Description
This is a lay summary of the article published under the DOI: 10.1155/2020/2683286
Yoruba translation of DOI: 10.1155/2020/2683286
Àjàkálẹ̀ aàrùn kán ti ń tànkálẹ̀ ní ìlú Wuhan, ní China, ní oṣù Ọpẹ́ 2019.
Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, Àjọ Tó N Rísí Ọ̀rọ Ìlere Lágbàáyé (WHO) kéde àìsàn tuntun kòrónà tí a sọ ní aàrun àìsàn kòrónà 2019 (COVID-19).
Ní òpin oṣù Ṣẹẹrẹ 2020, WHO kéde ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ “pàjáwìrì ìlera gbogbogbò tó kan gbogbo àgbáyé” látara ìtàkálẹ̀ àjàkálẹ̀ aàrùn káàkiri àgbáyé.
Nísisìnyí, kò sí àjẹsára tàbí ìtọ́jú tí a bọwọ́ lù fún aàrùn yí; nítorí náà, kókó ìwádìí yìí ni láti ṣẹ̀dá àjẹsára afáralókun-ìgbóguntàrùn láti lè kọjú ìjà sí COVID-19 nípa lílo ìlàna imunoiǹfọmátíikì.
Àwọn ète tí ó ń tukọ̀ àṣepọ̀ ìlàna imunoinfọmátíìkì àti ìfiwéra ìlàna gínómíìsì di lílò láti pinu ìmọọ́ṣe pẹ́putáìdì fún ṣíṣẹ̀dá àjẹsára adálórí-ẹ́pítóòpù pẹ́pútáìdì T-sẹẹ̀lì nípa lílo ìwémọ́ purotéènì ti 2019-nCoV gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn.
Ìyídà, ìtìbọ̀, àti ìọkúrò ni wọ́n rí p̀lú ìfiẃra ṣíṣẹ-n-tẹ̀lé nínú COVID-19.
Láfikún, ìdi pẹ́pútáìdì mẹ́wàá sí kíláàsì MHC I àti kíláàsì MHC II ni wọ́n ri pé wọ́n ń yege fún àjẹsára pẹ̀lú iye ẹni tó wà lágbàáyé tó tó 88.5% àti 99.99% lọ́kan-ò-jọ̀kan.
Àjẹsára adálórí-ẹ́pítóòpù pẹ́pútáìdì T-sẹẹ̀lì náà jẹ́ ṣíṣẹ̀dá fún COVID-19 nípa lílo ìwémọ́ purotéènì náà gẹ́gẹ́ bí i àfojúsùn ìpèsè èsì afáralókun.
Láíròtẹ́lẹ̀, àbá àjẹsára náà nílo ìyẹ̀wò láti lè ri pé ó wàpa àti pé ìpèsè èsì afáralókun dára láti lè dá ìtàkálẹ̀ yí dúró kí ó tó di ohun tí yóò ba ọ̀pọ̀ ohun jẹ́ káàkiri àgbáyé.
Ní ọdún 2020, kí àjẹsára tí ń gbógun ti COVID-19 tó wà lárọ́wọ́tó, àwọn olùṣèwádìí ní Sudan dábàá àjẹsára kan tí yóò fára lókun àti gbógun ti ìwémọ́ purotéènì aàrun SARS-CoV-2 náà.
Lásìkò yí, ọ̀pọ̀ olùṣèwádìí ni ó ń wá àjẹsára tó ń ṣiṣẹ́ tí kò si léwu ní lílò láti gbógun ti COVID-19, tí ó ṣẹ̀ ń tànkálẹ̀ káàkiri àgbáyé.
Àjẹsára adálórí-pẹ́pútáìdi kò léwu wọ́n sì jẹ́ olówó pọ́kú tí a bá ṣe àfiwé wọn pẹ̀lú irúfẹ́ àwọn àjẹsára mìíràn.
Àwọn pẹ́pútáìdi jẹ́ àmínó asiìdì kékèké àti pé àwọn àmínó asiìdì wọ̀nyí jẹ́ òkúta ìmọlé fún purotéènì, léyìí tó ní pẹ́putáìdì púpọ̀.
Ẹ́pítóòpù jẹ́ àfojúsùn pẹ́pútáìdi tí ẹ̀ka ìgboguntàrùn inú ará lè dá mọ̀.
Àjẹsára adálórí-pẹ́pútáìdi máa ń ṣàmúlò ẹ́pítóòpù látara aàrun tó fa ̀sì ìgbóguntàrùn inú ara, ̀yí tí í ṣe ìwémọ́ purotéènì, tàbí purotéènì E.
Àwọn purotéènì E náà jẹ́ ẹ̀ya akópa nínú àpapọ̀ purotéèni (́”ìdàbò”) tó yí aàrùn náà ka.
Purotéènì náà ni ipa tí ó ń kó lórí I bí aàrun náà ṣe nípá tó lórí àwọn sẹ́ẹ̀lì̀ àti bí ó ṣe ń fa àìsàn.
Àwọn olùṣèwádìí iṣẹ́ yìí ń gbèrò àti ṣe àjẹsára adálórí-pẹ́pútáìdi nípa ṣíṣe ìfiwéra ìtẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé jíìnì pẹ́pútáìdi tí a pín láàárín àsopọ aàrun kòrónà, nípa ṣíṣàmúlò ìwémọ́ (E) purotéènì gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn.
Lákọ̀ọ́kọ́ wọ́n wo àpapọ̀ dátà fún ìtẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé gíìni àwọn ohun tí ó lè jẹ́ àfojúsùn pẹ́pútáìdì.
Síwájú sí i, wọ́n lo módẹ́ẹ̀lì kọ̀m̀pútà àti ìmọ wọn lórí I bí àjẹsára ṣe máa ń ṣe ìtají èsi ìgbóguntàìsàn láti ṣe ìdámọ̀ ìtẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé gíìni tí a lè lò láti ṣẹ̀dá a àjẹsára.
Àwọn olùṣèwádìí i náà ṣe ìdámọ̀ pẹ́pútáìdì kọ̀ọ̀kan tí ó wà lára àpapọ̀ àwọn aàrun kòrónà tí ó lè jẹ́ lílò fún àjẹsára, àmọ́ tí ó sinlẹ̀ lórí i purotéènì E gẹ́gẹ́ bí i àyo àjẹsára wọn.
Wọ́n ní àwọn yege láti ṣẹ̀dá àjẹsára adálóríi-purotéènì tí ó lè gbógun ti COVID-19 nípa ìṣàmúlò oníṣíṣẹ̀ǹtẹ̀lé ìwémọ́ purotéènì náà.
Àwọn olùṣèwádìí náà sọ pé àwọn ni ọ̀wọ́ tó kọ́kọ́ ṣàwárí apá ìwépọ́ (E) purotéèni (pẹ́pútáìdì)̀ náà gẹ́gẹ́ bí I àjẹsára fún COVID-19.
Binciken nasu ya nuna yuwuwar allurar rigakafin furotin, waɗanda ke da aminci, sababbi, araha da kuma ingantacciyar hanyar haɓaka sabuwar rigakafin cutar ta COVID-19.
Àmọ́ sá, àjẹsára wọn yóò ní láti jẹ́ yíyẹ̀wò síwáju ní agbègbe ìmọ́tótó́ láti ri dájú pé ó dára fún lílò ó ṣì yèkooro.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ olùṣèwádìí ilẹ̀ Sudan tó wà nídìí iṣẹ́ yìí, àwọn àjẹsára oní purot́ènì kò wọ́n láti ṣẹ̀dá, nítorí náà wó lè di ṣíṣẹ àti pínpín ní àwọn ìlú tí wọ́n ṣè ń ní ìdàgbàsókè yó yèkooro.
Amharic translation of DOI: 10.1155/2020/2683286
Hausa translation of DOI: 10.1155/2020/2683286
Luganda translation of DOI: 10.1155/2020/2683286