Description
Lay summary for the article published under the DOI: 10.1101/2020.08.31.274852
Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.08.31.274852
Ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì (Ensete ventricosum) jẹ́ ohun ọ̀gbìn ọlọ́pọ-ìlò tí wọ́n ń gbìn lọ́pọ̀lọpọ̀ ní apá gúúsù àti gúúsù-mọ́-ìwọ-oòrùn ilẹ̀ Ethiopia fún oúnjẹ ènìyàn, oúnjẹ ẹranko àti fáíbà.
Ó ń dásí ìpèsè oúnjẹ àti àtijẹ-àtimu ní ìgberíko fún àwọn ènìyàn tí wọ́n tó mílíọ́nù lọ́nà ogún (20).
Ọlọ́kanòjọkan ni àgbélẹ̀rọ ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ń gbìn fún ìlò wọn nínú ìṣègùn ìbíl̀ẹ̀.
Àyípadà ajẹmọ́rọ̀-ajé tó bá àwùjọ àti ìpàdánu ìmọ̀ abínibí le yọrí sí àìnísí àwọn àgbélẹ̀rọ ajẹmégbògi mọ́ àti àwọn onírúnrú ìran tí wọ́n so mọ́ wọn.
Àmọ́ ṣá, a kò tí ì mọ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí bóyá a lè fi àbúdá ajẹmọ́ran ya àwọn àgbélẹ̀rọ ajẹmégbògi sọ́tọ̀ sí àwọn àgbélẹ̀rọ tí wọn kì í se egbògi.
Ní ọ̀gangan yìí, a ṣàpèjúwe onírúnrú ìran àgbélẹ̀rọ ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì láti kín ìdáàbòbò àti ìlò wọn tó já gaara lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan.
A ṣàyẹ̀wò onírúnrú ìran àgbélẹ̀rọ ẹ́ńsẹ́ètì 51, tí 38 nínú wọn sì ní iye ajẹmégbògi lórí.
Àpapọ̀ irú ojú-ìran 38 mìíràn ni wọ́n kàn jájè-jádò gbogbo ọ̀gangan 15 ìṣẹ̀lè SSR.
AMOVA ṣàfihàn rẹ̀ pé ìdá 97.6 nínú onírúnrú ìran wà láàrin ìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n ní FST 0.024 láàrin àwọn àgbélẹ̀rọ tí wọ́n jẹ́ egbògi-oògùn àti àwọn tí wọn kì í ṣe egbògi-oògùn.
Ẹ̀hun igi ìso-alábàágbépọ̀ ṣàfihàn ìsùpọ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí kò ní ìbátan kankan pẹ̀lú ìlò iye àwọn àgbélẹ̀rọ náà.
Ìtúpalẹ̀ (PcoA) náà tún fi òǹtẹ̀ lù ú pé kò sí ìyàtọ̀ ìṣùpọ̀ kankan láàrin àwọn ọ̀wọ́ náà, ó ṣàfihàn ìyàtọ̀ tí ò kéré láàrin àwọn àgbélẹ̀rọ tí wọ́n ń lò nínú ìṣègùn ìbílẹ̀ àti àwọn tí wọ́n wúlò fún nǹkan mìíràn.
A rí i pé àwọn àgbélẹ̀rọ ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì ń ṣùpọ̀ láìsí òté ìlò kankan, wọn kò sì fi ẹ̀rí ìyàtọ̀ ajẹmọ́ran hàn láàrin ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì tí wọ́n gbìn fún “ìṣègùn” àti àwọn àgbélẹ̀rọ tí wọn kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìṣègùn.
Èyí dábàá pé àwọn èròjà ìjóògùn ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì le má fẹjú ju iye nọ́ḿbà oríṣìí-ìran kọ̀ọ̀kan lọ, ó lè jẹ́ àbájáde ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwùjọ tàbi ìṣe ìṣọwọlò, tàbí kí àbọ̀ jịjẹ́ rẹ̀ má tọ̀nà tó.
Iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àlàyé ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ tí ó ṣe ìgbélárugẹ ìtọpinpin síwájú sí i nípa fífa ìjóògùn yọ nínú ẹ̀yà. àgbélẹ̀rọ ní pàtó.
Ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì, irúgbìn fún oúnjẹ àti egbògi pàtàkì tí ó yẹ kí wọ́n dáàbò bò, wà ní onírúnrú gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ará ìgbèríko Ethiopia fi yé wa, àmọ́ àwọn aṣèwádìí rí àwọn ìyàtọ̀ ajẹmọ́ran díẹ̀ nínú àwọn “àgbélẹ̀rọ” yìí.
Ẹ̀yà ẹranko tàbi irúgbìn tí ìyàtọ̀ wọn fojú hàn ni "Àgbélẹ̀rọ".
Ní Ethiopia, onírúnrú àgbélẹ̀rọ ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ń lò fún ìṣègùn ìbílẹ̀ láti tọ́jụ́ egungun tó bá kán, tọ́jú àrùn ẹ̀dọ̀, tàbi láti tọ́jú ìgbẹ́ gbuuru.
Ohun-jíjẹ ni wọ́n ń lo àwọn yòókù fún, ounjẹ àwọn ẹranko àti fáíbà- wọn kì í gbin irúgbìn náà fún èso orí rẹ̀, àmọ́ wọ́n lè jẹ lára ẹ̀ka rẹ̀.
Ó ṣe ni láànú, ewu píparun àwọn ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì ajẹmégbògi gẹ́gẹ́ bí irúgbìn ló pọ̀ jù tí àwọn yòókù lọ, tí wọ́n jẹ́ jíjẹ, tí wọn ń gbìn kálé-káko, torí ìyàtọ̀ tí ó ti bá àwùjọ àti ọrọ̀-ajé àti àìnímọ́ abínibí.
Àwọn ìwádìí àtẹ̀yìnwá lórí ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì gbájú mọ́ irúgbìn láti àwọn ibikan ní pàtó, àmọ́ nínú iṣẹ́ yìí, àwọn aṣèwádìí wo onírúnrú ìran àwọn ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì ajẹmégbògi ní pàtó, àti àwọn ìbaṣepọ̀ ajẹmọ́ran tí ó wà láàrin àwọn àgbélẹ̀rọ.
Bí wọ́n bá lóyé dáadáa nípa ìran ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì lè ṣe àwọn ìpinnu ìdáòbò láti dáàbò bo irúgbìn tí ó jọjú nínú àṣà àti ìlò yìí.
Láti tọ́ka sí àwọn àgbélẹ̀rọ tí ó ṣe pàtàkì, àwọn aṣèwádìí bẹ àwọn àgbààgbà abúlé ní ibi mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Ethiopia wò.
Wọ́n ṣe àfiwé nípa ìran àwọn àgbélẹ̀rọ ajẹmégbògi pẹ̀lu àwọn àgbélẹ̀rọ tí wọn kì í lò gẹ́gẹ́ bi egbògi, tí ó jẹ́ pé jíjẹ ni wọ́n ń jẹ wọ́n.
Ìṣàǹfààní ibẹ̀, àwọn aṣèwádìí rí i pé bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà láàrin àwọn irúgbìn lọ́ọ̀kan, ìran ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì fún jíjẹ àti fún egbogi kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra.
Kò sì tún sí ẹ̀rí tí ó dábàá pé àwọn àgbélẹ̀rọ tí wọ́n ní orúkọ ìbílẹ̀ ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń lò láti tọ́jú àrùn kan náà, jẹ́ ti àwọn ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ìyẹn báyẹn, àwọn aṣèwádìí kófìrí ìbáṣepọ̀ ajẹmọ́ran tímọtímọ́ láàrin àwọn irúgbìn tí wọ́n ń fi orúkọ ìbílẹ̀ kan pè, èyí tí ó túmọ̀ sí pé ipá àwọn ará ilẹ̀ náà dára jọjọ nípa fífi ojú ṣe ìdámọ̀, àti ṣíṣe ìyàtọ̀ láàárin àwọn àgbélẹ̀rọ kọ̀ọ̀kan pàtó.
Àwọn èsì wọ̀nyí ṣe àfikún àwọn ìmọ tí ó túnbọ̀ ń pọ̀ si nípa ìran ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì, èyí tí ó ran akitiyan ìdáàbò bò lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn àgbélẹ̀rọ tó ṣe pàtàkì sí ìṣègùn.
Àwọn àlàyé ajẹmọ́ran náà tún lè se ìrànwọ́ fún àwọn aṣèwádìí àwọn èròjà ajẹmégbògi ẹ́ńsẹ́ẹ̀ì lọ́jọ́ iwájú.
Àwọn aṣèwádìí dábàá ọ̀pọ̀ ohun tí ó fa ìjọra nínú àwọn ìran tí wọ́n rí.
Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe-é-ṣe kí ó jẹ́ pé gbogbo àwọn irúgbìn ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ní ìlò ajẹmóṣègùn, àwọn àṣà jẹ́ ìdí tí wọ́n fi ṣe àṣàyàn àwọn àgbélẹ̀rọ kọ̀ọ̀kan.
Ó tún ṣe-é-ṣe kí ó jẹ́ pé iye èròjà ajẹmégbògi ti irúgbìn kan nííṣe pẹ̀lú agbègbè wọn, pẹ̀lú bí irúgbìn ṣe ń gbèrú síi nípa àbùdá ajẹmóògùn tó jọjú ní ọ̀gangan àwọn òté kọ̀ọ̀kan.
Ní ọjọ́-iwájú, àwọn àbùdá kẹ́míkà ti onírúnrú àgbélẹ̀rọ le ṣínà ìṣípayá tó jinlẹ̀ nípa iye àbùdá ajẹmégbògi tó peléke jùlọ.
Iṣẹ́ ìwádìí yìí wà lára àjọṣepọ̀ tó fẹjú láàrin UK àti àwọn aṣèwádìí tí wọ́n fi ilẹ̀ Áfíríkà se ìbùdó tí ó fojúsun ríràgàbo ààbò àti ìpèsè oúnjẹ àti lílóye nípa èròjà ajẹmóògun tí ó wà lára irúgbìn ẹ́ńsẹ́ẹ̀tì.
Luganda translation of DOI: 10.1101/2020.08.31.274852
Amharic translation of DOI: 10.1101/2020.08.31.274852
Hausa translation of DOI: 10.1101/2020.08.31.274852
Northern Sotho(Sepedi) translation of DOI: 10.1101/2020.08.31.274852
Zulu Translation of DOI: 10.1101/2020.08.31.274852