Skip to main content
SearchLoginLogin or Signup

Àìsàn ọkàn àti ìtọ̀ ṣúgà máa ń fi àwọn aláìsàn COVID-19 sí nú ewu sí i

Yoruba translation of DOI: 10.1101/2020.11.28.20240267

Published onSep 29, 2023
Àìsàn ọkàn àti ìtọ̀ ṣúgà máa ń fi àwọn aláìsàn COVID-19 sí nú ewu sí i
·

Ipa ọ̀pọ̀ aàrùn lórí àbájáde COVID-19

Àgbétẹ́lẹ̀ àti àfojúsùn

Àjàkáyé aàrun kòró 19 (COVID-19) yìí tí yára tàn kárí ayé pẹ̀lú rírò ipò alárùn àti ìṣẹ̀lẹ̀ ikú.

Wọ́n ti jábọ̀ láìmọye ìgbà pé ìbágbépọ̀ ọlọ́pọ̀ aàrùn pẹ̀lú COVID-19 jẹ́ ewu ńlá fún àsọtẹ́lẹ̀ àbájáde àìsàn tí kò dára.

Àfojúsùn wa ni láti ṣe àgbéyẹ̀wò ipa ti ọ̀pọ̀ aàrùn ń kó nínú àwọn aláìsàn COVID-19 lórí àbájáde àti mímọ̀ iye ọjọ́ tí wọ́n yóò lò ni ilé-ìwòsàn, bíbéèrè fún ìgbàwọlé fún ICU tàbí òkú.

Àwọn ọ̀nà àágbegbà

Ọ̀kàn-dín-lógójì-lé-ní-irinwó àwọn aláìsàn àgbàlagbà tí wọ́n gbà ní (oṣù Okúdù àti oṣù Agẹmọm 2020) ní ilé-ìwòsàn yunifásítì Assiut àti Aswan wà nínú ìwádìí yìí.

Gbogbo àwọn akópa ni wọ́n ní COVID-19 gégẹ́ bí àlàálẹ̀ tí ílé-iṣẹ́ ètò ìlera fi lọ́lẹ̀ bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàtó tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ é ṣẹ kí ó ṣẹlẹ̀.

Esi

̀(TaqMan™ 2019-nCoV Control Kit v1 ni ó ṣe àwárí SARS-CoV-2 tí QIAGEN ní Germany pèsè (Cat. No. A47532) lórí ẹ̀rọ ohun ẹlẹ́mìí 7500 RT PCR, USA.

Àwọn ọlọ́pọ̀ àìsàn jẹ́ 61.7% nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n rí.

Àmì àìsàn tí ó wọ́pọ̀ jù ni pàápàá àmì àìsàn myalgia àti LRT bí i ìmí ìnira máa ń jẹ́ àmì àìsàn tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn aláìsàn tó ní ọ̀pọ̀ àìsàn (P < 0.05).

Àwọn aláìsàn tó ní ọ̀pọ̀ àìsàn kò ní láábù tó dára.

Ìgbàwọlé fún ICU pọ̀ fún àwọn ọlọ́pọ̀ àìsàn (35.8%).

Láàárín àwọn oríṣi ọlọ́pọ̀ aàrùn 45.4% ìṣẹ̀lẹ̀ CVD ni wọ́n gbà sí ICU lẹ́yìn náà ni ìṣẹ̀lẹ̀ DM tèle (40.8%).

Àti wí pé, àwọn ọlọ́pọ̀ aàrun nílò kí wọ́n ran ìmí sókè-sódò wọ́n lọ́wọ́ jú àwọn tí wọn ò lọ́pọ̀ aàrun lọ (31 vs. 10.7%, P<0.001).

Òdiwọ̀n àti ní ìwòsàn fún àwọn tó ní ọlọ́pọ̀ aàrùn tó ní COVID-19 kéré (59% vs.81%, P<0.001) ìṣẹ̀lẹ̀ ikú wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó ní ọ̀pọ̀ aàrùn (P< 0.001).

Àwọn tí wọ́n wà láyé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú CVD tó ti wà tẹ́lẹ̀ àti àwọn àìsàn ara mìíràn kéré sí àwọn tí kò ní aàrùn kankan (P<0.002 àti 0.001 lẹ́sẹẹsẹ).

Ìkádìí

Egbẹ́ ipò cardiovascular comorbid pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí àwọn àìsàn ara papọ̀ mọ ìkóràn COVID-19 ní ewu ìṣẹ̀lẹ̀ ikú.

Wàyí, àwọn ọlọ́pọ̀ aàrùn bí I ìtọ̀ ṣúgà, ajẹmọ́ ẹ̀dọ̀fórá ọlọ́jọ́ pípẹ́ tàbí àarùn kíndìnrín lè fá kí agbára COVID-19 pọ̀ si.


Àìsàn ọkàn àti ìtọ̀ ṣúgà máa ń fi àwọn aláìsàn COVID-19 sí nú ewu sí i

Ìwádìí fihàn pé aláìsàn COVID-19 tó ní àìsàn mìíràn bí i ẹ̀jẹ̀ ríru, ìtọ̀ ṣúgà, ọ̀fun, kíndìnrín àti àìsàn ọkàn wọ́n wà ní inù ewu àti ní àìsàn tó le, wọ́n sì nílò ìtọ́jú tó péye ní ilé ìwòsàn.

Ní àkótán, ó lẹ ó sì wọ́n láti tọ́jú aláìsàn tóní jú aàrun kan lọ.

Ọlọ́pọ̀ aàrun ní wón pe àwọn tó ní aàrùn abẹ́lẹ̀ tàbí ipò.

Àwọn dókítà jábọ̀ pe aàrun COVID-19 máa ń peléke si í lára àwọn olọ́pọ̀ aàrùn.

Àjàkáyé aàrun COVID-19, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2020, pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lágbàáyé àti wí pé àwọn ilé ìwosàn kò ní béèdì ICU fú àwọn aláìsàn.

Fún ìdí èyí, àwọn d́okítà ń wá ọ̀nà àti tètè mọ àwọn aláìsàn tó yẹ kí wọ́n wà ní ICU.

Nínú ìwádìí yìí, àwọn aṣèwàdìí ṣe àwárí bí àwọn ọlọpọ̀ àìsàn ṣe ní ipa lórí àwọn alárùn COVID-19.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n wo àwọn nǹkan tí ó lè fà á kí aláìsàn wà ní ilé-ìwòsàn fún ọjọ́ pípẹ́, gbígbà sí ICU tàbí ikú látàrí aàrùn COVID-19.

Àwọn aṣèwádìí ṣe àkíyèsi àwọn àgbàlagbà tó ni COVID-19 tí wọ́n gbà sí ilé-ìwòsàn 2 tó tóbi jù ní Egypt, àti wíwo àkòsílẹ̀ ìlẹra fún data àwọn ènìyàn, èsì ìdánwò lááàbù, àti èsì fótò àyà.

Wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ bọ́yá wọ́n gbà aláìsàn tí ara rẹ̀ yá sí ICU tàbí ó kú.

Àwọn aṣèwádìí ṣe àfiwéra èsì àyẹ̀wò ọlọ́pọ̀ aàrùn àti àwọn tí kò ní.

Ìwádìí fihàn pé ó kọjá Ìdá méjì àwọn aláìsan tí wọ́n ní ọpọ̀ àìsàn pẹ̀lú aàrùn ọkàn àti ìtọ̀ ṣúgà ló wọ́pọ̀ jù.

Àwọn ọlọ́pọ̀ àìsàn kò ní èsì láaàbù tó dáa àti wí pé wọ́n lè má ye àìsàn COVID-19.

Bákan náà, àwọn aláìsà tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ aàrùn bí àìsàn ọkàn tàbí ìtọ̀ ṣúgà, ó ṣe é ṣe kí wọ́n gbà wọ́n sí ICU kí wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́ láti mí.

Èsì tún fihàn pé àwọn arúgbó ni ó ṣe e ṣe kí wọ́n tètè kú látàrí COVID-19.

Nínú gbogbo ìwádìí nípa ọlọ́pọ̀ aàrùn, àwọn aṣèwádìí ṣe àwárí pé àìsàn ọkàn, ẹ̀jẹ̀ ríru àti ìtọ̀ ṣugà ló ní ewu jù, èyí sì ní ṣẹ pẹ̀lú ogbó.

Àwọn aṣèwádìí kò rí ìjámọ́ra láàárín ìtọ̀ ṣúgà àti ikú àwọn alárùn COVID-19.

Àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe kọjá jabọ̀ àwọn ipa ti ó ṣe é ṣe kí aàrùn ní, ìwádìí yìí sì ti fòǹtẹ̀ lù ú pé ọ̀pọ̀ aàrùn máa jẹ́ kí ewu aàrùn COVID-19 lẹ́ kan sí i, ó sì máa ń fa ìbájáde tó burú.

Àwọn aṣèwádìí sọ pé ìdíwọ́ máa wà fún ìwádìí yìí nítorí ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn wọn ni ó Ọ̀pọ̀ aàrùn ẹ̀dọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́, kíndìnrín, ìyòrò, aàrùn àjẹ́mọ́ ọpọlọ, endocrine, àti àìsàn agbogun-tira-ẹṅi.

Wọ́n ṣe àkíyèsi pé àìṣe déedée wà ní àwọn àkọsílẹ̀ ilé ìwòsàn, Ìlàkalẹ̀ ìtọ́jú àti ìlànà ìgbàwọlé lásìkò ìwádìí, èyí tí ó lè ṣe àkóbá fún ẹ̀sì wọn.

Àwọn asèwádìí tún mẹ́nubà á pé ìwádìí tí parí kí àbájáde àwọn aláìsàn wọ́n tó yé wọn.

Àwọn aṣèwádìí dábàá ọ̀pọ̀ ìwádìí mìíràn ní ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn, oríṣiríṣi àwọn ọ̀pọ̀ aàrùn, àti ọ̀pọ̀ àsìkò fún ìwádìí.


Connections
1 of 5
Comments
0
comment
No comments here
Why not start the discussion?