkì.
Luganda translation of DOI: 10.1186/s12891-020-03341-y
Amharic translation of DOI: 10.1186/s12891-020-03341-y
Hausa translation of DOI: 10.1186/s12891-020-03341-y
Northern Sotho(Sepedi) translation of DOI: 10.1186/s12891-020-03341-y