Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àwọn olùṣèwádìí ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt dábàá módẹ́ẹ̀lì kọ̀m̀pútà láti ṣe ìrànwọ́ ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn àti láti ṣe ìwòsàn fún COVID-19

Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.04.16.20063990

Published onAug 14, 2023
Àwọn olùṣèwádìí ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt dábàá módẹ́ẹ̀lì kọ̀m̀pútà láti ṣe ìrànwọ́ ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn àti láti ṣe ìwòsàn fún COVID-19
·

Módẹ́ẹ̀lì Ìṣàtúpalẹ̀ Àmì Àìsàn àti Ìsọtẹ́lẹ̀ fún Èsì Aláìsàn COVID-19 sí Ìtọ́jú tó dá lórí Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Adálóríàwòrán àti Ẹ̀rọ Awójúùtú sí Òǹkà nípa lílo àwọn àwòrán-an CT

Ìfọ́ńka àrun kòróná (COVID-19) ti tàn káàkiri àgbáyé.

Àjọ tó ń rí sí Èto Ìlera Lágbàáyé (WHO) ti kéde pé àrun kòrónà COVID-19 jẹ́ àjàkálẹ̀ àrun káàkiri àgbáyé.

Ète Asọ Àpapọ̀ Ìyídà Àdàkọ Lílo Ẹ̀wọ̀n Ìṣesí (RT-PCR) ní ìfàyègba ráńpé ní àwọn àsìkò ìsáájú COVID-19.

Fún ìdí èyí, Ìfi Kọ̀m̀pútà Yàwòrán Inú Ara (CT) máa ń jẹ́ lílò fún ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn.

COVID-19 ní àwọn àmì lórí àyẹ̀wo CT èyìí tó mú u yàtọ̀ sí àwọn àrun inú ẹ̀dọ̀fóró tó gbajúmọ̀.

Lára àwọn àmì náà ni iyàwòrán inú ẹ̀dọ̀fóró, ìrọ́pò àpo èémí inú ̀ẹ̀dọ̀fóró, àti irúfẹ́ bátànì tí a máà ń rí nínú ẹ̀rọ iyàwòrán inú ara.

Nínú ìwé iṣẹ́ ìwádìí yìí, Módẹ́ẹ̀lì Ẹ̀rọ tí a kọ́ níṣẹ́-mọṣẹ́ fún Ìṣàtúpalẹ̀ Àmì Àìsàn ati Ìsọtẹ́lẹ̀ fún Èsì Aláìsàn COVID 19 sí Ìtọ́jú (AIMDP) jẹ́ èyí tí a dábàá.

Módẹ́ẹ̀lì AIMDP ní ìṣe gbòógì méjì tí a dábàá sínú ẹ̀ka mẹ́jì, àwọn ni, Ẹ̀ka Ìṣàtúpalẹ̀ Àmì Àìsàn (DM) àti Ẹ̀ka Ìsọtẹ́lẹ̀ (PM).

Módẹ́ẹ̀lì Ìṣàtúpalẹ̀ Àmi À̀ìsàn (DM) jẹ́ èyí tí a dábàá ní lilò fún ìtètè mọ̀ àti láti ní ìdánilójú nípa ẹeni tó ní àrun COVID-19 kí ó sì lè ṣe ìyàtọ̀ láàárin rẹ̀ àti àwọn àrun inú ẹ̀dọ̀fóró tó gbajúmọ̀ nípa lílo àwọ àmi àìsan COVID-19 tí a rí gbà látara ẹ̀rọ ìṣàyẹ̀wo CT.

Módẹ́ẹ̀li DM náa,̀ máa ń ṣàmúlò Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Adálóríàwòrán (CNNs) gẹ́gẹ́ bí i ète Ìjìǹlẹ̀ ìkẹ́rọnímọ fún ìpínsọ́wọ̀ọ́, lè yànàná ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọ̀rán CT ní ìṣẹ́jú àáyá láti lè fikún ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn COVID-19 àti láti fikún.

Láfikún, àwọn orílẹ̀-̀èdè kò ní ìkáwọ́ láti lè pèsè ìtọ́jú fún gbogbo aláàárẹ̀, nítorí náà yóò jẹ́ kókó láti pèse ìtọ́jú fún àwọn tí àgọ́-ara wọ́n bá ń fèsì rere sí akitiyan ìtọ́jú.

Ní ìbámu pẹ̀lú òyE ohun tí à ń sọ, Módẹ́ẹ̀lì Ìsọtẹ́lẹ̀ (PM) jẹ́ èyí tí a dábàá láti sọtẹ́lẹ̀ nípa ipá tí aláìlera kán ní ní ibámu pẹ̀lú bí àgọ ara rẹ̀ ṣe lè fèsi sí ìtọ́jú sí ní ìbámu p̀ẹ̀lú à̀wọn ohun bí i ọjọ́ orí, ipò ìkó àìsàn, ìkọ̀jálẹ̀ àwọn ẹ̀yà èémí, àìlèṣiṣẹ́ ọpọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà ara àti ti ìtọ́jú.

PM máà ń ṣàmúlò Ète Ẹ̀rọ Awójútùú sí Òǹkà láti lè yan ohun tó ṣe kókó jùlọ sí aláìsàn.

Èsì ìwádìí náà fi àwọn èsì gidi hàn fún àbá módẹ́ẹ̀lì ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn àti módẹ́ẹ̀lì ìsọtẹ́lẹ̀, nípa lílo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ tó gidi àti ti àwòrán àyẹ̀wo CT.


Àwọn olùṣèwádìí ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt dábàá módẹ́ẹ̀lì kọ̀m̀pútà láti ṣe ìrànwọ́ ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn àti láti ṣe ìwòsàn fún COVID-19

Àwọn olùṣèwádìí ṣẹ̀dá ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà tí ó lè ṣe ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn aàrun COVID-19 ní kíákíá pẹ̀lú èsi ìṣerẹ́gí tó péye.

Wọ́n tún ṣẹ̀dá módẹ́ẹ̀lì tó lè ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ nípa bí aláìsàn ṣe lè yára máa fèsì sí ìtọ́jú.

SARS-CoV-2, aàrùn ̀ya ara èémí tó máà ń fa COVID-19, tàn ní kíákíá ní 2020 láti ṣokùfa àjàkálẹ̀ àrùn agbáyé e COVID-19.

Ète asọ àpapọ̀ ìyídà àdàkọ lílo ẹ̀wọ̀n ìṣesí (RT-PCR) jẹ́ ọkan lára àwọn àyẹ̀wò tó péye jùlọ láti ṣe ìṣàtúpalẹ̀ àmi àìsàn COVID-19.

Àmọ́, ó le má ni àbájáde tó ṣe é fọkàn tán tí ìkóràn náà bá wà ní ipò ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀.

Ìfi Kọ̀m̀pútà Yàwòrán Inú Ara (CT) fẹ́ jọ èyí tó péye láti máa ṣe ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn COVID-19, àmọ́ àwọn àyẹ̀wò ìyàwòrán náà gbọ́dọ̀ di yíyẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ ènìyàn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà èrò ẹni tó ní aàrun COVID-19 ti máa ń pọ̀jù ní ilé ìwòsàn, awọn òṣìṣẹ́ ìlera ò ní.

Òǹkọ̀wé iṣẹ́ ìwádìí yìí fẹ́ lo ìmẹ̀rọ tí à ń pè ní “ìkẹ́rọnímọ̀” láti lè jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́wọ́ láti lè dá aláìsàn tó ní aàrun COVID-19 mọ̀ látara àyẹ̀wò àwòrán-an CT, kí wọ́n ba à le lo ìwọ̀m̀ba ohun èlò tí wọ́n ní láti lè ṣe ìtọ́jú àwọn tí àgọ ara wọn ní fèsì sí ìtọ́jú.

Wọ́n fẹ́ lo d́étà àwọn aláìlera tó kó COVID-19 láti kó kọ̀m̀pútà bí wọ́n ṣe ń ṣe ìṣàtúpalẹ̀ àmi àìsàn COVID-19 látara àyẹ̀wò ayàwòrán CT, àti láti lè sọ ìsọtẹ́l̀ẹ̀ bóyá àgọ́ ara aláìlera kan yóò fèsì sí ìtọ́jú.

Wọ́n tún fẹ́ fi kún okun àti ìṣerẹ́gí èsì àbájáde láti ṣe ìṣàtupalẹ̀ àmì àìsàn COVID-19 nípa lílo àyẹ̀wo ìyàwòrán CT.

Àwọn olùṣèwádìí yìí fún àwọn kọ̀m̀pútà wọn ní dátà àwọn aláìlera (bí I àyèwò ìyàwòrán CT, èsi àyẹ̀wo RT-PCR, àti iye ìsun èjẹ̀) kí ó ba lè mo bí a ṣe ń ṣe iṣàtupalẹ̀ àmì àìsàn COVID-19 àti láti dábàá ọ̀nà ìwòsàn, léyì tó dálé ìrírí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọn ṣe ìṣàtupalẹ̀ àmi àìsàn tí wọ́n sì ṣe ìtọ́jú àwọn aláìsàn náà.

Àwọn olùṣèwádìí náà sọ pé ẹ̀rọ àwọn lè ṣe èsi ìṣerẹ́gí tó tó 97% ó sì ṣ ṣe ìṣọtẹ́lẹ̀ láti àyẹ̀wo ìyàwòrán CT ní bí I 20 ìṣẹ́jú.

Wọ́n tún sọ pé ẹ̀rọ àwọn ń ṣe ìṣọtẹ́lẹ̀ tó péye ní ìgbà tí ò pẹ́ rárá ju bí àsẹyege tí àwọn olùṣèwádìí mìíràn lè sẹ lọ pẹ̀lú irúfẹ́ àwọn oríṣi dátà mìíran.

Àwọn ọ̀wọ́ olùṣèwádìí mìíràn ti wo ṣíṣe ìṣàtúpalẹ̀ àmì àìsàn COVID-19 nípa lílo àyẹ̀wo ìyàwòrán CT àti ìkẹ́rọnímọ̀.

Nínú àwọn iṣẹ́ ìwádìí yií àwọn módẹ́ẹ̀lì ẹ̀rọ náà kò le ṣàlàyé ìṣàtupalẹ̀ àmì àìsàn bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìṣègùn òyìnbó ṣe lè ṣe é; wọ́n máa ń pèsè ìsàtupalẹ̀ àmì àìsàn náà fún ara wọn.

Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, àwọn olùṣèwádìí gbìyànjú láti wá ojútùú sí ìṣòro náà nípa sísọ irúfẹ́ àyẹ̀wò ìyàwòrán CT tí ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà náà ń lò láti ṣe ìṣàtupalẹ̀ àmì àìsan rẹ̀.

Àwọn olùṣèwádìí náà gbimọ̀ láti ṣe àyẹ̀wò módẹ́ẹ̀lì yìí lórí I dátà láti fi ìdí èi wọn múlẹ̀.

Wọ́n tún gberò láti ṣe módẹ́ẹ̀lì tuntun tí ó lè ṣe ìṣotẹ́lẹ̀ bí ó ṣe rẹ àwọn tí wọ́n kó àrun COVID-19 tó.

Wọ́n ni yóò ṣe ìrànwó fún àọn dókítà lórí I bí wọn yóò ṣe máa se ìwòsàn fún àwọn aláìlera.

Pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú ìwadìí, àwọn ọ̀wọ́ olùṣèwádìí ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt lè ṣe ìrànwọ́ fún àwọn dókítà lórí I bí wọ́n ṣe lè lo ìwọ̀m̀ba ohun èlò tí wọ́n ní láti fi tójú àwọn aláìsàn COVID-19.

Amọ́, ète wọn yóò nílò àwọn ohun iẹ̀rọ ̀akójúọ̀sùwọ̀ń, bí I ẹ̀rọ ayàwòrán CT àti àwọn kọ̀m̀pútà tó dáńtọ́, léyìí tó lè má sì ni ọpọ̀lọpọ̀ agbègbè nílẹ̀ Áfíríkà.

Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?